1“Njẹ́ nítorí náà, Jóòbù, èmí bẹ̀ ọ, gbọ́ ọ̀rọ̀ mi kí o sì fetísí ọ̀rọ̀ mi!
2Kíyèsí i nísinsìnyí, èmí ya ẹnu mi, ahọ́n mi sì sọ̀rọ̀ ní ẹnu mi.
3Ọ̀rọ̀ mi yóò sì jási ìdúró ṣinṣin ọkàn mi, ètè mi yóò sì sọ ìmọ̀ mi jáde dájúdájú.
4Ẹ̀mí Ọlọ́run Ní ó tí dá mi, Àti ìmísí Olódùmáre ni ó ti fún mi ní ìyè.
5Bí ìwọ bá le dá mi lóhùn, tò ọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ṣẹẹsẹ níwájú mi; dìdé!
6Kíyèsí i, bí ìwọ ṣe jẹ́ ti Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni èmí náà; láti amọ̀ wá ni a sì ti dá mi pẹ̀lú
7Kíyèsí i, ẹrù ń lá mi kì yóò bà ọ; bẹ́ẹ̀ ni ọwọ́ mi kì yóò wúwo sí ọ lára.
7
8“Nítòótọ́ ìwọ sọ ní etí mi, èmí sì gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ wí pé,
9‘Èmí mọ́, laini ẹ̀ṣẹ̀ ìrékọjá; Àláìṣẹ̀ ní èmí; bẹ́ẹ̀ àìṣéédéé kò sí ní ọwọ́ mi.
10Kíyèsí i, Ọlọ́run ti rí àìṣedéédéé pẹ̀lú mi; ó kà mí sì ọ̀tá rẹ̀.
11Ó kàn ẹ̀ṣẹ̀ mi sínú àbà; o kíyèsi ipa ọ̀nà mi gbogbo.’
11
12“Kíyèsí i, nínú èyí ìwọ sìnà! Èmí o dá ọ lóhùn pé, Ọlọ́run tóbi jù ènìyàn lọ!
13Nítorí kí ni ìwọ ṣe ń báa jà, wí pé, òun kò níi sọ ọ̀rọ̀ kan nítorí iṣẹ́ rẹ̀?
14Nítorí pe Ọlọ́run sọ̀rọ̀ lẹ́ẹkan, àní lẹ́ẹkẹji, ṣùgbọn ènìyàn kò róye rẹ̀.
15Nínú àlá, ní ojúran òru, nígbà tó orun ìjìká bá kùn ènìyàn lọ, ní sísùn lórí ìbùṣùn,
16Nígbà náà ni ó lè sọ̀rọ̀ ní etí wọn, yóò sì dẹ́rùbà wọ́n pẹ̀lú ìbáwí,
17Kí ó lè fa ènìyàn sẹ́yìn kúrò nínú ètè rẹ̀; Kí ó sì pa ìgbéraga mọ́ kúrò lọ́dọ̀ ènìyàn;
18Ó sì fa ọkàn rẹ̀ pàdà kúro nínú ìsà-òkú, àti ẹ̀mí rẹ̀ láti ṣẹ̀gbé lọ́wọ́ ìdà.
19A sì nà á lórí ibùsùn ìrọra rẹ̀; Pẹ̀lúpẹ̀lú a fi ìjà egungun rẹ̀ ti ó dúró pẹ́ nà án.
20Bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀mí rẹ kọ ounjẹ, ọkàn rẹ̀ sì kọ oúnjẹ dídùn.
21Ẹran ara rẹ̀ run, títí a kò sì fi lè ríi mọ́ egungun rẹ̀ tí a kò rí sì ta jáde.
22Àní ọkàn rẹ̀ sì súnmọ́ ìsà òkú, ẹ̀mí rẹ̀ sìsúnmọ́ ọ̀dọ̀ àwọn ìranṣẹ́ ikú.
22
23“Bí oníṣẹ́ kan ba wà lọ́dọ̀ rẹ̀, ẹni tí ń ṣe alágbàwí, ọ̀kan ninú ẹgbẹ̀rún láti fi ọ̀nà pípé hàn ni,
24Nígbà náà ni ó ṣe oore ọ̀fẹ́ fún un ó sì wí pé, gbà á kúrò nínú ìlọ sínú ìsà òkú èmi ti ràá pàdà;
25Ara rẹ̀ yóò sì di ọ̀tun bí i ti ọmọ kékeré, yóò sì tún padà sí ọjọ́ ìgbà èwe rẹ̀;
26Ó gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run, òun sì se oju rere rẹ̀, o sì rí ojú rẹ̀ pẹ̀lú ayọ̀, òhun o san òdodo rẹ̀ padà fún ènìyàn
27Ó wá sọ́dọ̀ ènìyàn ó sì wí pé èmi ṣẹ̀, kò sì sí èyí tí o tọ́, mo sì ti yí èyí tí ó tọ́ po, a kò sì san ẹ̀san rẹ̀ fún mi;
28ó ti gba ọkàn mi kúrò nínú ìlọ sínú ihò, ẹ̀mí mi yóò sì rí ìmọ́lẹ̀!
28
29“Wò ó! Nǹkan wọ̀nyí ni Ọlọ́run máa ń ṣe fún ènìyàn nígbà méjì àti nígbà mẹ́ta,
30Láti mú ọkàn rẹ padà kúrò nínú isà òkú, láti fi ìmọ́lẹ̀ alààyè mọ́ sí i.
30
31“Jóòbù, kíyèsìí gidigidi kí o sì fetí sí mi; pa ẹnu rẹ mọ́, èmi ó sì máa sọ ọ́
32Bí ìwọ bá sì ní ohun íwí, dá mi lóhùn; máa sọ, nítorí pé èmi fẹ́ dá ọ láre.
33Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, gbọ́ tèmi; pa ẹnu rẹ mọ́ èmi ó sì kọ́ ọ ní ọgbọ́n.”