2“Ìjọba àti ẹ̀ru ḿbẹ lọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀, òun ní iṣe ìlàjà ní ibi gígagíga ọ̀run.
3Àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ha ní ìyè bí, tàbí ara tani ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ kò tàn sí?
4Èé ha ti ṣe tí a ó fi dá ènìyàn láre lọ́dọ̀ Ọlọ́run? Tàbí ẹni tí a bí láti inú obìnrin wá yóò ha ṣe mọ́?
5Kíyèsí i, òṣùpá kò sì lè í tàn ìmọ́lẹ̀, àní àwọn ìràwọ kò mọ́lẹ̀ ní ojú rẹ̀.
6Áḿbọ̀torí ènìyàn tí iṣe ìdin, àti ọmọ ènìyàn tí iṣe kòkòrò!”