Ìwé Jóòbù 10:1-22 BYB2014 - Bible AI

1“Agara ìwà ayé mi dá mi tán, èmi yóò tú àròyé mi sókè lọ́dọ̀ mi, èmi yóò máa sọ níní kíkorò ìbìnújẹ́ ọkàn mi.

2Èmi yóò wí fún Ọlọ́run pé: má ṣe dámi lẹ́bi; fi hàn mí nítorí ìdí ohun tí ìwọ fí ń bá mi jà.

3Ó ha tọ́ tí ìwọ ì bá fi máa ni mí lára, tí ìwọ ìbá fi máa gan iṣẹ́ ọwọ́ rẹ tí ìwọ yóò fi máa tàn ìmọ́lẹ̀ sí ìmọ̀ ènìyàn búrurú.

4Ojú rẹ ìha ṣe ojú ènìyàn bí? Tàbí ìwọ a máa ríran bí ènìyàn ti í ríran?

5Ọjọ́ rẹ ha dàbí ọjọ́ ènìyàn, ọdún rẹ ha dàbí ọjọ́ ènìyàn?

6Tí ìwọ fi ń bèèrè àìṣedédé mi, tí ìwọ sì fi wá ẹ̀ṣẹ̀ mi rí?

7Ìwọ mọ̀ pé èmi kì í ṣe oníwà búburú, kò sì sí ẹni tí ó le gbà mí kúrò ní ọwọ́ rẹ?

7

8“Ọwọ́ rẹ ni ó dámi, tí ó sì mọ mí pọ̀ yíkákiri; síbẹ̀ ìwọ sì ńbà mí jẹ́.

9Èmi bẹ̀ ọ́ rántí pé ìwọ tí ìwọ ti mọ mí bí amọ̀; ìwọ yóò ha sì tún mú mi lọ padà sí erùpẹ̀?

10Ìwọ kò ha ti tún mí dà jáde bí i wàrà, ìwọ kò sì múmí dípò bí i wàràǹkàsì?

11Ìwọ sá ti fi àwọ̀ ẹran ara wọ̀ mí, ìwọ sì fi egungun àti iṣan ṣọgbà yí mi ká.

12Ìwọ ti fún mi ní ẹ̀mí àti ojú rere, ìbẹ̀wò rẹ sì pa ọkàn mi mọ́.

12

13“Nǹkan wọ̀nyí ni ìwọ sì ti fi pamọ́ nínú rẹ; èmi mọ̀ pé, èyí ń bẹ ní ọkàn rẹ.

14Bí mo bá ṣẹ̀, nígbà náà ni ìwọ yóò máa ṣọ́mi ìwọ kì yóò sì dárí àìṣedédé mi jìn.

15Bí mo bá ṣe ẹni búburú, ègbé ni fún mi! Bí mo bá sì ṣe ẹni rere, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò sì le gbe orí mi sókè. Nítorí mo wà nínú ìtọ́jú púpọ̀, mo sì wo ìpọ́jú mi.

16Bí mo bá gbé orí mi ga. Ìwọ ń dẹ mí kiri bi i kìnnìhún; àti pẹ̀lú, ìwọ a sì fi ara rẹ hàn fún mi ní ìyànjú.

17Ìwọ sì tún sọ àwọn ẹlẹ́rìí rẹ sí mi di ọ̀tún, Ìwọ sì sọ ìrúnú rẹ di púpọ̀ sí mi; Àyípadà àti ogun dó tì mí.

17

18“Nítorí kí ni ìwọ ṣe mú mi jáde láti inú wá? Áà! èmi ìbá kúkú ti kú, ojúkójú kì bá tí rí mi

19Tí ó bá lejẹ́ pé èmi le wà láàyè, À bá ti gbé mi láti inú lọ isà-òkú.

20Ọjọ́ mi kò ha kúrú bí? Rárá dáwọ́ dúró, kí ó sì yí padà kúrò lọ́dọ̀ mi nítorí kí èmi lè ni ayọ̀ ní ìṣẹ́jú kan

21Kí èmi kí ó tó lọ síbi tí èmi kì yóò padà sẹ́yìn mọ́, Àní kí ilẹ̀ òkùnkùn àti òjìji ikú,

22Ilẹ̀ òkùnkùn bí òkùnkùn tìkárarẹ̀, Àti ti òjìji ikú, láìní ìtọ́, Níbi tí ìmọ́lẹ̀ dàbí òkùnkùn.”

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>