1
2Olùfẹ́, ọmọ Ọlọ́run ni àwa ń ṣe nísinsin yìí, a kò ì tí i fihàn bí àwa ó ti rí: àwa mọ̀ pé, nígbà tí òun ba farahàn, àwa yóò dàbí rẹ̀; nítorí àwa yóò rí i, àní bí òun tí rí.
3Olúkúlùkù ẹni tí o ba sì ní ìrètí yìí nínú rẹ̀, ń wẹ ara rẹ̀ mọ́, àní bí òun ti mọ́.
4Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ó ń rú òfin pẹ̀lú: nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ni rírú òfin.
5
6Ẹnikẹ́ni tí o ba ń gbé inú rẹ̀ kì í dẹ́ṣẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ń dẹ́ṣẹ̀ kò rí i, bẹ́ẹ̀ ni kò mọ̀ ọ́n.
7Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín: ẹni tí ó bá ń ṣe òdodo, ó jásí olódodo, gẹ́gẹ́ bí òun tí jẹ olódodo.
8
9
10Nínú èyí ni àwọn ọmọ Ọlọ́run ń farahàn, àti àwọn ọmọ Èṣù; ẹníkẹni í kò ba ń ṣe òdodo, àti ẹni tí kò fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀ kì í ṣe ti Ọlọ́run.
11
12Kì í ṣe bí Káínì, tí í ṣe ẹni búburú, tí o sì pa arákùnrin rẹ̀. Nítorí kín ni ó sì ṣe pa á? Nítorí tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́ búburú ṣùgbọ́n tí arakúnrin rẹ̀ sì jẹ́ òdodo.
13
14
15Ẹnikẹ́ni tí ó ba kórìíra arákùnrin rẹ̀ apànìyàn ni: ẹ̀yin sì mọ́ pé kò sí apànìyàn tí o ni ìyè àìnípẹ̀kun láti máa gbé inú rẹ̀.
16
17Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ni ohun ìní ayé, tí ó sì ri arákùnrin rẹ̀ tí ó ṣe aláìní, tí ó sì sé ìlẹ̀kùn ìyọ́nú rẹ̀ mọ́ ọn, báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe ń gbé inú rẹ̀?
18
19Àti nípa èyí ni àwa ó mọ̀ pé àwa jẹ́ ti òtítọ́, àti pé àwa ó sì dá ara wa lójú níwájú rẹ̀.
20Nínú ohunkóhun tí ọkàn wa bá ń dá wa lẹ́bi; nítorí pé Ọlọ́run tóbi ju ọkàn wa lọ, ó sì mọ ohun gbogbo.
21
22Àti ohunkòhun tí àwa bá béèrè, ni àwa ń rí gbà lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí tí àwa ń pa òfin rẹ̀ mọ́, àwa sì ń ṣe àwọn nǹkàn tí ó dára lójú rẹ̀.
23
24