Ìwé Jóòbù 26:1-14 BYB2014 - Bible AI

1Ṣùgbọ́n Jóòbù sì dáhùn wí pé:

2Báwo ni ìwọ ń ṣe ìrànlọ́wọ́ ẹni tí kò ní ipá, báwo ní ìwọ ń ṣe gbà apá ẹni tí kò ní agbára?

3Báwo ni ìwọ ń ṣe ìgbìmọ̀ ẹni tí kò ní ọgbọ́n, tàbí báwo ní ìwọ sọdi ọ̀ràn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ bí ó ti rí?

4Ta ni ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, àti ẹ̀mi ta ni ó gba ẹnu rẹ sọ̀rọ̀?

4

5“Àwọn aláìlágbára ti iṣà òkú wárìrì, lábẹ́ omi pẹ̀lú àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

6Ìhòòhò ni ipò òkú níwájú Ọlọ́run, ibi ìparun kò sí ní ibojì.

7Òun ní o nà ìhà àríwá ọ̀run ní ibi òfùrufú, ó sì fi ayé rọ̀ ní ojú òfo.

8Ó di omi pọ̀ nínú ìkùùkù àwọsánmọ̀ rẹ̀ tí ó nípọn; àwọsánmọ̀ kò sì ya nísàlẹ̀ wọn.

9Ó sì fa ojú ìtẹ́ rẹ̀ sẹ́yìn, ó sì tẹ àwọsánmọ̀ rẹ̀ sí i lórí.

10Ó fi idẹ yí omi òkun ká, títí dé ààlà ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn.

11Ọ̀wọ̀n òpó ọ̀run wárìrì, ẹnu sì yà wọ́n sì ìbàwí rẹ̀.

12Ó fi ipá rẹ̀ dààmú omi òkun; nípa òye rẹ̀, ó gé Ráhábù sí wẹ́ẹ́wẹ́.

13Nípa ẹ̀mí rẹ̀ ni ó ti ṣe ọ̀run ní ọ̀sọ́; ọwọ́ rẹ̀ ni ó ti dá ejò wíwo nì.

14Kíyèsí i, èyí ní òpin ọ̀nà rẹ̀; ohùn èyí tí a gbọ́ ti kéré tó! Ta ni ẹni náà tí òye àrá agbára rẹ̀ lè yé?”

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>