1Ígbà náà ní Élífásì, ará Témà, dáhùn wí pé:
2“Ọlọ́gbọ́n a máa sọ̀rọ̀ ìmọ̀ asán, kí ó sì máa fi afẹ́fẹ́ ìlà oòrun kún ara rẹ̀ nínú?
3Òun lè máa fi àròyé sọ̀rọ̀ tí kò ní èrè, tàbí pẹ̀lú ọ̀rọ̀ nínú èyí tí kò lè fi ṣe rere?
4Ìwọ ṣá ìbẹ̀rù tì, ìwọ sì dí àdúrà lọ́nà níwájú Ọlọ́run.
5Nítorí pé ẹnu ara rẹ̀ ni ó jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, ìwọ sì yàn ahọ́n alárékérekè ni ààyò.
6Ẹnu ara rẹ̀ ni ó dá lẹ́bi, kì í ṣe èmi; àní ètè ara rẹ̀ ni ó jẹ́rìí tì ọ́.
6
7“Ìwọ ha íse ọkùnrin tí a kọ́ bi? Tabì a há dá ọ ṣáájú àwọn òkè?
8Ìwọ gburòó àsírí Ọlọ́run rí, tàbí ìwọ ha dá ọgbọ́n dúró sọ́dọ̀ ara rẹ?
9Kí ni ìwọ mọ̀ tí àwa kò mọ̀? Òye kí ní ó yé ọ tí kò sí nínú wa?
10Eléwú ogbó àti ògbólógbòó ènìyàn wà pẹ̀lú wa, tí wọ́n gbójú baba rẹ lọ.
11Ìtùnú Ọlọ́run ha kéré lọ́dọ̀ rẹ? Ọ̀rọ̀ kan sì ṣe jẹ́jẹ́ jù lọ́dọ̀ rẹ?
12Èéṣe ti àyà rẹ fi ń dà ọ kiri, kí ni n mú ojú rẹ se wàìwàì.
13Tí ìwọ fi yí ẹ̀mí rẹ padà lòdì sí Ọlọ́run, tí ó fi ń jẹ́ ki ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ kí ó máa bọ́ ní ẹnu rẹ̀ bẹ́ẹ̀?
13
14“Kí ni ènìyàn tí ó fi mọ́? Àti ẹni tí a tinú obìnrin bí tí yóò fi ṣe olódodo?
15Kíyèsí i, òun (Ọlọ́run) kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀, àní àwọn ọ̀run kò mọ́ ní ojú rẹ̀;
16Ańbọ̀tórí ènìyàn, ẹni ìríra àti eléèérìí, tí ń mù ẹ̀ṣẹ̀ bi ẹní mú omi.
16
17“Èmi ó fihàn ọ́: gbọ́ ti èmi; Èyí tí èmi sì rí, òun ni èmi ó sì sọ,
18tí àwọn ọlọ́gbọ́n ti pa ní ìtàn lati ọ̀dọ̀ àwọn baba wọn wá, ti wọ́n kò sì fi pamọ́,
19Àwọn tí a fi ilẹ̀ ayé fún nìkan, àlejò kan kò sì là wọ́n kọjá.
20Ènìyàn búburú ń ṣe làálàá, pẹ̀lú ìrora, ní ọjọ́ rẹ̀ gbogbo, àti iye ọdún ní a dá sílẹ̀ fún aninilára.
21Ìró ìbẹ̀rù ń bẹ ní etí rẹ̀; nínú ìrora ni apanirun yóò dìde sí i.
22O kò gbàgbọ́ pé òun ó jáde kúrò nínú òkùnkùn; a sì ṣà á sápákan fún idà.
23Ó ń wò káàkiri fún oúnjẹ wí pé, níbo ní ó wà? Ó mọ̀ pé ọjọ́ òkùnkùn súnmọ́ tòsí.
24Ìpọ́njú pẹ̀lú ìrora ọkàn yóò mú un bẹ̀rù, wọ́n ó sì sẹ́gun rẹ̀ bi ọba ti ímúra ogun.
25Nítorí pé ó ti nawọ́ rẹ̀ jáde lòdì sí Ọlọ́run, ó sì múra rẹ̀ le lòdì sí Olódùmáarè,
26Ó súre, ó sì fi ẹ̀yìn giga, àní fi ìké kòóko àpáta rẹ̀ tí ó nipọn kọlù ú.
26
27“Nítorí tí òun fi ọ̀rá rẹ̀ bo ara rẹ̀ lojú, o sì ṣe jabajaba ọ̀rá sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀.
28Òun sì gbé inú ahoro ìlú ìtakété, àti nínú iléyílé tí ènìyàn kò gbé mọ́, tí ó múra tán lati di àlàpà.
29Òun kò lé ìlà, bẹ́ẹ̀ ohun ìní rẹ̀ kò lè dúró pẹ́; Bẹ́ẹ̀ kò lè mú pípé rẹ̀ dúró pẹ́ lórí ilẹ̀.
30Òun kì yóò jáde kúrò nínú òkùnkùn; ọ̀wọ́ iná ni yóò jó ẹ̀ka rẹ̀, àti nípaṣẹ̀ ẹ̀mí ẹnu rẹ̀ ní yóò máa kọjá lọ kúrò.
31Kí òun kí ó má ṣe gbẹ́kẹ̀le asán, kí ó má sì ṣe tan ara rẹ̀ jẹ. Nítorí pé asán ní yóò jásí èrè rẹ̀.
32A ó mú un ṣẹ ṣáájú pípẹ́ ọjọ́ rẹ̀, ẹ̀ka rẹ̀ kì yóò sì tutù.
33Yóò sì gbọ̀n àìpọ́n èṣo rẹ̀ dànù bí i àjàrà, yóò sì rẹ̀ ìyanna rẹ̀ nù bí i ti igi Ólífì.
34Nítorí pé ayọ̀ àwọn àgàbàgebè yóò túká, iná ní yóò sì jó àgọ́ àwọn tí ó fẹ́ràn àbẹ̀tẹ́lẹ̀.
35Wọ́n lóyún ìwà ìkà, wọ́n sì bí ẹ̀ṣẹ̀, ikùn wọn sì pèṣè ẹ̀tàn.”