1
2tí ó bá di ìyàwó ọkùnrin mìíràn lẹ́yìn ìgbà tí ó kúrò nílé rẹ,
3àti tí ọkọ rẹ̀ kejì kò bá fẹ́ràn rẹ̀ tí ó sì kọ ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ sí i, kí ó fi fún un kí ó sì lé e kúrò nílé e rẹ̀, tàbí tí ọkọ rẹ̀ kejì bá kú,
4nígbà náà ni ọkọ, tí ó ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, kò gbọdọ̀ fẹ ẹ mọ́ lẹ́yìn tí ó ti di àìmọ́. Nítorí èyí ni ìríra níwájú OLÚWA. Má ṣe mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sórí ilẹ̀ tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ bí ogún.
5Bí ọkùnrin kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó, o kò gbọdọ̀ ran lọ sí ogun tàbí kí ó ní iṣẹ́ kan láti ṣe. Ó ní láti ní òmìnira fún ọdún kan kí ó dúró sílé kí ó sì mú inú dídùn bá ìyàwó rẹ̀ tí ó fẹ́.
6
7
8
9Rántí ohun tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ ṣe sí Míríámù lójú ọ̀nà lẹ́yìn ìgbà tí o jáde kúrò ní Éjíbítì.
10Nígbà tí o bá wín arákùnrin rẹ ní ohunkóhun, má ṣe lọ sí ilé rẹ̀ láti gba ohun tí ó bá mú wá bí ẹ̀rí.
11Dúró síta gbangba kí o sì jẹ́ kí ọkùnrin tí o wín mú ògò rẹ jáde wá fún ọ.
12Bí ọkùnrin náà bá jẹ́ talákà má ṣe lọ sùn ti ìwọ ti ògo rẹ.
13Dá aṣọ ìlékè rẹ padà ní àṣálẹ́ kí ó báà le sùn lórí i rẹ̀. Nígbà náà ni yóò dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, ó sì má a jásí ìwà òdodo níwájú OLÚWA Ọlọ́run rẹ.
14
15San owó iṣẹ́ rẹ̀ ní ọjọ́ kan náà kí ó tó di àṣàálẹ́, nítorí ó jẹ́ talákà, ó sì gbẹ́kẹ̀lé e bí kò ṣe bẹ́ẹ̀ ó lè képe OLÚWA sí ọ, o sì máa gba ìdálẹ́bi ẹ̀ṣẹ̀.
16Baba kò gbọdọ̀ kú fún àwọn ọmọ wọn tàbí kí àwọn ọmọ kú fún bàbá wọ́n; olúkúlùkù ní láti kú fún ẹ̀ṣẹ̀ òun tìkára rẹ̀.
17
18Rántí pé o jẹ́ ẹrú ní Éjíbítì tí OLÚWA Ọlọ́run rẹ sì gbà ọ́ níbẹ̀. Ìdí nìyí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ṣe èyí.
19
20Nígbà tí o bá ń gun igi ólífì lára àwọn igi i rẹ, má ṣe padà lọ sí ẹ̀ka náà ní ìgbà kejì. Fi èyí tí ó kù fún àlejò, aláìní baba àti opó.
21Nígbà tí o bá kórè èṣo àjàrà nínú ọgbà àjàrà rẹ, má ṣe lọ sí ọgbà náà mọ́. Fi èyí tí ó kù fún àlejò, aláìní baba àti opó.
22Rántí pé o ti jẹ́ àlejò ní Éjíbítì. Ìdí nìyí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ṣe èyí.