Ìwé Jóòbù 14:1-22 BYB2014 - Bible AI

1“Ènìyàn tí a bí nínú obìnrin ọlọ́jọ́ díẹ̀ ni, ó sì kún fún ìpọ́njú.

2Ó jáde wá bí ìtànná ewéko, a sì ké e lulẹ̀; Ó sì ń fò lọ bí òjìji, kò sì dúró pẹ́.

3Ìwọ sì ń síjú rẹ wò irú èyí ni? Ìwọ sì mú mi wá sínú ìdájọ́ pẹ̀lú rẹ?

4Ta ni ó lè mú ohun mímọ́ láti inú àìmọ́ jáde wá? Kò sí ẹnìkan!

5Ǹjẹ́ a ti pinnu ọjọ́ rẹ̀, ìye oṣù rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ; Ìwọ ti pàlà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní òun kò le kọjá rẹ̀.

6Yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lè sinmi, títí yóò fi pé ọjọ́ rẹ̀ bí alágbàṣe.

6

7“Nítorí pé ìrètí wà fún igi, bí a bá ké e lulẹ̀, pé yóò sì tún ṣọ, àti pé ẹ̀ka rẹ̀ titun kì yóò dá.

8Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ogbó nínú ilẹ̀, tí kùkùté rẹ̀ si kú ni ilẹ̀;

9Síbẹ̀ nígbà tí ó bá gboorùn omi, yóò sọ yóò sì yọ ẹ̀ka jáde bí irúgbìn.

10Ṣùgbọ́n ènìyàn kú, a sì dàánù; Àní ènìyàn jọwọ́ ẹ̀mi rẹ̀ lọ́wọ́: Òun ha dà?

11“Bí omi tí i sàn nínú ipa odò, tí odò sì ífà tí sì ígbẹ,

12bẹ́ẹ̀ ènìyàn dùbúlẹ̀ tí kò sì dìde mọ́; títí ọ̀run kì yóò fi sí mọ́, wọ́n kì yóò jí, a kì yóò jí wọn kúrò lójú oorun wọn.

12

13“Áà! ìwọ ìbá fi mí pamọ́ ní ipò òkú, kí ìwọ kí ó fi mí pamọ́ ní ìkọ̀kọ̀, títí ìbínú rẹ yóò fi rékọjá, ìwọ ìbá lànà ìgbà kan sílẹ̀ fún mi, kí ó si rántí mi!

14Bí ènìyàn bá kú yóò sì tún yè bí? Gbogbo ọjọ́ ìgbà tí a là sílẹ̀ fún mi ni èmi dúró dè, títí àmúdọ̀tún mi yóò fi dé.

15Ìwọ ìbá pè, èmi ìbá sì dá ọ lóhùn; ìwọ ó sì ní ìfẹ́ sì iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

16Ṣùgbọ́n nísinsìn yìí ìwọ ń káye ìsísẹ̀ mi; ìwọ kò fa ọwọ́ rẹ kúrò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi?

17A fi èdìdì di ìrékọjá mi sínú àpò, ìwọ sì rán àìṣedédé mi pọ̀.

17

18“Àti nítòótọ́ òkè ńlá tí ó ṣubú, ó dasán, a sì sí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀.

19Omi a máa yinrin òkúta, ìwọ a sì mú omi ṣàn bo ohun tí ó hù jáde lóri ilẹ̀, ìwọ sì sọ ìrètí ènìyàn dí òfo.

20Ìwọ ṣẹ́gun rẹ̀ láéláé, òun sì kọjá lọ; Ìwọ pa awọ oju rẹ̀ dà, o sì rán an lọ kúrò.

21Àwọn ọmọ rẹ̀ bọ́ sí ipò ọlá, òun kò sì mọ̀; wọ́n sì rẹ̀ sílẹ̀, òun kò sì kíyèsìí lára wọn.

22Ṣùgbọ́n ẹran ara rẹ̀ ni yóò rí ìrora. Ọkàn rẹ̀ ni yóò sì máa ní ìbìnújẹ́ nínú rẹ̀.”

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>