1“Ò ó, ojú mi ti rí gbogbo èyí rí, Etí mí sì gbọ́, ó sì ti yé e.
2Ohun tí ẹ̀yin mọ̀, èmi mọ̀ pẹ̀lú, èmi kò rẹ̀yìn sí yin.
3Nítòótọ́ èmi ó bá Olódumárè sọ̀rọ̀, Èmi sì ń fẹ́ bá Ọlọ́run sọ àsọyé.
4Èyin ni oníhùmọ̀ èké, oníṣègùn lásán ni gbogbo yín
5Áà! ẹ̀yin kì bá kúkú dákẹ́! Èyi ni kì bá sì ṣe ọgbọ́n yín.
6Ẹ gbọ́ àwíyé mi nísinsìn yìí, Ẹ sì fetísilẹ̀ sí àròyé ètè mi.
7Èyin fẹ́ sọ ìsọkúsọ fún Ọlọ́run? Ki ẹ sì fi ẹ̀tàn sọ̀rọ̀ gbè é?
8Ẹ̀yin fẹ́ ṣojúṣaajú rẹ̀? Ẹ̀yin fẹ́ gbèjà fún Ọlọ́run?
9Ó ha dára tí yóò fi húdìí yín sílẹ̀, Tàbí kí ẹ̀yin tàn án bí ẹnìkan ti ítan ẹnìkejì?
10Yóò máa bá yín wí nítòótọ́, Bí ẹ̀yin bá ṣojúusájú ènìyàn níkọ̀kọ̀.
11Ìwà ọlá rẹ̀ kì yóò bà yín lẹ́rù bí? Ìpayà rẹ̀ kì yóò pá yín láyà?
12Ìrántí yín dàbí eérú; Ìlú odi yín ìlú odi amọ̀.
12
13“Ẹ pa ẹnu yín mọ́ kúrò lára mi, kí èmi kí ó lè sọ̀rọ̀, ohun tí ń bọ̀ wá íbá mi, kí ó máa bọ̀.
14Ǹjẹ́ nítorí kí ni èmi ṣe ń fi èyín mi bu ẹran ara mi jẹ, Tí mo sì gbé ẹ̀mí mi lé ara mi lọ́wọ́?
15Bí ó tilẹ̀ pa mí, síbẹ̀ èmi ó máa gbẹ́kẹ̀lé e; Ṣùgbọ́n èmi ó máa tẹnumọ́ ọ̀nà mi níwájú rẹ̀.
16Èyí ni yóò sì ṣe ìgbàlà mi, Àgàbàgebè kì yóò wá síwájú rẹ̀.
17Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi ní ìfàyà balẹ̀, àti àṣọpé mí ni etí yín.
18Wò ó nísinsin yìí, èmi ti làdí ọ̀ran mi sílẹ̀; èmi mọ̀ pé a ó dá mi láre.
19Ta ni òun ti yóò bá mi ṣàròyé? Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, èmi fẹ́ pa ẹnu mí mọ́, èmi ó sì jọ́wọ́ ẹ̀mi mi lọ́wọ́.
19
20“Ṣùgbọ́n, má ṣe ṣe ohun méjì yìí sí mi, Nígbà náà ni èmi kì yóò sì fi ara mi pamọ́ kúrò fún ọ:
21Fa ọwọ́ rẹ sẹ́yìn kurò lára mi, má sì jẹ́ kí ẹ̀rù rẹ kí ó pá mi láyà.
22Nígbà náà ni kí ìwọ kí ó pè, èmi o sì dáhùn; Ta ni jẹ́ kí ń máa sọ̀rọ̀, ki ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn.
23Mélòó ní àìṣedédé àti ẹ̀ṣẹ̀ mi? Mú mi mọ̀ ìrékọjá àti ẹ̀ṣẹ̀ mi.
24Nítorí kí ni ìwọ ṣe pa ojú rẹ mọ́, tí o sì yàn mí ní ọ̀tá rẹ?
25Ìwọ ó fa ewé ya ti afẹ́fẹ́ ń fẹ́ síhìn-ín sọ́hùn-ún? Ìwọ a sì máa lépa àkémọ́lẹ̀ pòròpórò gbígbẹ?
26Nítorí pé ìwọ kọ̀wé ohun kíkorò sí mi, o sì mú mi ní àìṣedéédéé èwe mi.
27Ìwọ kàn àbà mọ́ mi lẹ́ṣẹ̀ pẹ̀lú, ìwọ sì ń wò ipa ọ̀nà ìrìn mi ní àwòfín; Ìwọ sì ń fi ìlà yí gìgisẹ̀ mi ká.
27
28“Àní, yí ẹni tí á ti run ká, bí ohun tí ó bu, Bí aṣọ tí kòkòrò jẹ bàjẹ́.