Ìwé Jóòbù 32:1-22 BYB2014 - Bible AI

1Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí dákẹ́ láti dá Jóòbù lóhùn, nítorí ó ṣe olódodo lójú ara rẹ̀.

2Nígbà náà ni inú bí Élíhù ọmọ Bárákélì ará Búsì, láti ìbátan ìdílé Rámù; ó bínú si Jóòbù nítorí ti ó dá ara rẹ̀ láre kàkà ki ó dá Ọlọ́run láre.

3Inú sì bí i sí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta, nítorí tí wọn kò rí ọ̀nà láti dá Jóòbù lóhùn bẹ́ẹ̀ ni wọ́n dá Jóòbù lẹ́bi.

4Ǹjẹ́ Élihù ti dúró tití Jóòbù fi sọ̀rọ̀ tán nitorí tí àwọn wọ̀nyí dàgbà ju òun lọ ní iye ọjọ́.

5Nígbà tí Élíhù ríi pé ìdáhùn ọ̀rọ̀ kò sí ní ẹnu àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí nígbà náà ni ó bínú.

6Élíhù, ọmọ Bárákélì, ará Búsì, dáhùn ó sì wí pé: ọmọdé ní èmi àgbà sì ní ẹ̀yin; Ǹjẹ́ nítorí náà ní mo dúró mo sì ń bẹ̀rù láti fi ìmọ̀ mi hàn yin.

7Èmi wí pé ọjọjọ́ ni ìbá sọ̀rọ̀, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ní ìbá kọ́ ni ní ọgbọ́n.

8Ṣùgbọ́n ẹ̀mi kan ní ó wà nínú ènìyàn àti ìmísí Olódùmarè ní ì sì máa fún wọn ní òye.

9Ènìyàn ńláńlá kì íṣe ọlọ́gbọ́n, Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbà ní òye ẹ̀tọ́ kò yé.

9

10“Nítorí náà ní èmí ṣe wí pé: Ẹ dẹtí sílẹ̀ sí mi; èmí pẹ̀lú yóò fi ìmọ̀ mi hàn.

11Kíyèsí i, èmí ti dúró de ọ̀rọ̀ yín; Èmi fetísí àròyé yín, nígbà tí ẹ̀yin ń wá ọ̀rọ̀ ti ẹ̀nyín yóò sọ;

12Àní mo fíyèsí yín tinútinú; sì kíyèsí i, kò sí ẹnìkan nínú yín tí ó le já Jóòbù ní irọ́, tàbí tí ó lè dá a lóhùn àríyànjiyàn rẹ̀!

13Kí ẹ̀yín kí ó má ṣe wí pé, àwa wá ọgbọ́n ní àwárí: Ọlọ́run ni ó lè bì í ṣubú, kì í ṣe ènìyàn.

14Bí òun kò ti sọ̀rọ̀ sí mi, bẹ́ẹ̀ ni èmí kì yóò fi ọ̀rọ̀ yín dá a lóhùn.

14

15“Ẹnu sì yà wọ́n, wọn kò sì dáhùn mọ́, wọ́n síwọ́ ọ̀rọ̀ ísọ́.

16Mo si reti, nítorí wọn kò sì fọhún, wọ́n dákẹ́ jẹ́ẹ́; wọn kò sì dáhùn mọ́.

17Bẹ́ẹ̀ ni èmí ò sì dáhùn nípa ti èmí, èmí pẹ̀lú yóò sì fi ìmọ̀ mi hàn.

18Nítorí pé èmí kún fún ọ̀rọ̀ sísọ, èmí ń rọ̀ mi ni inú mi.

19Kíyèsí i, ìkùn mi dàbí ọtí wáìnì, tí kò ní ojú-ìhò; ó múra tán láti bẹ́ bí ìgò-àwọ̀ tuntun.

20Èmí ó sọ, kí ara kí ó le rọ̀ mí, èmí ó sí ètè mi, èmí ó sì dáhùn.

21Lótítọ́ èmí kì yóò ṣe ojúṣàájú sí ẹnìkankan, bẹ́ẹ̀ ni èmí kì yóò sì ṣe ìpọ́nni fún ẹnìkan.

22Nítorí pé èmí kò mọ̀ ọ̀rọ̀ ìpọ́nni í sọ; ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀, Ẹlẹ́dàá mi yóò mú mi kúrò lọ́gán.

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>