1Èyí ni ìbùkún tí Móṣè ènìyàn Ọlọ́run bùkún fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kí ó tó kú.
2Ó sì wí pé:
2“OLÚWA ti Sínáì wá,ó sì yọ sí wọn láti Ṣéírì wáó sì tàn án jáde láti òkè Páránì wá.Ó ti ọ̀dọ̀ ẹgbẹgbàarùn ún àwọn mímọ́ wáláti ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni òfin kan amúbíiná ti jáde fún wọn wá.
3Nítòótọ́, ó fẹ́ràn àwọn ènìyàn an rẹ̀,gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ wà ní ọwọ́ rẹ̀.Ní ẹṣẹ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti foríbalẹ̀,àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni wọ́n ti ń gba ọ̀rọ̀,
4òfin tí Móṣè fifún wa,ìní ti ìjọ ènìyàn Jákọ́bù.
5Òun ni ọba lórí Jéṣúrúnìní ìgbà tí olórí àwọn ènìyàn péjọ pọ̀,pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì
5
6“Jẹ́ kí Rúbẹ́nì yè kí ó má ṣe kú,tàbí kí ènìyàn rẹ mọ níwọ̀n.”
7Èyí ni ohun tí ó sọ nípa Júdà: “OLÚWA gbọ́ ohùn Júdàkí o sì mú tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ wá.Kí ọwọ́ rẹ̀ kí ó tó fún un,kí ó sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta rẹ̀!”
8Ní ti Léfì ó wí pé: “Jẹ́ kí Túmímù àti Úrímù rẹ kí ó wàpẹ̀lú ẹni mímọ́ rẹ.Ẹni tí ó dánwò ní Másà,ìwọ bá jà ní omi Méríbà.
9Ó wí fún baba àti ìyá rẹ pé,‘Èmi kò buyì fún wọn.’Kò mọ àwọn arákùnrin rẹ̀,tàbí mọ àwọn ọmọ rẹ̀,ṣùgbọ́n ó dúró lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀,ó sì pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́.
10Ó kọ́ Jákọ́bù ní ìdájọ́ rẹ̀àti Ísírẹ́lì ní òfin rẹ̀.Ó mú tùràrí wá ṣíwájú rẹ̀àti ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ẹbọ sísun sórí i pẹpẹ rẹ̀.
11Bù sí ohun ìní rẹ̀, OLÚWA,kí o sì tẹ́wọ́gba iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.Lu ẹgbẹ́ àwọn tí ó dìde sí i;kí wọn kí ó má ṣe dìde mọ́.”
12Ní ti Bẹ́ńjámínì ó wí pé: “Jẹ́ kí olùfẹ́ OLÚWA máa gbé ní àlàáfíà lọ́dọ̀ rẹ̀,òun a máa bò ó ní gbogbo ọjọ́,ẹni tí OLÚWA fẹ́ràn yóò máa sinmi láàrin èjìká rẹ̀.”
13Ní ti Jóṣẹ́fù ó wí pé: “Kí OLÚWA bùkún ilẹ̀ rẹ,fún ohun iyebíye láti ọ̀run pẹ̀lú ìrìàti ibú tí ó ń bẹ níṣàlẹ̀;
14àti fún èso iyebíye tí ọ̀run mú wáàti ti ohun iyebíye tí ń dàgbà ní oṣooṣù;
15pẹ̀lú ohun pàtàkì òkè ńlá ìgbàanìàti fún ohun iyebíye ìgbà ayérayé;
16Pẹ̀lú ohun iyebíye ayé àti ẹ̀kún un rẹ̀àti fún ìfẹ́ ẹni tí ó ń gbé inú igbó.Jẹ́ kí gbogbo èyí sinmi lé orí Jósẹ́fù,lórí àtàrí ẹni tí ó yàtọ̀ láàrin àwọn arákùnrin rẹ̀.
17Ní ọlá ńlá ó dàbí àkọ́bí akọ màlúù;ìwo rẹ̀, ìwo àgbáǹréré ni.Pẹ̀lú wọn ni yóò fi ti àwọn orílẹ̀ èdè,pàápàá títí dé òpin ayé.Àwọn ní ẹgbẹẹgbàárùn-ún Éfúráímù,àwọn sì ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún Mánásè.”
18Ní ti Ṣébúlúnì ó wí pé: “Yọ̀ Sébúlúnì, ní ti ìjáde lọ rẹ,àti ìwọ Ísákárì, nínú àgọ́ rẹ.
19Wọn yóò pe àwọn ènìyàn sórí òkèàti níbẹ̀ wọn yóò rú ẹbọ òdodo,wọn yóò mu nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ òkun,nínú ìṣúra tí ó pamọ́ nínú iyanrìn.”
20Ní ti Gádì ó wí pé: “Ìbùkún ni ẹni tí ó mú Gádì gbilẹ̀!Gádì ń gbé níbẹ̀ bí kìnnìún,ó sì fa apá ya, àní àtàrí.
21Ó sì yan ilẹ̀ tí ó dára jù fún ara rẹ̀;ìpín olórí ni a sì fi fún un.Nígbà tí ó rí tí gbogbo àwọn ènìyàn péjọ,ó mú òdodo OLÚWA se,àti ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.”
22Ní ti Dánì ó wí pé: “Ọmọ kìnnìún ni Dánì,tí ń fò láti Básánì wá.”
23Ní ti Náfítánì ó wí pé, “Ìwọ Náfítánì, Náfítánì kún fún ojú rere Ọlọ́runàti ìbùkún OLÚWA;yóò jogún ìhà ìwọ̀ oòrùn àti gúṣù.”
24Ní ti Áṣérì ó wí pé: “Ìbùkún ọmọ ni ti Áṣérì;jẹ́ kí ó rí ojú rere láti ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀kí ó sì ri ẹṣẹ̀ rẹ̀ sínú òróró.
25Bàtà rẹ̀ yóò jẹ́ irin àti idẹ,agbára rẹ̀ yóò sì rí bí ọjọ́ rẹ̀.
26“Kò sí ẹlòmíràn bí Ọlọ́run Jéṣúrúnì, ẹni tí ń gun ọ̀run fún ìrànlọ́wọ́ rẹàti ní ojú ọ̀run nínú ọlá ńlá rẹ̀.
27Ọlọ́run ayérayé ni ibi ìsádi rẹ,àti ní ìsàlẹ̀ ni apá ayérayé wà.Yóò lé àwọn ọ̀ta rẹ níwájú rẹ,ó sì wí pé, ‘Ẹ máa párun!’
28Ísírẹ́lì nìkan yóò jòkòó ní àlàáfíà,oríṣun Jákọ́bù nìkanní ilẹ̀ ọkà àti ti ọtí wáìnì,níbi tí ọ̀run ti ń ṣẹ ìrì sílẹ̀.
29Ìbùkún ni fún ọ, Ísírẹ́lì,ta ni ó dà bí ì rẹ,ẹni tí a gbàlà láti ọ̀dọ̀ OLÚWA?Òun ni àṣà àti ìrànwọ́ rẹ̀àti idà ọlá ńlá rẹ̀.Àwọn ọ̀ta rẹ yóò tẹríba fún ọ,ìwọ yóò sì tẹ ibi gíga wọn mọ́lẹ̀.”