Ìwé Jóòbù 20:1-29 BYB2014 - Bible AI

1Ígbà náà ní Sófárì, ara Náámà dáhùn, ó sì wí pé:

2“Nítorí náà ní ìro inú mi dá mi lóhùn, àti nítorí èyí náà ní mo sì yára si gidigidi.

3Mo ti gbọ́ ẹ̀san ẹ̀gàn mi, ẹ̀mí òye mi sì dá mi lóhùn.

3

4“Ìwọ kò mọ̀ èyí rí ní ìgbà àtijọ́, láti ìgbà tí a sọ ènìyàn lọ́jọ̀ silẹ̀ ayé,

5Pé, orin ayọ̀ ènìyàn búburú, ìgbà kúkúrú ni, àti pé, ní ìṣẹ́jú kan ní ayọ̀ àgàbàgebè?

6Bí ọláńlá rẹ̀ tilẹ̀ gòkè dé ọ̀run, ti ori rẹ̀ sì kan àwọsánmà;

7Ṣùgbọ́n yóò ṣègbé láéláé bí ìgbẹ́ ara rẹ̀; àwọn tí ó ti rí i rí yóò wí pé, ‘Òun ha dà?’

8Yóò fò lọ bí àlá, a kì yóò sì rí i, àní a ó lé e lọ bi ìran òru.

9Ojú tí ó ti rí i rí kì yóò sì rí i mọ́, bẹ́ẹ̀ ni ibùjókòó rẹ̀ kì yóò sì ri i mọ́.

10Àwọn ọmọ rẹ̀ yóò máa wá àti rí ojú-rere lọ́dọ̀ talákà, ọwọ́ rẹ̀ yóò sì kó ọrọ̀ wọn padà.

11Egungun rẹ̀ kún fún agbára ìgbà èwe rẹ̀, tí yóò bá a dùbúlẹ̀ nínú erùpẹ̀.

11

12“Bí ìwà búburú tilẹ̀ dún ní ẹnu rẹ̀, bí ó tilẹ̀ pa á mọ́ nísàlẹ̀ ahọ́n rẹ̀,

13bí ó tilẹ̀ dá a sí, tí kò si kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tí ó pa á mọ́ síbẹ̀ ní ẹnu rẹ̀,

14Ṣùgbọ́n oúnjẹ rẹ̀ nínú ikùn rẹ̀ ti yípadà, ó jásí òróró pamọ́lẹ̀ nínú rẹ̀;

15Ó ti gbé ọrọ̀ mì, yóò sì tún bí i jáde; Ọlọ́run yóò pọ̀ ọ́ yọ jáde láti inú rẹ̀ wá.

16Ó ti fà oró pamọ́lẹ̀ múu; ahọ́n gúnte ní yóò pa á.

17Kì yóò rí odò wọ̀n-ọn-nì, ìṣàn omi, odò tí ń sàn fún oyin àti ti òrí àmọ́.

18Ohun tí ó ṣíṣẹ́ fún ni yóò mú un padà, kí yóò sì gbé e mì; gẹ́gẹ́ bí ọrọ̀ tí ó ní, kì yóò sì yọ̀ nínú rẹ̀.

19Nítorí tí ó fi owó rẹ̀ ni talákà lára, ó sì ti kẹ́hìndà wọ́n; Nítorí ti ó fi agbára gbé ilé tí òun kò kọ́.

19

20“Nítorí òun kò mọ̀ ìwà pẹ̀lẹ́ nínú ara rẹ̀, kì yóò sì gbà nínú èyí tí ọkán rẹ̀ fẹ́ sílẹ̀.

21Ohun kan kò kù fún jíjẹ́ rẹ̀; Nitorí náà ọ̀rọ̀ rẹ̀ kì yóò dúró pẹ́.

22Nínú ànító rẹ̀, ìdààmú yóò dé bá a; àwọn ènìyàn búburú yóò dáwọ́ jọ lé e lórí.

23Yóò sì ṣe, nígbà tí ó bá fẹ́ jẹun Ọlọ́run yóò fà ríru ìbínú rẹ̀ sí í lórí, nígbà tó bá ń jẹun lọ́wọ́, yóò sì rọ òjò ìbínú rẹ̀ lé e lórí.

24Yóò sá kúrò lọ́wọ́ ohun ogun ìrìn; ọrun akọ irin ní yóò ta a po yọ.

25O fà á yọ, ó sì jáde kúrò lára; idà dídán ní ń jáde láti inú òróòro wá: Ẹ̀rù ńlá ń bẹ ní ara rẹ̀.

26Òkùnkùn biribiri ní a ti pamọ́ fún ìṣúra rẹ̀; iná ti a kò fẹ́ ní yóò jó o run: yóò sì jẹ èyí tí ó kù nínú àgọ́ rẹ̀ run.

27Ọ̀run yóò fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ hàn, ayé yóò sì dìde dúró sí i.

28Ìbísí ilé rẹ̀ yóò kọjá lọ, àti ohun ìní rẹ̀ yóò ṣàn dànù lọ ni ọjọ́ ìbínú Ọlọ́run.

29Èyi ni ìpín ènìyàn buburú láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá, àti ogún tí a yàn sílẹ̀ fún un láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>