Ìwé Jóòbù 27:1-23 BYB2014 - Bible AI

1Pẹ̀lúpẹ̀lú Jóòbù sì tún sọ kún ọ̀rọ̀ òwe rẹ̀, ó sì wí pé:

2“Bí Ọlọ́run ti ń bẹ, ẹni tí ó gba ìdájọ́ mi lọ, àti Olódùmárè tí ó bà mi ní ọkàn jẹ́;

3(Níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀mí mi ń bẹ nínú mi, àti tí ẹ̀mi Ọlọ́run ń bẹ nínú ihò imú mi.)

4Ètè mi kì yóò sọ̀rọ̀ èké, Bẹ́ẹ̀ ni ahọ́n mi kì yóò sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn.

5Kí a má ríi pé èmi ń dá yín láre; títí èmi ó fi kú, èmi kì yóò sí ìwà òtítọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi.

6Òdodo mi ni èmi dìmú ṣinṣin, èmi kì yóò sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́; àyà mi kì yóò sì gan ọjọ́ kan nínú ọjọ́ ayé mi.

6

7“Kí ọ̀ta mi kí ó dàbí ènìyàn búburú, àti ẹni tí ń dìde sími kí ó dàbí ẹni aláìsòdodo.

8Nítorí kí ni ìrètí àgàbàgebè, nígbà tí Ọlọ́run bá ké ẹ̀mí rẹ̀ kúrò, nígbà tí ó sì fà á jáde?

9Ọlọ́run yóò ha gbọ́ àdúrà rẹ̀, nígbà tí ìpọ́jú bá dé sí i?

10Òun ha le ní inú dídùn sí Olódùmarè? Òun ha lé máa képe Ọlọ́run nígbà gbogbo?

10

11“Èmi ó kọ́ yín ní ẹ̀kọ́ ní ti ọwọ́ Ọlọ́run: ọ̀nà tí ńbẹ lọ́dọ̀ Olódùmarè ni èmi kì yóò fi pamọ́.

12Kíyèsí i, gbogbo yín ni ó ti rí i; nítorí kí ni ẹ̀yin ṣe já sí asán pọ̀ bẹ́ẹ̀?

12

13“Ẹ̀yin ni ìpín ènìyàn búburú lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àti ogún àwọn aninilára, tí wọ́n ó gbà lọ́wọ́ Olódùmáre:

14Bí àwọn ọmọ rẹ bá di púpọ̀, fún idà ni; àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ kì yóò yó fún oúnjẹ.

15Àwọn tí ó kú nínú tirẹ̀ ni a ó sìnkú nínú àjàkálẹ̀-àrùn: àwọn opó rẹ̀ kì yóò sì sunkún fún wọn.

16Bí ó tilẹ̀ kó fàdákà jọ bí erùpẹ̀, tí ó sì dá aṣọ jọ bí amọ̀;

17Àwọn ohun tí ó tò jọ àwọn olóòótọ́ ni yóò lò ó; àwọn aláìṣẹ̀ ni yóò sì pín fàdákà rẹ̀.

18Òun kọ́ ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí kòkòrò aṣọ, àti bí ahéré tí olùsọ́ kọ́.

19Ọlọ́rọ̀ yóò dùbúlẹ̀, ṣùgbọ́n òun kì yóò tún ṣe bẹ́ẹ̀ mọ́; ó síjú rẹ̀, òun kò sì sí. Nígbà tí ó bá la ojú rẹ̀, gbogbo rẹ̀ a lọ

20Ẹ̀rù ńlá bàá bí omi ṣíṣàn; ẹ̀fúùfù ńlá jí i gbé lọ ní òru.

21Ẹ̀fúùfù ìlà oòrùn gbé e lọ, òun sì lọ; àti bí ìjì ńlá ó sì fà á kúrò ní ipò rẹ̀.

22Nítorí pé Olódùmárè yóò kọ lù ú, kì yóò sì dá a sí; òun ìbá yọ̀ láti sá kúrò ní ọwọ́ rẹ̀.

23Àwọn ènìyàn yóò sì ṣápẹ́ sí i lórí, wọn yóò sì ṣe síọ̀ sí i kúrò ní ipò rẹ̀.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>