Ìwé Jóòbù 12:1-25 BYB2014 - Bible AI

1Jóòbù sì dáhùn, ó sì wí pé:

2“Kò sí àní-àní níbẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni àwọn ènìyàn náà, ọgbọ́n yóò sì kú pẹ̀lú yín!

3Ṣùgbọ́n èmi ní ìyè nínú gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin: èmi kò rẹ̀yìn sí i yín: àní, ta ni kò mọ gbogbo nǹkan wọ̀nyí?

3

4“Èmi dàbí ẹni tí a ń fi ṣe ẹlẹ́yà lọ́dọ̀ aládùúgbò rẹ̀, tí ó ké pe Ọlọ́run, tí ó sì dá a lóhùn: à ń fi olóòótọ́ ẹni-ìdúró-ṣinṣin rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà.

5Ẹ̀gàn ni ẹni-ò-tòsì, tí ẹsẹ̀ rẹ múra tan láti yọ, nínú ìró ẹni tí ara rọ̀.

6Àgọ́ àwọn ìgárá ń bẹ̀rù; àwọn tí ó sì ń mú Ọlọ́run bínú wà láìléwu, àwọn ẹni tí ó sì gbá òrìṣà mú ní ọwọ́ wọn.

6

7“Ṣùgbọ́n nísínyìí bí àwọn ẹranko léèrè, wọn o kọ́ ọ ní ẹ̀kọ́, àti ẹyẹ ojú ọ̀run, wọn ó sì sọ fún ọ.

8Tàbí ba ilẹ̀ àyé sọ̀rọ̀, yóò sì kọ́ ọ, àwọn ẹja inú òkun yóò sì sọ fún ọ.

9Ta ni kò mọ̀ nínú gbogbo nǹkan wọ̀nyí pé, ọwọ́ OLÚWA ni ó ṣe nǹkan yìí?

10Ní ọwọ́ ẹni tí ẹ̀mí ohun alààyè gbogbo gbé wà, Àti ẹ̀mí gbogbo aráyé.

11Etí kì í dán ọ̀rọ̀ wò bí, Tàbí adùn ẹnu kì í sì í tọ́ oúnjẹ rẹ̀ wò bí?

12Àwọn arúgbó ni ọgbọ́n wà fún, Àti nínú gígùn ọjọ́ ni òye?

12

13“Pẹ̀lú rẹ Ọlọ́run ni ọgbọ́n àti agbára: Òun ni ìmọ̀ àti òye.

14Kíyèsí i, ó bì wó, a kò sì lè gbe ró mọ́; Ó ṣé ènìyàn mọ́, kò sì sí ìsísílẹ̀ kan.

15Kíyèsí i, ó dá àwọn omi dúró, wọ́n sì gbẹ; Ó sì rán wọn jáde, wọ́n sì sẹ̀ bo ilẹ̀ ayé yípo.

16Pẹ̀lú rẹ ni agbára àti ìṣẹ́gun; Ẹni tí ń sìnà àti ẹni tí ń mú ni sìnà, tirẹ̀ ni wọ́n ń ṣe.

17Ó mú àwọn ìgbìmọ̀ lọ ní ìhòòhò, A sì sọ àwọn onídàájọ́ di òmùgọ̀.

18Ó tú ìdè ọba, Ó sì fi mú àmùrè gbà wọ́n ní ọ̀já.

19Ó mú àwọn àlùfáà lọ ní ìhòòhò, Ó sì tẹ orí àwọn alágbára ba.

20Ó mú ọ̀rọ̀ ẹnu ẹni ìgbẹ́kẹ̀lé kúrò, Ó sì ra àwọn àgbààgbà ní iyè.

21Ó bu ẹ̀gàn lu àwọn ọmọ ọlọ́là, Ó sì tú àmùrè àwọn alágbára.

22Ó hú ìdí ohun ìjìnlẹ̀ jáde láti inú òkùnkùn wá, Ó sì mú òjìji ikú wá sínú ìmọ́lẹ̀.

23Òun a mú orílẹ̀-èdè bí sí i, a sì run wọ́n; Òun a sọ orílẹ̀-èdè di ńlá, a sì tún ṣẹ̀ wọn kù.

24Òun a gba àyà olú àwọn ènìyàn aráyé, A sì máa mú wọn wọ́ kiri nínú ijù níbi tí ọ̀nà kò sí.

25Wọn a máa fi ọwọ́ ta ilẹ̀ nínú òkùnkùn níbi tí kò sí ìmọ́lẹ̀, Òun a sì máa mú wọn tàsé ìrìn bí ọ̀mùtí.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>