Ìwé Jóòbù 18:1-21 BYB2014 - Bible AI

1Ígbà náà ni Bílídádì, ará Ṣúà, dáhùn, ó sì wí pé:

2“Nígbà wo ni ẹ̀yin yóò tó fi ìdí ọ̀rọ̀ tì; ẹ rò ó, nígbẹ̀yìn rẹ̀ ni àwa ó tó máa sọ

3Nítorí kí ni a ṣe ń kà wá sí bí ẹranko, tí a sì ń kà wá si bí ẹni ẹ̀gàn ní ojú yín?

4Ìwọ fa ara rẹ ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ nínú ìbínú rẹ̀; kí a ha kọ ayé sílẹ̀ nítorí rẹ̀ bi? Tàbí kí a sí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀?

4

5“Nítòótọ́ ìmọ́lẹ̀ ènìyàn búburú ni a ó pa kúrò, Ọ̀wọ́ iná rẹ̀ kì yóò sì tan ìmọ́lẹ̀.

6Ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn nínú àgọ́ rẹ̀, fìtílà ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni a ó sì pa pẹ̀lú.

7Ìrìn ẹṣẹ̀ agbára rẹ̀ yóò di fífọn; ìmọ́lẹ̀ òun tìkárarẹ̀ ni yóò bí i ṣubú.

8Nípa ẹ̀ṣẹ̀ òun tìkararẹ̀ ó ti bọ́ sínú àwọ̀n, ó sì rìn lóri okùn dídẹ.

9Tàkúté ni yóò mú un ní gìgísẹ̀, àwọn àwọ̀n tí a dẹ yóò sì ṣẹ́gun rẹ̀.

10A dẹkùn sílẹ̀ fún un lórí ilẹ̀, a sì wà ọ̀fìn fún un lojú ọ̀nà.

11Ẹ̀rù ńlá yóò bà á ní ìhà gbogbo, yóò sì lé e dé ẹsẹ̀ rẹ̀.

12Àìlera rẹ̀ yóò di pipa fún ebi, ìparun yóò dìde dúró sí i nígbà tí ó bá ṣubú.

13Yóò jẹ ẹ̀yà ara rẹ̀; àkọ́bí ikú ni yóò jẹ agbára rẹ̀ run.

14A ó fà á tu kurò nínú àgọ́ tí ó gbẹ́kẹ̀lé, a ó sì mú un tọ ọba ẹ̀rù ńlá nì lọ.

15Yóò sì máa jókòó nínú àgọ́ rẹ̀ èyí tí í ṣe tirẹ̀; ìmí ọjọ́ ni a ó fún káàkiri ibùgbé rẹ̀.

16Gbòngbò rẹ̀ yóò gbẹ níṣàlẹ̀, a ó sì ké ẹ̀ka rẹ̀ kúrò lókè.

17Ìrántí rẹ̀ yóò parun kúrò ni ayé, kì yóò sí orúkọ rẹ̀ ní ìgboro ìlú.

18A ó sì lée láti inú ìmọ́lẹ̀ sí inú òkùnkùn, a ó sì lé e kúrò ní ayé.

19Kì yóò ní ọmọ tàbí ọmọ ọmọ nínu àwọn ènìyàn rẹ̀, Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹnikẹ́ni tí yóò kù nínú agbo ilé rẹ̀.

20Ẹnu yóò ya àwọn ìran ti ìwọ̀ oòrùn sí ìgbà ọjọ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rù ìwárìrì ti í bá àwọn ìran ti ìlà oòrùn.

21Nítòótọ́ irú bẹ́ẹ̀ ni ibùgbé àwọn ènìyàn búburú Èyí sì ni ipò ẹni tí kò mọ̀ Ọlọ́run.”

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>