Ìwé Jóòbù 29:1-25 BYB2014 - Bible AI

1Pẹ̀lúpẹ̀lù, Jóòbù sì tún tẹ̀ ṣíwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé:

2“Áà! ìbá ṣe pé èmi wà bí ìgbà oṣù tí ó kọjá, bí ọjọ́ tí Ọlọ́run pamímọ́;

3Nígbà tí fìtílà rẹ tàn sí mi ní orí, àti nípa ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ èmi rìn nínú òkùnkùn já;

4Bí mo tirí nígbà ọ̀dọ́ mi, nígbà tí ọ̀rẹ́ Ọlọ́run tímọ́tímọ́ bùkún ilé mi

5Nígbà tí Olódùmarè wà pẹ̀lú mi, nígbà tí àwọn ọmọ mi wà yí mi ká;

6Nígbà tí èmi fi òrí àmọ́ n wẹ ìsísẹ̀ mi, àti tí àpata ń tú ìsàn òróró jáde fún mi wá.

6

7“Nígbà tí mo jáde la àárin ìlú lọ sí ẹnu ibodè, nígbà tí mo tẹ́ ìtẹ́ mi ní ìgboro,

8Nígbà náà ni àwọn ọmọkùnrin rí mi, wọ́n sì sápamọ́, àwọn àgbà dìde dúró ní ẹṣẹ̀ wọn;

9Àwọn ọmọ aládé dákẹ́ ọ̀rọ̀ sí sọ, wọn a sì fí ọwọ́ wọn lé ẹnu;

10Àwọn ọmọ ọlọ́lá dákẹ́, ahọ́n wọn sì lẹ̀mọ́ èrìgì ẹnu wọn.

11Nígbà tí etí gbọ́, ó sì súre fún mi, àti nígbà tí ojú sì rí mi, ó jẹ́rìí mi;

12Nítorí mo gbà talákà tí n fẹ́ ìrànlọ́wọ́, àti aláìní baba, tí kò sí olùrànlọ́wọ́ fún un

13Ẹni tí ó ń kìlọ̀ súre fún mi, èmi sì mú àyà opó kọrin fún ayọ̀.

14Èmi sì mú òdodo wọ̀ bí aṣọ, ẹ̀tọ́ mi dà bí aṣọ ìgúnwà àti adé ọba.

15Mo ṣe ojú fún afọ́jú mo sì ṣe ẹṣẹ̀ fún amúkùnún.

16Mo ṣe baba fún talákà, mo ṣe ìwádìí ọ̀ràn àjòjì tí èmi kò mọ̀ rí.

17Mo sì ká eyín ẹ̀rẹ̀kẹ́ ìkà ènìyàn, mo sì já ohun ọdẹ náà kúrò ní eyín rẹ̀.

17

18“Nígbà náà ni mo rò pé, ‘Èmi yóò kú nínú ilé mi, èmi yóò sì mú ọjọ́ mi pọ̀ sí i bí i yanrìn.

19Gbòǹgbò mi yóò ta kan omi, ìrì yóò sì sẹ̀ ní gbogbo òru sí ara ẹ̀ka mi.

20Ògo mi yóò wà ní ọ̀tún ní ọ̀dọ̀ mi, ọrun mi sì padà di titun ní ọwọ́ mi’

20

21“Èmi ni ènìyàn ń dẹtí sílẹ̀ sí, wọn a sì dúró, wọn a sì dákẹ́ rọ́rọ́ ní ìmọ̀ràn mi.

22Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ mi, wọn kò tún sọ̀rọ̀ mọ́; ọ̀rọ̀ mi wọ̀ wọ́n ní etí ṣinṣin.

23Wọn a sì dúró dè mí bí ẹni wí pé wọ́n dúró fún ọ̀wọ́ òjò wọn a sì mu nínú ọ̀rọ̀ mi bí ẹní mu nínú òjò àrọ̀-kúrò.

24Èmi sì rẹ́rìn ín sí wọn nígbà tí wọn kò bá gbà á gbọ́; ìmọ́lẹ̀ ojú mi jẹ́ iyebíye síwọn.

25Mo la ọ̀nà sílẹ̀ fún wọn, mo sì jókòó bí olóyè wọn; mo jókòó bí ọba ní àárin ológun rẹ̀; mo sì rí bí ẹni tí ń tu ẹni tí ń sọ̀fọ̀ nínú.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>