1Ígbà náà ni Sófárì, ará Naamáa, dáhùn, ó sì wí pé:
2“A ha lè ṣe kí a máa dáhùn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀? A ha lè fi gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí da ènìyàn láre?
3Ṣé àmọ̀tàn rẹ le mú ènìyàn pa ẹnu wọn mọ́ bí? Ṣé ẹnikẹ́ni kò ní bá ọ wí bí ìwọ bá yọ ṣùtì sí ni?
4Ìwọ sáà ti wí fún Ọlọ́run pé, ‘ìṣe mi jẹ́ aláìléérí, èmi sì mọ́ ní óju rẹ.’
5Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ìbá jẹ́ sọ̀rọ̀, kí ó sì ya ẹnu rẹ̀ sí ọ lára;
6Kí ó sì fi àsírí ọgbọ́n hàn ọ́ pé, ó pọ̀ ju òye ènìyàn lọ; Nítorí náà, mọ̀ pé Ọlọ́run ti gbàgbé àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kan.
6
7“Ìwọ ha le ṣe àwárí ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run bí? Ìwọ ha le ṣe àwárí ibi tí Olodùmáarè dé bi?
8Ó ga ju àwọn ọ̀run lọ; kí ni ìwọ le è ṣe? Ó jìn ju jíjìn isà òkú lọ; kí ni ìwọ le mọ̀?
9Ìwọ̀n rẹ̀ gùn ju ayé lọ, ó sì ní ibú ju òkun lọ.
9
10“Bí òun bá rékọjá, tí ó sì sénà, tàbí tí ó sì mú ni wá sí ìdajọ́, ǹjẹ́, ta ni ó lè dí i lọ́wọ́?
11Òun sáà mọ ènìyàn asán; àti pé ṣé bí òun bá rí ohun búburú, ṣé òun kì i fi iyè sí i?
12Ṣùgbọ́n òmùgọ̀ ènìyàn yóò di ọlọgbọ́n, nígbà tí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ bá bí ènìyàn.
12
13“Bí ìwọ bá fi ọkàn rẹ fún un, tí ìwọ sì na ọwọ́ rẹ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀,
14Bí ìwọ bá gbé ẹ̀ṣẹ̀ tí ń bẹ ní ọwọ́ rẹ jù sọnù, tí ìwọ kò sì jẹ́ kí aburú gbé nínú àgọ́ rẹ.
15Nígbà náà ni ìwọ ó gbé ojú rẹ sókè láì ní àbàwọ́n, àní ìwọ yóò dúró ṣinṣin, ìwọ kì yóò sì bẹ̀rù,
16Nítorí pé ìwọ ó gbàgbé ìṣòro rẹ, ìwọ ó sì rántí rẹ̀ bí omi tí ó ti ṣàn kọjá lọ.
17Ọjọ́ ayé rẹ yóò sì mọ́lẹ̀ ju ọ̀sán gangan lọ, bí òkùnkùn tilẹ̀ bò ọ́ mọ́lẹ̀ nísisinyìí, ìwọ ó dàbí òwúrọ̀.
18Ìwọ ó sì wà láìléwu, nítorí pé ìrètí wà; àní ìwọ ó rin ilé rẹ wò, ìwọ ó sì sinmi ní àlàáfíà.
19Ìwọ ó sì dùbúlẹ̀ pẹ̀lú, kì yóò sì sí ẹni tí yóò dẹ́rùbà ọ́, àní ènìyàn yóò máa wá ojú rere rẹ.
20Ṣùgbọ́n ojú ìkà ènìyàn yóò mófo; gbogbo ọ̀nà àbáyọ ni yóò nù wọ́n, ìrètí wọn a sì dàbí ẹni tí ó jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́.”