Ìwé Jóòbù 28:1-28 BYB2014 - Bible AI

1“Nítòótọ́, koto fàdákà ń bẹ, àti ibi tí wọ́n ti máa ń da wúrà.

2Nínú ilẹ̀ ni à ń gbé ń wa irin, bàbà ni a sì ń dà láti inú òkúta wá.

3Ènìyàn ni ó parí òkùnkùn, ó sì ṣe àwárí òkúta òkùnkùn àti ti inú òjìji ikú sí ìhà gbogbo.

4Wọ́n wa ihò ilẹ̀ tí ó jìn sí àwọn tí ń gbé òkè, àwọn tí ẹṣẹ̀ ènìyàn gbàgbé; wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀, wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀ jìnnà sí àwọn ènìyàn.

5Bí ó ṣe ti ilẹ̀ ni, nínú rẹ̀ ni oúnjẹ ti ń jáde wá, àti ohun tí ó wà ní ìṣàlẹ̀ ni ó yí sókè bí ẹni pé iná.

6Òkúta ibẹ̀ ni ibi òkúta Sáfírì, o sì ní erùpẹ̀ wúrà.

7Ipa ọ̀nà náà ni ẹyẹ kò mọ̀, àti ojú gúnnugún kò rí i rí;

8Àwọn ẹrankan agbéraga kò rìn ibẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni kìnnìún tí ń ké ramúramù kò kọjá níbẹ̀ rí.

9Ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé akọ òkúta, ó yí òkè ńlá po láti ìdí rẹ̀ wá.

10Ó sì la ipa odò ṣíṣàn nínú àpáta, ojú inú rẹ̀ sì rí ohun iyebíye gbogbo.

11Ó sì ṣe ìṣàn odò kí ó má ṣe kún —kún-ya, ó sì mú ohun tí ó pamọ́ hàn jáde wá sí ìmọ́lẹ̀.

11

12“Ṣùgbọ́n níbo ni á ó gbé wá ọgbọ́n rí, níbo sì ni òye ń gbe?

13Ènìyàn kò mọ iye rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è rí i ní ilẹ̀ àwọn alààyè.

14Ọ̀gbun wí pé, kò sí nínú mi; omi òkun sì wí pé, kò si nínú mi.

15A kò le è fi wúrà rà á, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi òsùnwọ̀n wọn fàdákà ní iye rẹ̀.

16A kò le è fi wúrà Ófírì, tàbí òkútà Óníkísì iyebíye, tàbí òkúta Sáfírì díye lé e.

17Góòlù àti òkúta Kírísítalì kò tó ẹgbẹ́rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi ohun èló wúrà ṣe pàsípààrọ̀ rẹ̀.

18A kò lè dárúkọ iyùn tàbí òkúta Jásípérì; iye ọgbọ́n sì ju òkúta Rubì lọ.

19Òkùta tópásì ti Kúsì kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le fi wúrà dáradára díwọ̀n iye rẹ̀.

19

20“Níbo ha ni ọgbọ́n ti jáde wá? Tàbí níbo ni òye ń gbé?

21A rí i pé, ó farasinko kúrò ní ojú àwọn alààyè gbogbo, ó sì fara sin fún ẹyẹ ojú ọ̀run.

22Ibi ìparun (Ábádónì) àti ikú wí pé, àwa ti fi etí wa gbúròó rẹ̀.

23Ọlọ́run ni ó mọ òye ipa ọ̀nà rẹ̀, òun ni ó sì mọ ibi tí ó ń gbé

24Nítorí pé ó wòye dé òpin ayé, ó sì rí gbogbo ìsàlẹ̀ ọ̀run,

25Láti dà òṣùwọ̀n fún afẹ́fẹ́, ó sì fi òṣùwọ̀n wọ̀n omi.

26Nígbà tí ó pàsẹ fún òjò, tí ó sì la ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá,

27Nígbà náà ni órí i, ó sì sọ ọ́ jáde; ó pèsè rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ṣe ìwádìí rẹ̀ rí.

28Àti fún ènìyàn ni ó wí pé, ‘Kíyè sí i ẹ̀rù OLÚWA èyí ni ọgbọ́n, àti láti jáde kúrò nínú ìwà búburú èyí ni òye.’ ”

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>