Ìwé Jóòbù 16:1-22 BYB2014 - Bible AI

1Ígbà náà ní Jóòbù dáhùn, ó sì wí pé:

2“Èmi ti gbọ́ irú ohun pípọ̀ bẹ́ẹ̀ rí ayọnilẹ́nu onítùnú ènìyàn ní gbogbo yín.

3Ọ̀rọ̀ asán lè ni òpin? Tàbí nín ni ó gbó ọ láyà tí ìwọ fi dáhùn?

4Èmi pẹ̀lú le sọ bí ẹ̀yin; bí ọkàn yín bá wà ní ipò ọkàn mi, èmi le íkọ ọ̀rọ̀ pọ̀ si yin ni ọ̀run, èmi a sì mi orí mi sí i yín.

5Èmi ìbá fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi gbà yín ni ìyànjú, àti ṣíṣí ètè mi ìbá sì tu ìbìnújẹ́ yín.

5

6“Bí èmi tilẹ̀ sọ̀rọ̀, ìbìnújẹ́ mi kò tù; bí mo sì tilẹ̀ dákẹ́, níbo ni ìtùnú mí dé?

7Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó dá mi lágara; Ìwọ (Ọlọ́run) mú gbogbo ẹgbẹ́ mi takété.

8Ìwọ sì fi ìkiyẹ̀jẹ kùn mí lára, tí ó jẹ́rìí tì mí; àti rírù tí ó yọ lára mi, ó jẹ́rìí lòdì sí ojú mi.

9Ọlọ́run fi Ìbínú rẹ̀ fà mí ya, ó sì ṣọ̀tá mi; ó pa eyín rẹ̀ keke sí mi, ọ̀ta mi sì gbójú rẹ̀ sí mi.

10Wọ́n ti fi ẹnu wọn yán sí mi; Wọ́n gbá mi ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ni ìgbá ẹ̀gàn; Wọ́n kó ara wọn pọ̀ sí mi.

11Ọlọ́run ti fi mí lé ọwọ́ ẹni búburú, ó sì mú mi ṣubú sí ọwọ́ ènìyàn ìkà.

12Mo ti jókòó jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n ó fà mí já; ó sì dì mí ọrùn mú, ó sì gbọ̀n mí túútúú, ó sì gbé mi kalẹ̀ ṣe àmì—ìtàfàsí rẹ̀.

13Àwọn tafàtafà rẹ̀ dúró yí mi kákiri; ó là mí láyà pẹ̀rẹ̀, kò si dásí, ó sì tú òróòro ara mi dà sílẹ̀.

14Ìbàjẹ́ lórí ìbàjẹ́ ní ó fi bà mí jẹ́; ó súré kọlù mi bí jagunjagun.

14

15“Mo rán aṣọ ọ̀fọ̀ n bò ara mi, mo sì rẹ̀ ìwo mi sílẹ̀ nínú erùpẹ̀.

16Ojú mi ti pọ́n fún ẹkún, òjìji ikú sì ṣẹ́ sí ìpéǹpéjú mi.

17Kì í ṣe nítorí àìsòótọ́ kan ní ọwọ́ mi; àdúrà mi sì mọ́ pẹ̀lú.

17

18“Áà! Ilẹ̀ ayé, ìwọ má ṣe bò ẹ̀jẹ̀ mi, kí ẹkún mi má ṣe wà ní ipò kan.

19Ǹjẹ́ nísinsinyí kíyèsí i, ẹlẹ́rìí mi ń bẹ ní ọ̀run, ẹ̀rí mi sì ń bẹ lókè ọ̀run.

20Àwọn ọ̀rẹ́ mi ń fi mí ṣẹ̀sín, ṣùgbọ́n ojú mi ń da omijé sọ́dọ̀ Ọlọ́run;

21Ìbáṣe pé ẹnìkan le è máa ṣe alágbàwí fún ẹnìkejì lọ́dọ̀ Ọlọ́run, bí ènìyàn kan ti íṣe alágbàwí fún ẹnìkejì rẹ̀.

21

22“Nítorí nígbà tí iye ọdun díẹ̀ rékọjá tán, nígbà náà ni èmi ó lọ sí ibi tí èmi kì yóò padà bọ̀.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>