Ìwé Jóòbù 19:1-29 BYB2014 - Bible AI

1Ígbà náà ni Jóòbù dáhùn, ó sì wí pé:

2“Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ̀yin ó fi máa fi ìyà jẹ mí, tí ẹ̀yin ó fi máa fi ọ̀rọ̀ mi ní ìjàǹjá?

3Ìgbà mẹ́wàá ní ẹ̀yin ti ń gàn mí; ojú kò tìyín tí ẹ fi jẹ mí níyà.

4Kí a sì wí bẹ́ẹ̀ pé, mo sìnà nítòótọ́, ìsìnà mi wà lára èmi tìkáarami.

5Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ̀yin ó ṣògo si mi lórí nítòótọ́, tí ẹ ó sì máa fi ẹ̀gàn mi gún mí lójú,

6Kí ẹ mọ̀ nísinsin yìí pé, Ọlọ́run ni ó bì mí ṣubú, ó sì nà àwọ̀n rẹ̀ yí mi ká.

6

7“Kiyè sì í, èmi ń kígbe pe, ‘Ọwọ́ alágbára;’ ṣùgbọ́n a kò gbọ́ ti èmi; mo kígbe fún ìrànlọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ìdajọ́.

8Ó sọgbà dí ọ̀nà mi tí èmi kò le è kọjá, Ó sì mú òkùnkùn ṣú sí ipa ọ̀nà mi.

9Ó ti bọ́ ògo mi, ó sì sí adé kúrò ní orí mi.

10Ó ti bà mí jẹ́ ní ìhà gbogbo, ẹ̀mí sì pin; ìrètí mi ni a ó sì fàtu bí igi.

11Ó sì tinábọ ìbínú rẹ̀ sími, ó sì kà mí sí bí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀tá rẹ̀.

12Ẹgbẹ́ ogun rẹ̀ sì dàpọ̀ sí mi, wọ́n sì mọ odi yí mi ká, wọ́n sì yí àgọ́ mi ká.

12

13“Ó mú àwọn arákùnrin mi jìn nà sí mi réré, àti àwọn ojúlùmọ̀ mi di àjèjì sí mi pátapáta.

14Àwọn alájọbí mi fà sẹ́yìn, àwọn afaramọ́ ọ̀rẹ́ mi sì di onígbàgbé mi.

15Àwọn ará inú ilé mi àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin mi kà mí sí àjèjì; èmi jásí àjèjì ènìyàn ní ojú wọn.

16Mo pe ìránṣẹ́ mi, òun kò sì dá mi lóhùn; mo fi ẹnu mi bẹ̀ ẹ́.

17Ẹ̀mí mi sú àyà mi, àti òòrun mi sú àwọn ọmọ inú ìyá mi.

18Àní àwọn ọmọdé kùnrin fi mí ṣẹ̀sín: Mo dìde, wọ́n sì sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi.

19Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ kòríkòsùn mi kórìíra mi, àwọn olùfẹ́ mi sì kẹ̀yìndà mí.

20Egungun mi lẹ̀ mọ́ ara mi àti mọ́ ẹran ara mi, mo sì bọ́ pẹ̀lú awọ eyín mi.

20

21“Ẹ ṣáànú fún mi, ẹ ṣàánú fún mi, ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, nítorí ọwọ́ Ọlọ́run ti bà mí.

22Nitorí kí ni ẹ̀yin ṣe lépa mi bí Ọlọ́run, tí ẹran ara mi kò tẹ́ yín lọ́rùn?

22

23“Áà! Ìbáṣe pé a le kọ̀wé ọ̀rọ̀ mi nísinsìn yìí, ìbáṣepé a le dà á sínú ìwé!

24Kí a fi kálàmú irin àti ti òjé kọ wọ́n sínú àpáta fún láéláé.

25Nítorí èmi mọ̀ pé olùdáùndè mi ń bẹ láàyè àti pe òun ni yóò dìde dúró lórí ilẹ̀ ní ìkẹyìn;

26Àti lẹ́yìn ìgbà tí a pa àwọ̀ ara mi run, síbẹ̀ láìsí ẹran ara mi ni èmi ó rí Ọlọ́run,

27Ẹni tí èmi ó rí fún ara mi, tí ojú mi ó sì wo, kì sì íṣe ti ẹlòmìíràn; ọkàn mi sì dákú ní inú mi.

27

28“Bí ẹ̀yin bá wí pé, ‘àwa ó ti lépa rẹ̀ tó! Àti pé, gbogbo ọ̀rọ̀ náà ni a ṣáà rí ní ọwọ́ rẹ̀,’

29Kí ẹ̀yin kí ó bẹ̀rù; nítorí ìbínú ní ímú ìjìyà wá nípa ìdà Kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé ìdájọ́ kan ń bẹ.”

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>