1“Mo ti bá ojú mi dá májẹ̀mu, èmi yó ha ṣe tẹjú mọ́ wúndíá?
2Nítórí pé kí ni ìpín Ọlọ́run láti ọ̀run wá? Tàbí kí ni ogún Olódùmárè láti òkè ọ̀run wá.
3Kò ṣe pé àwọn ènìyàn búburú ni ìparun wà fún, àti àjàkálẹ̀ àrùn fún àwọn oníṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀?
4Òun kò ha ri ipa ọ̀nà mi, òun kò ha sì ka gbogbo ìṣíṣẹ̀ mi?
4
5“Bí ó bá ṣepé èmi bá fi àìṣòótọ́ rìn, tàbí tí ẹsẹ̀ mi sì yára sí ẹ̀tàn;
6(Jẹ́ kí Ọlọ́run wọ̀n mí nínú ìwọ̀n òdodo, kí Ọlọ́run le mọ ìdúró ṣinṣin mi.)
7Bí ẹṣẹ̀ mí bá yà kúrò lójú ọ̀nà, tí àyà mí sì tẹ̀lé ipa ojú mi, tàbí bí àbàwọ́n kan bá sì lẹ̀mọ́ mi ní ọwọ́,
8Ǹjẹ́ kí èmi kí ó gbìn kí ẹlòmìíràn kí ó sì mújẹ, àní kí a fa irú ọmọ mi tu.
8
9“Bí àyà mi bá di fífà sípasẹ̀ obinrin kan, tàbí bí mo bá lọ í ba de ènìyàn ní ẹnu ọ̀nà ilé aládùúgbò mi,
10Ṣùgbọ́n kí àyà mi kí ó lọ ọlọ fún ẹlòmíràn, kí àwọn ẹlòmíràn kí ó tẹ̀ ara wọn ní ara rẹ̀.
11Nítorí pé yóò jẹ́ ohun ìtìjú àní ẹ̀ṣẹ̀ tí a ó ṣe onídàájọ́ rẹ̀
12Nítorí pé iná ní èyí tí ó jó dé ibi ìparun, tí ìbá sì fa gbòǹgbò ohun ìbísí mi gbogbo tu.
12
13“Tí mo bá sì se àìka ọ̀ràn ìránṣẹ́kùnrin mi tàbí ìránṣẹ́bìnrin mi sí, nígbà tí wọ́n bá ń bá mi jà;
14Kí ni èmi ó ha ṣe nígbà tí Ọlọ́run bá dìde? Nígbà tí ó bá sì ṣe ìbẹ̀wò, ohùn kí ni èmi ó dá?
15Ẹni tí ó dá mi ní inú kọ́ ni ó dá a? Ẹnìkan náà kí ó mọ wá ní inú ìyá wa?
15
16“Bí mo bá fa ọwọ́ sẹ́yìn fún ìfẹ́ inú talákà, tàbí bí mo bá sì mú kí ojú opó di aláìríran,
17Tàbí tí mo bá nìkan bu òkèlè mi jẹ, tí aláìní baba kò jẹ nínú rẹ̀;
18Nítorí pé láti ìgbà èwe mi wá ni a ti tọ́ ọ dàgbà pẹ̀lú mi bí ẹni pé baba, èmi sì ń ṣe ìtọ́jú opó láti inú ìyá mi wá:
19Bí èmi bá rí olùpọ́njú láìní aṣọ, tàbí talákà kan láìní ìbora;
20Bí ọkàn rẹ̀ kò bá súre fún mi, tàbí bí ara rẹ̀ kò sì gbóná nípaṣẹ̀ irun àgùntàn mi;
21Bí mo bá sì gbé ọwọ́ mi sókè sí aláìní baba, nítorí pé mo rí ìrànlọ́wọ́ mi ní ẹnu ibodè,
22Ǹjẹ́, ní apá mi kí o wọ́n kúrò ní ọkọ́ èjìká rẹ̀, kí apá mi kí ó sì ṣẹ́ láti egungun rẹ̀ wá.
23Nítorí pé ìparun láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni ẹ̀rù-ńlá fún mi, àti nitorí Ọláńlá rẹ̀ èmi kò le è dúró.
23
24“Bí ó bá ṣe pé mo fi wúrà ṣe ìgbẹ́kẹ̀lé mi, tàbí tí mo bá wí fún fàdákà dídára pé, ‘Ìwọ ni ààbò mi;’
25Bí mo bá yọ̀ nítorí ọrọ̀ mí pọ̀, àti nítorí ọwọ́ mi dẹ lọ́pọ̀lọpọ̀;
26Bí mo bá bojú wo oòrùn nígbà tí ń ràn, tàbí òṣùpá tí ń ràn nínú ìtànmọ́lẹ̀,
27Bí a bá tàn ọkàn mi jẹ: Láti fí ẹnu mi kò ọwọ́ mi:
28Èyí pẹ̀lú ni ẹ̀ṣẹ̀ ti àwọn Onidàájọ́ ní bẹ̀wò. Nítorí pé èmí yóò jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run tí ó wà lókè.
28
29“Bí ó bá ṣepé mo yọ̀ sì ìparun ẹni tí ó korìíra mi. Tàbí bí mo bá sì gbéra sókè, nígbà tí ibi bá a.
30Bẹ́ẹ̀ èmí kò sì jẹ ẹnu mi ki ó ṣẹ̀ nípa fífi ègún sí ọkàn rẹ̀.
31Bí àwọn ènìyàn inú àgọ́ mi kò bá lè wí pé, ta ni kò ì tí ì jẹ ẹran rẹ̀ ní àjẹyó?
32(Àléjò kò wọ̀ ni ìgboro rí; èmí sí ìlẹ̀kùn mi sílẹ̀ fún èrò.)
33Bí mo bá bò ẹ̀ṣẹ̀ mi mọ́lẹ̀ bí Ádámù, ni pápá, ẹ̀bi mi mọ́ ni àyà mi.
34Ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ènìyàn ni mo ha bẹ̀rù bí? Tàbí ẹ̀gan àwọn ìdílé ní ń bà mí ní ẹ̀rù? Tí mo fi p'ẹnu mọ́, tí èmí kò sì fi jáde sóde?
34
35(“Ìbá ṣepé ẹnìkán le gbọ́ ti èmí! Kíyèsí i, àmi mi, kí Olódùmárè kí ó dá mi lóhùn! Kí èmí kí ó sì rí ìwé náà tí ọ̀ta mi ti kọ!
36Nítòótọ́ èmí ìbá gbé e le èjìká mi, èmi ìbá sì dé bí adé mọ́ orí mi.
37Èmi ìbá sì sọ iye ìsísẹ̀ mi fún un, bí ọmọ aládé ni èmi ìbá súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.)
37
38“Bí ilẹ̀ mi bá sì ké rara lòdì sí mi tí a sì fi omijé kún gbogbo poro rẹ̀.
39Bí mo bá jẹ èṣo oko mi láìsánwọ́ tàbi tí mo sì mú ọkàn olúwa rẹ̀ fò lọ,
40kí ẹ̀gún òṣùṣú kí ó hù dípò àlìkámà, àti èpò búburú dípò ọkà bárlè.”