Ìwé Jóòbù 21:1-34 BYB2014 - Bible AI

1Jóòbù wá dahùn, ó sì wí pé:

2“Ẹ tẹ́tí silẹ̀ dẹdẹ sì àwọn ọ̀rẹ́ mi, kí èyí kí ó jásí ìtùnú tí ó fún mi.

3Ẹ jọ̀wọ́ mi ki èmi sọ̀rọ̀; lẹ́yìn ìgbà tí mo bá sọ tán, ìwọ máa fi ṣẹ̀sín ń ṣo.

3

4“Bí ó ṣe tí èmi ni, àròyé mi iṣe sí ènìyàn bí? Tàbí èétíṣe tí ọkàn mi kì yóò fi ṣe àìbalẹ̀?

5Ẹ wò mí fín, kí ẹnu kí ó sì yà yín, kí ẹ sì fi ọwọ́ lé ẹnu yín.

6Àní nígbà tí mo rántí, ẹ̀rù bà mí, ìwárìrì sì mú mi lára.

7Nítorí kí ní ènìyàn búburú fi wà ní ayé, tí wọ́n gbó, àní tí wọ́n di alágbára ní ipa?

8Irú ọmọ wọn fi ìdí kalẹ̀ ní ojú wọn pẹ̀lú wọn, àti ọmọ-ọmọ wọn ní ojú wọn.

9Ilé wọn wà láìní ewu àti ẹ̀rù, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pá iná Ọlọ́run kò sí lára wọn.

10Akọ màlúù wọn a máa gùn, kì ísì íṣe; abo màlúù wọn a máa bí, kì í sì í ṣẹ́yun;

11Wọn a máa rán àwọn ọmọ wọn wẹ́ẹ́wẹ́ẹ́ jáde bí agbo ẹran, àwọn ọmọ wọn a sì máa jó kiri.

12Wọ́n mú ohun ọ̀nà orin, ìlù àti háápù, wọ́n sì ń yọ̀ sí ohùn fèrè

13Wọ́n ní ọjọ́ wọn nínú ọrọ̀; wọn sì lọ sí ipò òkú ní àlàáfíà.

14Nítorí náà ni wọ́n ṣe wí fún Ọlọ́run pé, lọ kúrò lọ́dọ̀ wa, nítorí pé wọn kò fẹ́ ìmọ̀ ipa ọ̀nà rẹ!

15Kí ni Olódùmarè tí àwa ó fi máa sìn in? Èrè kí ni a ó sì jẹ bí àwa ba gbàdúrà sí i?

16Kíyè sí i, àlàáfíà wọn kò sí nípa ọwọ́ wọn; ìmọ̀ ènìyàn búburú jìnnà sí ni réré.

16

17“Ìgbà mélòómélòó ní a ń pa iná ènìyàn búburú kú? Ìgbà mélòómélòó ní ìparun wọn dé bá wọn, tí Ọlọ́run sì í máa pín ìbìnújẹ́ nínú ìbínú rẹ̀?

18Wọ́n dàbí àkékù oko níwájú afẹ́fẹ́, àti bí ìyàngbò, tí ẹfúùfù ńlá fẹ́ lọ.

19Ẹ̀yin wí pé, ‘Ọlọ́run to iya ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jọ fún àwọn ọmọ rẹ̀.’ Jẹ́ kí ó san án fún un, yóò sì mọ̀ ọ́n.

20Ojú rẹ̀ yóò rí ìparun ara rẹ̀, yóò sì máa mu nínú ríru ìbínú Olódùmarè.

21Nítorí pé àlàáfíà kí ni ó ní nínú ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, nígbà tí a bá ké iye oṣù rẹ̀ kúrò ní agbede-méjì?

21

22“Ẹnikẹ́ni le íkọ́ Ọlọ́run ní ìmọ̀? Òun ní í sáa ń ṣe ìdájọ́ ẹni ibi gíga.

23Ẹnìkan a kú nínu pípé agbára rẹ̀, ó wà nínú ìrọra àti ìdákẹ́ pátapáta.

24Ọpọ́n rẹ̀ kún fún omi ọmú, egungun rẹ̀ sì tutù fún ọ̀rá.

25Ẹlòmìíràn a sì kú ninú kíkorò ọkàn rẹ̀, tí kò sì fi inú dídùn jẹun.

26Wọ́n o dùbúlẹ̀ bákan náà nínú erùpẹ̀, kòkòrò yóò sì ṣùbò wọ́n.

26

27“Kíyèsí i, èmi mọ̀ ìrò inú yín àti àrékérekè ọkàn yín láti ṣe ìlòdì sí mi.

28Nítorí tí ẹ̀yin wí pé, ‘Níbo ní ilé ọmọ aládé, àti níbo ní àgọ́ àwọn ènìyàn búburú nì gbé wà?’

29Ẹ̀yin kò béèrè lọ́wọ́ àwọn tí ń kọjá lọ ní ọ̀nà? Ẹ̀yin kò mọ̀ àmì wọn, pé

30Ènìyàn búburú ní a fi pamọ́ fún ọjọ́ ìparun? A ó sì mú wọn jáde ní ọjọ́ ríru ìbínú.

31Ta ni yóò sọ ipa ọ̀nà rẹ̀ kò ó ní ojú, ta ni yóò sì san án padà fún un ní èyí tí ó ti ṣe?

32Síbẹ̀ a ó sì sin ín ní ọ̀nà ipò òkú, a ó sì máa ṣọ́ ibojì òkú.

33Ògúlùtù àfonífojì yóò dùn mọ́ ọn. Gbogbo ènìyàn yóò sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, bí ènìyàn àìníye ti lọ ṣíwájú rẹ̀.

33

34“Èé ha ti ṣe tí ẹ̀yin fi ń tù mí nínú lásán, bí ò ṣepé ní ìdáhùn yín, eké kù níbẹ̀!”

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>