Ìwé Jóòbù 3:1-26 BYB2014 - Bible AI

1Ẹ̀yìn èyí ní Jóòbù yanu, ó sì fi ọjọ́ ìbí rẹ̀ ré

2Jóòbù sọ, ó sì wí pé:

3ⓐ “Kí ọjọ́ tí a bi mi kí ó di ìgbàgbé, àti òru ni, nínú èyí tí a wí pé, ‘A loyún ọmọkùnrin kan!’

4Kí ọjọ́ náà kí ó já si òkùnkùn, kí Ọlọ́run kí ó má ṣe kà á sí láti ọ̀run wá; bẹ́ẹ̀ ni kí ìmọ́lẹ̀ kí ó má ṣe mọ́ sí i.

5Kí òkùnkùn àti òjìjì ikú fi ṣe ti ara wọn; kí àwọ-sánmọ̀ kí ó bà lé e; kí ìṣúdúdú ọjọ́ kí ó pa láyà.

6Kí òkùnkùn kí ó ṣú bo òru náà biribiri, kí ó má ṣe yọ pẹ̀lú ọjọ́ ọdún náà: kí ó má ṣe kà a mọ́ iye ọjọ́ oṣù.

7Kí òru náà kí ó yàgàn; kí ohun ayọ̀ kan kí ó má ṣe wọ inú rẹ̀ lọ.

8Kí àwọn tí í fi ọjọ́ gégùn-ún kí o fi gégùn-ún, tí wọ́n mura tán láti ru Léfíátánì sókè.

9Kí ìràwọ̀ òféfé ọjọ́ rẹ̀ kí ó ṣókùnkùn; kí ó má wá ìmọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n kí ó máa mọ́ síi, bẹ́ẹ̀ ni kí ó má ṣe rí àfẹ̀rẹ̀mọ́jú mọ́

10Nítorí tí kò sé ìlẹ̀kùn inú ìyá mi, bẹ́ẹ̀ ni kò pa ìbànújẹ́ rẹ́ ní ojú mi.

10

11“Èéṣe tí èmi kò fi kú láti inú wá, tàbí tí èmi kò fi pín ẹ̀mí ní ìgbà tí mo ti inú jáde wá?

12Èéṣe tí eékún wá pàdé mi, tàbí ọmú tí èmi yóò mu?

13Ǹjẹ́ nísinsìn yìí èmi ìbá ti dúbúlẹ̀ jẹ́ẹ́; èmi a sì dákẹ́, èmi ìbá ti sùn ǹjẹ́ èmi ìbá ti sinmi

14pẹ̀lú àwọn ọba àti ìgbìmọ̀ ayé tí ìmọ́lẹ̀ takété fún ara wọn.

15Tàbí pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé tí ó ní wúrà, tí wọ́n sì fi fàdákà kun ilé wọn

16Tàbí bí ọ̀lẹ̀ tí a sin, èmi kì bá ti sí: bí ọmọ ìṣúnú tí kò rí ìmọ́lẹ̀?

17Níbẹ̀ ni ẹni-búburú síwọ́ ìyọ nilẹ́nu, níbẹ̀ ni ẹni àárẹ̀ wà nínú ìsinmi.

18Níbẹ̀ ni àwọn ìgbèkùn sinmi pọ̀, wọn kò gbóhùn amúnisìn mọ́.

19Àti èwe àti àgbà wà níbẹ̀, ẹrú sì di òmìnira kúrò lọ́wọ́ olówó rẹ̀.

20“Nítorí kí ni a ṣe fi ìmọ́lẹ̀ fún òtòsì, àti ìyè fún ọlọ́kan kíkorò,

21tí wọ́n dúró de ikú, ṣùgbọ́n òun kò wá, tí wọ́n wálẹ̀ wá a jù fún ìṣúra tí a bò mọ́lẹ̀ pamọ́.

22Ẹni tí ó yọ̀ gidigidi, tí inú wọ́n sì dùn nígbà tí wọ́n wá ibojì òkú rí?

23Kí ni a fi ìmọ́lẹ̀ fún ẹni tí ọ̀nà rẹ̀ fi ara pamọ́ fún tí Ọlọ́run sì ṣọgbà yí wọn ká?

24Nítorí pé èémí-ẹ̀dùn wà ṣáájú oúnjẹ mi; ikérora mi sì tú jáde bí omi.

25Nítorí pé ohun náà tí mo bẹ̀rù gidigidi ni ó dé bá mi yìí, àti ohun tí mo fòyà rẹ̀ bá mi ó sì ṣubú lù mí.

26Èmi kò wà ni ìléwu rí, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ní ìsinmi; bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ni ìfàyà balẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀ ìyọnu dé.”

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
>