1“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, àwọn tí mo gbà ní àbúrò ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà, baba ẹni tí èmi kẹ́gàn láti tò pẹ̀lú àwọn ajá agbo-ẹran mi.
2Kí ni ìwúlò agbára ọwọ́ wọn sími, níwọ̀n ìgbà tí agbára wọn ti fi wọ́n sílẹ̀?
3Wọ́n rù nítorí àìní àti ìyàn wọ́n ń rìn káàkiri ní ilẹ̀ gbígbẹ ní ibi ìkọsílẹ̀ ní òru.
4Àwọn ẹni tí ń já ewé iyọ̀ ní ẹ̀bá ìgbẹ́; gbogbo igikígi ni ounjẹ jíjẹ wọn.
5A lé wọn kúrò láàrin ènìyàn, àwọn ènìyàn sì pariwo lé wọn lórí bí ẹní pariwo lé olè lórí.
6A mú wọn gbe inú pàlàpálá òkùta àfonífojì, nínú ihò ilẹ̀ àti ti òkúta.
7Wọ́n ń dún bí ẹranko ní àárin ìgbẹ́, wọ́n kó ara wọn jọpọ̀ ní abẹ́ èṣìsì.
8Àwọn ọmọ ẹni tí òye kò yé, àní àwọn ọmọ lásán, a sì lé wọn jáde kúrò ní orí ilẹ̀.
8
9“Ǹjẹ́ nísinsin yìí, àwọn ọmọ wọn ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà nínú orin; àní èmi di ẹni ìsọ̀rọ̀ sí láàrin wọn.
10Wọ́n kórìíra mi; wọ́n sá kúrò jìnnà sími, wọn kò sì bìkítà láti tutọ́ sími lójú.
11Nítorí Ọlọ́run ti tú okùn ìyè mi, ó sì pọ́n mi lójú; àwọn pẹ̀lú sì dẹ ìjánu níwájú mi.
12Àwọn ènìyàn lásán dìde ní apá ọ̀tún mi; wọ́n tì ẹsẹ̀ mi kúrò, wọ́n sì la ipa ọ̀nà ìparun sílẹ̀ dèmí.
13Wọ́n da ipa ọ̀nà mi rú; wọ́n sì sọ ìparun mi di púpọ̀, àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́.
14Wọ́n ya sími bí i omi tí ó ya gbuuru; ní ariwo ńlá ni wọ́n kó ara wọn ká tì sí mi.
15Ẹ̀rù ńlá bà mí; wọ́n lépa ọkàn mi bí ẹ̀fúùfù, àlàáfíà mi sì kọjá lọ bí àwọ̀ sánmọ̀.
15
16“Àti nísinsin yìí ọkàn mí sì dà jáde síi; ọjọ́ ìpọ́njú mi dì mí mú.
17Òru gún mi nínú egungun mi, ìyí tí ó bù mí jẹ kò sì sinmi.
18Nípa agbára ńlá rẹ̀ Ọlọ́run wà bí aṣọ ìbora fún mi, ó sì lẹ̀mọ́ mi ní ara yíká bí ọrùn aṣọ ìlekè mi.
19Ọlọ́run ti mú mi lọ sínú ẹrẹ̀, èmi sì dàbí eruku àti eérú.
19
20“Èmi ké pè ọ́ ìwọ Ọlọ́run ṣùgbọ́n, ìwọ kò dámi lóhùn; èmi dìde dúró ìwọ sì wò mí lásán.
21Ìwọ padà di ẹni ìkà sími; ọwọ́ agbára rẹ ni ìwọ fi dè mí ní ọ̀nà.
22Ìwọ gbémi sókè sí inú ẹ̀fúùfù, ìwọ múmi fò lọ, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì sọ mí di asán pátapáta.
23Èmi sáà mọ̀ pé ìwọ yóò mú mi lọ sínú ikú, sí ilé ìpéjọ tí a yàn fún gbogbo alààyè.
23
24“Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnìkan kí yóò ha na ọwọ́ rẹ̀ nígbà ìṣubu rẹ̀, tàbí kì yóò ké nínú ìparun rẹ̀.
25Èmi kò ha sunkún bí fún ẹni tí ó wà nínú ìṣòro? Ọkàn mi kò ha bàjẹ́ fún talákà bí?
26Nígbà tí mo fojú sọ́nà fún àlàáfíà, ibi sì dé; nígbà tí mo dúró de ìmọ́lẹ̀, òkùnkùn sì dé.
27Ikùn mí n ru kò sì sinmi; Ọjọ́ ìpọ́njú ti dé bámi.
28Èmí ń rìn kiri nínú ọ̀fọ̀, ṣùgbọ́n kì í ṣe nínú òòrùn; èmi dìde dúró ní àwùjọ mo sì kígbé fún ìrànlọ́wọ́.
29Èmi ti di arákùnrin ìkòokò, èmi di ẹgbẹ́ àwọn ògòǹgò.
30Àwọ̀ mi di dúdú ó sì ń bọ́wọ̀; egungun mi sì jórun fún oru.
31Hapu orin mi pẹ̀lú sì di ti ọ̀fọ̀, àti ìpè orin mi sì di ohùn àwọn tí ń sunkún.