Ìwé Jóòbù 36:1-33 BYB2014 - Bible AI

1Elíhù sì tún sọ̀rọ̀ wí pé:

2“Fún mi láyè díẹ̀ èmi ó sì fi hàn ọ́ nítorí ọ̀rọ̀ sísọ ní ó kún fún Ọlọ́run.

3Èmi ó mú ìmọ̀ mi ti ọ̀nà jínjìn wá, èmi ó sì fi òdodo fún Ẹlẹ́dàá mi.

4Rí i dájú pé ọ̀rọ̀ mi kì yóò ṣèké nítòótọ́; ẹni tí ó pé ní ìmọ̀ wà pẹ̀lú rẹ̀.

4

5“Kíyèsí i, Ọlọ́run ni alágbára, kò sì gàn ènìyàn; ó ní agbára ní ipá àti òye.

6Òun kì í dá ẹ̀mí ènìyàn búburú sí ṣùgbọ́n ó fi òtítọ́ fún àwọn tálákà.

7Òun kì ímú ojú rẹ̀ kúrò lára olódodo, ṣùgbọ́n àwọn ọba ni wọ́n wà lórí ìtẹ́; Àní ó fi ìdí wọn múlẹ̀ láéláé, a sì gbé wọn lékè.

8Bí ó bá sì dè wọ́n nínú àbà, tí a sì fi okùn ìpọ́njú dè wọ́n,

9Nígbà náà ni o ń sọ àwọn ohun tí wọn ti ṣe fún wọn, wí pé wọ́n ti ṣẹ̀ pẹ́lú ìgbéraga wọn.

10Ó sí wọn létí pẹ̀lú sí ọ̀nà ẹ̀kọ́, ó sì pàṣẹ kí wọn kí ó padà kúrò nínú àìṣedéédéé.

11Bí wọ́n bá gbàgbọ́ tí wọ́n sì sìn ín, wọn ó lo ọjọ́ wọn ní ìrọ̀ra, àti ọdún wọn nínú afẹ́.

12Ṣùgbọ́n, bí wọn kò bá gbàgbọ́, wọ́n ó ti ọwọ́ idà ṣègbé, wọ́n á sì kú láìní òye.

12

13“Ṣùgbọ́n àwọn àgàbàgebè ní àyé kó ìbínú jọ; wọn kò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ó bá dà wọ́n.

14Nígbà náà ni ọkàn wọn yóò kú ní èwe, ẹ̀mí wọn a sì wà nínú àwọn oníwà Sódómù.

15Òun gba òtòsì nínú ìpọ́njú wọn, a sì sọ̀rọ̀ sí wọn ní etí nínu ìnira wọn.

15

16“Bẹ́ẹ̀ ni pẹ̀lúpẹ̀lú ó sì dè ọ lọ láti inú ìhágágá síbi gbòòrò, sí ibi tí ó ní ààyè tí kò ní wàhálà nínú rẹ̀ ohun tí a sì gbé kalẹ̀ ní tábìlì rẹ̀ a jẹ́ kìkì ọ̀rá oúnjẹ tí ó fẹ́.

17Ṣùgbọ́n ìwọ kún fún ìdájọ́ àwọn búburú; ìdájọ́ àti òtítọ́ dì ọ́ mú.

18Nítorí ìbínú ń bẹ, ṣọ́ra kí òtítọ́ rẹ máa bàà tàn ọ́; láti jẹ́ kí títóbi èyà mú ọ sìnà.

19Ọ̀rọ̀ rẹ pọ̀ tó, tí wàhálà kì yóò fi dé bá ọ bí? Tàbi ipa agbára rẹ?

20Má ṣe ìfẹ́ òru, nígbà tí a ń ké àwọn orilẹ̀ èdè kúrò ní ipò wọn.

21Máa sọra kí ìwọ ki ó má yí ara rẹ̀ padà sí búrubú; Nítori èyí tí ìwọ rò pé ó dára jù ìpọ́njú lọ.

21

22“Kíyèsí i, Ọlọ́run á gbé-ni-ga nípa agbára rẹ̀; ta ni jẹ́ olùkọ́ni bí òun?

23Ta ni ó là ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀ sílẹ̀ fún un, tàbí ta ni ó lè wí pé ìwọ ti ń ṣe àìṣedéédéé?

24Rántí kí ìwọ kí ó gbé iṣẹ́ rẹ̀ ga, ti ènìyàn ni yín nínú orin.

25Olúkúlùkù a máa rí i; ènìyàn a máa wòó ní òkèrè,

26Kíyèsí i, Ọlọ́run tóbi, àwa kò sì mọ̀ bí ó ti ní òye tó, bẹ́ẹ̀ ni a kò lè wádìí iye ọdún rẹ̀ rí.

26

27“Nítorí pé òun ni ó fa ìkán omi ọjọ́ sílẹ̀, kí wọn kí ó kán bí òjò ní odò,

28tí àwọsánmọ̀ ń rọ̀, tí ó sì fi ń gbìn lọ́pọ̀lọpọ̀ lórí ènìyàn.

29Pẹ̀lúpẹ̀lú ẹnikẹ́ni lè imọ́ ìtànká àwọ̀sánmọ̀, tàbí ariwo àrá láti àgọ́ rẹ̀?

30Kíyèsí i, ó tan ìmọ́lẹ̀ yí ara rẹ̀ ká ó sì bo ìsàlẹ̀ òkun mọ́lẹ̀.

31Nitorí pé nípa wọn ní ń ṣe dájọ́ àwọn orílè èdè ènìyàn; ó sí ń pèsè oúnjẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.

32Ó fi ìmọ́lẹ̀ bo ọwọ́ rẹ̀ méjèèje ó sì rán sí ẹni olódì.

33Ariwo àrá rẹ̀ fi ìjì hàn ní; ọ̀wọ́ ẹran pẹ̀lú wí pé, ó súnmọ́ etílé!

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>