1Ígbà náà ni Jóòbù sì dáhùn wí pé:
2“Àní lónìí ni ọ̀ràn mi korò; ọwọ́ mí sì wúwo sí ìkérora mi.
3Áà! èmi ìbá mọ ibi tí èmí ìbá wá Ọlọ́run rí, kí èmí kí ó tọ̀ ọ́ lọ sí ibùgbé rẹ̀!
4Èmi ibá sì to ọ̀ràn náà níwájú rẹ̀, ẹnu mi ìbá sì kún fún àròyé.
5Èmi ìbá sì mọ ọ̀rọ̀ tí òun ìbá fi dá mi lóhùn; òye ohun tí ìbá wí a sì yé mi.
6Yóò ha fi agbára ńlá bá mi wíjọ́ bí? Àgbẹdọ̀, kìkì pé òun yóò sì kíyèsí mi.
7Níbẹ̀ ni olódodo le è bá a wíjọ́, níwájú rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì bọ́ ni ọwọ́ onídájọ́ mi láéláé.
7
8“Sì wòó, bí èmi bá lọ sí iwájú, òun kò sí níbẹ̀, àti sí ẹ̀yìn, èmi kò sì rí òye rẹ̀:
9Ni apá òsì bí ó bá ṣiṣẹ́ níbẹ̀, èmi kò rí i, ó fi ara rẹ̀ pamọ́ ni apa ọ̀tún, tí èmi kò le è rí i.
10Ṣùgbọ́n òun mọ ọ̀nà tí èmi ń tọ̀, nígbà tí ó bá dán mí wò, èmi yóò jáde bí wúrà.
11Ẹṣẹ̀ mí ti tẹ̀lé ipaṣẹ̀ ìrìn rẹ̀; ọ̀nà rẹ̀ ni mo ti kíyèsí, tí ń kò sì yà kúrò.
12Bẹ́ẹ̀ ni èmi kò padà sẹ́yìn kúrò nínú òfin ẹ̀nu rẹ̀, èmi sì pa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ mọ́ ju oúnjẹ òòjọ́ lọ
12
13“Ṣùgbọ́n onínú kan ni òun, ta ni yóò sì yí i padà? Èyí tí ọkàn rẹ̀ sì ti fẹ́, èyí náà ní í ṣe.
14Nítòótọ́ ohun tí a ti yàn fún mi ní í ṣe; ọ̀pọ̀lọpọ̀ irú bẹ́ẹ̀ ni ó wà ní ọwọ́ rẹ̀.
15Nítorí náà ni ara kò ṣe rọ̀ mí níwájú rẹ̀; nígbà tí mo bá rò ó, ẹ̀rù a bà mi.
16Nítorí pé Ọlọ́run ti pá mi ní àyà, Olodùmáarè sì ń dààmú mi,
17Nítorí tí a kò tí ì ké mi kúrò níwájú òkùnkùn, bẹ́ẹ̀ ni kò pa òkùnkùn biribiri mọ́ kúrò níwájú mi.