Ìwé Jóòbù 35:1-16 BYB2014 - Bible AI

1Elíhù sì wí pe:

2“Ìwọ rò pé èyí ha tọ́, tí ìwọ wí pé, òdodo mi ni èyí níwájú Ọlọ́run?

3Nítorí tí ìwọ wí pé èrè kí ní yóò já sí fún ọ, tàbí èrè kí ni èmi yóò fi jẹ́ ju èrè ẹ̀ṣẹ̀ mi lọ.

3

4“Èmi ó dá ọ lóhùn àti àwọn ẹgbẹ́ rẹ pẹ̀lú rẹ.

5Ṣíjú wo ọ̀run; kí o rí i, ki o sì bojúwo àwọ̀sánmọ̀ tí ó ga jù ọ lọ

6Bí ìwọ bá sẹ̀ kí ni ìwọ fi sẹ̀ sí? Tàbí bí àìṣedéédéé rẹ di púpọ̀, kí ni ìwọ fi èyí nì ṣe sí i?

7Bí ìwọ bá sì ṣe olódodo, kí ni ìwọ fí fún u, tàbí kí ni òun rí gbà láti ọwọ́ rẹ wá?

8Ìwà búburú rẹ ni fún ènìyàn bí ìwọ; òdodo rẹ sì ni fún ọmọ ènìyàn.

8

9“Nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìninilára, wọ́n mú ni kígbe; wọ́n kigbe nípa apá àwọn alágbára.

10Ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó wí pé, ‘Níbo ni Ọlọ́run Ẹlẹ́dàá mi wà tí ó sì fi orin fún mi ní òru;

11Tí òun kọ́ wa ní ẹ̀kọ́ jù àwọn ẹranko ayé lọ, tí ó sì mú wa gbọ́n ju àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run lọ?’

12Nígbà náà ni wọ́n ń ké ṣùgbọ́n Ọlọ́run kò dáhùn nítorí ìgbéraga ènìyàn búburú.

13Nítòótọ́ Ọlọ́run kì yóò gbọ́ asán; bẹ́ẹ̀ ní Olódùmarè kì yóò kà á sí.

14Bí ó tilẹ̀ ṣe pé ìwọ wí pé ìwọ kì í rí i, ọ̀rọ̀ ìdájọ́, ń bẹ níwájú rẹ, ẹni tí ìwọ sì gbọdọ̀ dúró dè.

15Ṣùgbọ́n nísinsìnyí nítorí tí ìbínú rẹ̀ kò tí ṣẹ́ ọ níṣẹ̀ẹ́, òun kò ha lè hun ímọ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà búrubú bí?

16Nítorí náà ní Jóòbù se ya ẹnu rẹ̀ lásán ó ṣọ ọ̀rọ̀ di púpọ̀ láìsí ìmọ̀.”

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>