1
2
3
4torí pé wọ́n á yí àwọn ọmọ yín padà kúrò lẹ́yìn mi, láti jẹ́ kí wọn máa sin òrìṣà, ìbínú OLÚWA yóò sì wá sórí yín, yóò sì run yín kíákíá.
5
6
7OLÚWA kò torí pé ẹ pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ ju àwọn ènìyàn yóòkù lọ yàn yín, ẹ̀yin sáà lẹ kéré jù nínú gbogbo ènìyàn.
8Ṣùgbọ́n torí Ọlọ́run fẹ́ràn yín, tí ó sì pa ìbúra tí ó ṣe pẹ̀lú àwọn baba ńlá yín mọ́ ni ó se fi ọwọ́ agbára ńlá mú un yín jáde tí ó sì rà yín padà nínú oko ẹrú, àti láti ọwọ́ agbára Fáráò ọba Éjíbítì.
9Nítorí náà ẹ mọ̀ dájúdájú pé OLÚWA Ọlọ́run yín, Òun ni Ọlọ́run, Ọlọ́run olótìítọ́ ni, tí ń pa májẹ̀mú ìfẹ́ rẹ̀ mọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìran, àwọn tí ó fẹ́ ẹ tí ó sì ń pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
10Ṣùgbọ́n
11Nítorí náà ẹ kíyési láti máa tẹ̀lé àwọn àṣẹ, ìlànà àti òfin tí mo fun un yín lónìí.
12
13Yóò fẹ́ràn yín, yóò bùkún un yín yóò sì mú kí ẹ pọ̀ sí i. Yóò bùkún èṣo inú un yín, ọ̀gbìn ilẹ̀ yín, oúnjẹ yín, wáìnì tuntun àti òróró yín, àwọn màlúù, agbo ẹran yín, àti àwọn àgùntàn, ọ̀wọ́ ẹran yín, ní ilẹ̀ tí ó ti búra fún àwọn baba ńlá yín láti fún un yín.
14A ó bùkún un yín ju gbogbo ènìyàn lọ, kò sí ẹni tí yóò yàgàn nínú ọkùnrin tàbí obìnrin yín, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ọ̀kan nínú àwọn ohun ọ̀sìn in yín tí yóò wà láìlọ́mọ.
15OLÚWA yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú àrùn gbogbo, kì yóò jẹ́ kí èyíkéyìí àrùn búburú tí ẹ mọ̀ ní Éjíbítì wá sára yín, ṣùgbọ́n yóò fi wọ́n lé ara gbogbo àwọn tí ó kórìíra yín.
16Gbogbo àwọn ènìyàn tí OLÚWA Ọlọ́run yín fi lé yín lọ́wọ́ ni kí ẹ parun pátapáta. Ẹ má ṣe sàánú fún wọn, ẹ má ṣe sin olúwa ọlọ́run wọn torí pé ìdánwò ni èyí jẹ́ fún un yín.
17Ẹ lè máa rò láàrin ara yín pé, “Àwọn orílẹ̀ èdè yìí lágbára jù wá lọ. Báwo ni a o ṣe lé wọn jáde?”
18Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe bẹ̀rù wọn: Ẹ rántí dáradára ohun tí OLÚWA Ọlọ́run yín ṣe sí Fáráò àti gbogbo Éjíbítì.
19Ẹ sáà fi ojú u yín rí àwọn àdánwò ńlá, àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá, ọwọ́ agbára àti nínà ọwọ́ tí OLÚWA Ọlọ́run yín fi mú un yín jáde. OLÚWA Ọlọ́run yín yóò ṣe bákan náà sí gbogbo àwọn ènìyàn náà tí ẹ ń bẹ̀rù.
20Pẹ̀lúpẹ̀lù, OLÚWA Ọlọ́run yín yóò rán oyin sáàrin wọn títí tí àwọn tí ó sálà tí wọ́n sápamọ́ fún un yín, yóò fí ṣègbé.
21Ẹ má gbọ̀n jìnnìjìnnì torí wọn, torí pé OLÚWA Ọlọ́run yín tí ó wà láàrin yín, Ọlọ́run alágbára ni, àti Ọlọ́run tí ó tóbi lọ́pọ̀lọpọ̀.
22OLÚWA Ọlọ́run yín yóò lé gbogbo orílẹ̀ èdè wọ̀n-ọn-nì kúrò níwájú u yín díẹ̀díẹ̀. A kò ní gbà yín láàyè láti lé wọn dànù lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Kí àwọn ẹranko ìgbẹ́ má baà gbilẹ̀ sí i láàrin yín.
23Ṣùgbọ́n OLÚWA Ọlọ́run yín yóò fi wọ́n lée yín lọ́wọ́, yóò sì máa fà wọ́n sínú un dàrúdàpọ̀ títí tí wọn yóò fi run.
24Yóò fi àwọn ọba wọn lé e yín lọ́wọ́, ẹ̀yin ó sì pa orúkọ wọn rẹ́ lábẹ́ ọ̀run. Kò sí ẹni tí yóò lè dojú ìjà kọ yín títí tí ẹ ó fi pa wọ́n run.
25Dá iná sun àwọn ère òrìṣà wọn, ẹ má ṣe ṣe ojúkòkòrò sí fàdákà tàbí wúrà tí ó wà lára wọn. Ẹ má ṣe mú un fún ara yín, bí bẹ́ẹ̀ kọ́ yóò jẹ́ ìdẹkùn fún un yín, torí pé ìríra ni sí OLÚWA Ọlọ́run yín.
26Ẹ má ṣe mú ohun ìríra wá sí ilé yín, kí ìwọ má bàá di ẹni ìparun bí i rẹ̀. Ẹ kóríra rẹ̀ kí ẹ sì kàá sí ìríra pátapáta, torí pé a yà á sọ́tọ̀ fún ìparun ni.