1“Ẹ̀mí mi bàjẹ́, ọjọ́ mi ni a ti gé kúrú, ìsà òkú dúró dè mí.
2Nítòótọ́ àwọn ẹlẹ́yà h wà lọ́dọ̀ mi, ojú mi sì tẹ̀mọ́ ìmúnibínú wọn.
2
3“Ǹjẹ́ nísinsínyí, fi lélẹ̀ yàn onígbọ̀wọ́ fún mi lọ́dọ̀ rẹ; ta ni OLÚWA tí yóò le ṣe ààbò fún mi?
4Nítorí pé ìwọ ti ṣé wọ́n láyà kúrò nínú òyè; nítorí náà ìwọ kì yóò gbé wọn lékè.
5Ẹni tí ó fi àwọn ọ̀rẹ́ hàn fún ìgárá, òun ni ojú àwọn ọmọ rẹ̀ yóò mú òfo.
5
6“Ọlọ́run ti sọ mi di ẹni òwe fún àwọn ènìyàn; níwájú wọn ni mo dàbí ẹni ìtutọ́ sí ní ojú.
7Ojú mí ṣú bàìbàì nítorí ìbìnújẹ́, gbogbo ẹ̀yà ara mi sì dàbí òjìji.
8Àwọn olódodo yóò yanu sí èyí, ẹni aláìsẹ̀ sì bínú sí àwọn àgàbàgebè.
9Olódodo pẹ̀lú yóò di ọ̀nà rẹ̀ mú, àti ọlọ́wọ́ mímì yóò máa lera síwájú.
9
10“Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti gbogbo yín, ẹ yí padà, kí ẹ sì tún bọ̀ nísinsin yìí; èmi kò le rí ọlọgbọ́n kan nínú yín.
11Ọjọ́ tí èmi ti kọjá, ìro mi ti fà já, àní ìro ọkàn mi.
12Àwọn ènìyàn wọn yí ìsọ́ òru di ọ̀sán; wọ́n ní, ìmọ́lẹ̀ súnmọ́ ibi tí òkùnkùn dé.
13Bí mo tilẹ̀ ní ìrètí, ipò òku ní ilé mi; mo ti tẹ́ ìbùsùn mi sínú òkùnkùn.
14Èmi ti wí fún ìdibàjẹ́ pé, ìwọ ni baba mi, àti fún kòkòrò pé, ìwọ ni ìyá mi àti arábìnrin mi,
15Ìrètí mi ha dà nísinsinyí? Bí ó ṣe ti ìrètí mi ni, ta ni yóò rí i?
16Yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ipò òkú, nígbà tí a jùmọ̀ sinmi pọ̀ nínú erùpẹ̀ ilẹ̀?”