Ìwé Jóòbù 22:1-30 BYB2014 - Bible AI

1Ígbà náà ni Élífásì, ará Témà, dáhùn wí pé:

2ⓐ “Ènìyàn lè è ṣe rere fún Ọlọ́run? Bí ọlọ́gbọ́n ti í ṣe rere fún ara rẹ̀?

3Ohun ayọ̀ ha ni fún Olódùmáarè pé, olódodo ni ìwọ? Tàbí èrè kí ni fún un, ti ìwọ mú ọ̀nà rẹ̀ pé?

3

4“Yóò ha bá ọ wí bí, nítorí ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ? Yóò ha bá ọ lọ sínú ìdájọ́ bí?

5Ìwà búburú rẹ kò ha tóbi, àti ẹ̀ṣẹ̀ rẹ láìníye?

6Nítòótọ́ ìwọ bèèrè fún ààbò ni ọwọ́ arákùnrin rẹ láìnídìí, ìwọ sì tú oníhòhò ní aṣọ wọn.

7Ìwọ kò fi omi fún aláàárẹ̀ mu, ìwọ sì háwọ́ oúnjẹ fún ẹni tí ebi ń pa.

8Bí ó ṣe ti alágbára nì ni, òun ni ó ní ilẹ̀, ọlọ́lá sì tẹ̀dó sínú rẹ̀.

9Ìwọ ti rán àwọn opó padà lọ ní ọwọ́ òfo; Apá àwọn ọmọ aláìní baba ti di ṣiṣẹ́.

10Nítorí náà ni ìdẹkùn ṣe yí ọ káàkiri, àti ìbẹ̀rù òjijì ń yọ ọ́ lẹ́nu,

11Èé ṣe tí òkùnkùn, fi pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ìwọ kò fi lè ríran; Èé ṣe tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi sì bò ọ́ mọ́lẹ̀.

11

12“Ọlọ́run kò ha jẹ́ ẹni gíga ọ̀run? Ṣá wò orí àwọn ìràwọ̀ bí wọ́n ti ga tó!

13Ìwọ sì wí pé, Ọlọ́run ti ṣe mọ̀? Òun ha lè ṣe ìdájọ́ láti inú òkùnkùn wá bí?

14Àwọ̀sánmọ̀ tí ó nípọn ni ìbora fún un, tí kò fi lè ríran; ó sì rìn nínú àyíká ọ̀run.

15Ìwọ fẹ́ rìn ìpa ọ̀nà ìgbàanì tí àwọn ènìyàn búburú tí rìn?

16A ké wọn lulẹ̀ kúrò nínú ayé láìpé ọjọ́ wọn; ìpilẹ̀ wọn ti dé bí odò síṣàn;

17Àwọn ẹni tí ó wí fún Ọlọ́run pé, lọ kúrò lọ́dọ̀ wa! Kí ni Olódùmárè yóò ṣe fún wọn?

18Ṣíbẹ̀ ó fi ohun rere kún ilé wọn! Ṣùgbọ́n ìmọ̀ ènìyàn búburú jìnnà sí mi!

18

19“Àwọn olódodo rí ìparun wọn, wọ́n sì yọ̀, àwọn aláìlẹ̀ṣẹ̀ sì fi wọ́n rẹ́rìn ín ẹlẹ́yà pé,

20Lótìítọ́ àwọn ọ̀ta wa ni a ké kúrò, iná yóò sì jó oró wọn run.

20

21“Fa ara rẹ súnmọ́ Ọlọ́run, ìwọ ó sì rí àlàáfíà; Pẹ̀lú rẹ̀ nípa èyí ni rere yóò wá bá ọ.

22Èmi bẹ̀ ọ́, gba òfin láti ẹnu rẹ̀ wá, kí o sì tò ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àyà rẹ.

23Bí ìwọ bá yípadà sọ́dọ̀ Olódùmáarè, a sì gbé ọ ró, bí ìwọ bá sì mú ẹ̀ṣẹ̀ jìnnà réré kúrò nínú àgọ́ rẹ,

24Tí ìwọ bá tẹ́ wúrà dáradára sílẹ̀ lórí erùpẹ̀ àti wúrà ófiri lábẹ́ òkúta odò,

25Nígbà náà ní Olódùmáarè yóò jẹ́ wúrà rẹ, àní yóò sì jẹ́ fàdákà fún ọ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.

26Lótìítọ́ nígbà náà ní ìwọ ó ní inú dídùn nínú Olódùmáarè, ìwọ ó sì gbé ojú rẹ sókè sọ́dọ̀ Ọlọ́run.

27Bí ìwọ bá gbàdúrà rẹ sọ́dọ̀ rẹ̀, yóò sì gbọ́ tìrẹ, ìwọ ó sì san ẹ̀jẹ́ rẹ.

28Ìwọ ó sì gbìmọ̀ ohun kan pẹ̀lú, yóò sì fi ìdí múlẹ̀ fún ọ; ìmọ́lẹ̀ yóò sì mọ́ sípa ọ̀nà rẹ.

29Nígbà tí ipa-ọ̀nà rẹ bá lọ sísàlẹ̀, nígbà náà ni ìwọ o wí pé, ‘Ìgbésókè ń bẹ!’ Ọlọ́run yóò sì gba onírẹ̀lẹ̀ là!

30Yóò gba ẹni tí kì í iṣe aláìjẹ̀bi là, a ó sì gbà á nípa mímọ́ ọwọ́ rẹ̀.”

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>