1“Ayà sì fò mi si èyí pẹ̀lú, ó sì kúro ní ìpò rẹ̀.
2Fetísílẹ̀! Fetísílẹ̀, kí ẹ sì gbọ́ ìró ohùn rẹ̀, àti èyí tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde wá.
3Ó ṣe ìlànà rẹ̀ ní ìsàlẹ̀ ọ̀run gbogbo, Mọ̀nàmọ́ná rẹ̀ ni ó sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ dé òpin ilẹ̀ ayé.
4Lẹ́yìn mọ̀nàmọ́ná Òun kan fọ̀ ramúramù; ó sì fi ohùn ọláńlá rẹ̀ sán àrá; òhun kì yóò sì dá àrá dúró nígbà tí ó bá ń gbọ́ ohùn rẹ̀.
5Ọlọ́run fi ohùn rẹ̀ sán àrá ní ọ̀nà ìyanu; ohùn ńláńlá ni íṣe tí àwa kò le mọ̀.
6Nítori tí ó wí fún Sínóó pé, Ìwọ rọ̀ sílẹ̀ ayé, àti pẹ̀lú fún ọwọ́ òjò, àti fún òjò ńlá agbára rẹ̀.
7Ó fi èdìdì di ọwọ́ gbogbo ènìyàn kí gbogbo wọn kí ó lè mọ iṣẹ́ rẹ̀ ó sì tún dá olúkúlùkù ẹ̀nìyàn dúró lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀
8Nígbà náà ní àwọn ẹranko wọ inú ihò lọ, wọn a sì wà ni ipò wọn.
9Láti ìhà gúsù ni ìjì àjàyíká tí jáde wá, àti òtútù láti inú afẹ́fẹ́ ti tú àwọ̀sánmọ̀ ká.
10Nípa ẹ̀mí Ọlọ́run a fí ìdí-omi fún ni, ibú-omi á sì sún kì.
11Pẹ̀lúpẹ̀lú ó fi omi púpọ̀ mú àwọ̀sánmọ̀ wúwo, a sì tú àwọ̀sánmọ̀ ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ ká ara wọn.
12Àwọn wọ̀nyí i káàriri nípà ìlànà rẹ̀, kí wọn kí ó lé ṣe ohunkohun tí ó pa láṣẹ fún wọn lórí ilẹ̀ ayé.
13Ó mú àwọ̀sánmọ̀ wá, ìbá ṣẹ fún ìkìlọ̀, tàbí omi wá sí ayé láti fi ìfẹ́ rẹ̀ hàn.
13
14“Jóòbù, dẹtí sílẹ̀ sí èyí; dúró jẹ́ẹ́ kí o sì ro iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run.
15Ìwọ mọ àkókò ìgbà tí Ọlọ́run sọ wọ́n lọ́jọ̀, tí ó sì mú ìmọ́lẹ̀ àwọ̀sánmọ̀ rẹ̀ dán?
16Ìwọ mọ ti àwọ̀sánmọ̀ í fòó lọ, iṣẹ́ ìyanu ẹni tí ó pé ní ìmọ̀?
17Aṣọ rẹ̀ ti máa gbóná, nígbà tí ó fi atẹ́gùn ìhà gúsù mú ayé dákẹ́.
18Ìwọ ha ba tẹ́ pẹpẹ ojú ọ̀run, tí ó dúró sinsin, tí ó sì dàbí dígi tí ó yọ̀ dà?
18
19“Kọ́ wa ní èyí tí a lè wí fún un; nítorí pé àwa kò le ílàdí ọ̀rọ̀ nítorí òkùnkùn wa.
20A ó ha wí fún un pé, èmi fẹ́ sọ̀rọ̀? Tàbí ẹnìkan lèwí pé, ìfẹ́ mi ni pé kí a gbémi mù?
21Ṣibẹ̀ nísinsin yìí ènìyàn kò rí oòrùn tí ń dán nínú àwọ̀sánmọ̀, ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ń kọjá, a sì fẹ́ wọn mọ́.
22Góòlù dídán ti inú ìhà àríwá jáde wá; lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni ọláńlá ẹ̀rùn ńlá.
23Nipa ti Olódùmarè àwa kò le wádìí rẹ̀; ó ré kọjá ní ipá; nínú ìdájọ́ àtí títí bi oun kì í ba ẹ̀tọ́ àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ òtítọ́ jẹ́.
24Nítorí náà ènìyàn ha máa bẹ̀rù rẹ̀; òun kì í se ojú sájú ẹnikẹ́ni tí ó gbọ́n ní ayé?”