Ìwé Jóòbù 38:1-41 BYB2014 - Bible AI

1Ígbà náà ní OLÚWA dá Jóòbù lóhùn láti inú ìjì àjàyíká wá, ó sì wí pé:

2“Ta ni èyí tí ń fi ọ̀rọ̀ àìní ìgbirò ṣu ìmọ̀ ní òkùnkùn?

3Di ẹ̀gbẹ́ ara rẹ ní àmùrè bí ọkùnrin nísinsin yìí, nítorí pé èmi yóò béèrè lọ́wọ́ rẹ kí o sì dámi lóhùn.

3

4“Níbo ni ìwọ wà nígbà ti mo fi ìpìnlẹ̀ ayé sọlẹ̀? Wí bí ìwọ bá mòye.

5Ta ni ó fi ìwọ̀ rẹ lélẹ̀, dájú bí ìwọ bá mọ̀ ọ́n? Tàbí ta ni ó ta okùn wíwọ̀n sórí rẹ?

6Lórí ibo ni a gbé kan ìpìnlẹ̀ rẹ̀ mọ́, tàbí ta ni ó fi òkúta igun rẹ̀ lélẹ̀,

7Nígbà náà àwọn ìràwọ̀ òwúrọ̀ jùmọ̀ Kọrin pọ̀, tí gbogbo àwọn áńgẹ́lì hó ìhó ayọ̀?

7

8“Tàbí ta ni ó fi ìlẹ̀kùn sé omi òkun mọ́, nígbà tí ó ya padà bí ẹni pé ó ti inú jáde wá,

9Nígbà tí mo fi àwọ sánmọ̀ ṣe aṣọ rẹ̀, tí mo sì fi òkùnkùn biribiri se ọ̀já ìgbà nú rẹ̀,

10Nígbà tí mo ṣe òpin fún-un, tí mo sì se bèbè àti ìlẹ̀kùn,

11Tí mo sì wí pé níhìn-ín ni ìwọ ó dé, kí o má sì rékọjá, níhìn-ín sì ni ìgbéraga rẹ yóò gbé dúró mọ?

11

12“Ìwọ pàṣẹ fún òwúrọ̀ láti ìgbà ọjọ́ rẹ̀ wá ìwọ sì mú ìlà oòrùn mọ ipò rẹ̀,

13Kí ó lè di òpin ilẹ̀ ayé mú, ki a lè gbọ́n àwọn ènìyàn búburú kúrò nínú rẹ̀?

14Kí ó yí padà bí amọ̀ fún èdìdì amọ̀, kí gbogbo rẹ̀ kí ó sì fi ara rẹ̀ hàn bí ẹni pé nínú aṣọ ìgúnwà.

15A sì fa ìmọ́lẹ̀ wọn sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ ènìyàn búburú, apá gíga yóò sì ṣẹ́.

15

16“Ìwọ ha wọ inú ìsun òkun lọ rí bí? Ìwọ sì rìn lórí ìsàlẹ̀ ibú ńlá?

17A ha sílẹ̀kùn ikú sílẹ̀ fún ọ rí bí, ìwọ sì rí ilẹ̀kùn òjìji òkú?

18Ìwọ mòye ibú ayé bí? Sọ bí ìwọ bá mọ gbogbo èyí.

18

19“Ọ̀nà wo ni ìmọ́lẹ̀ ń gbé? Bí ó ṣe ti òkùnkùn, níbo ni ipò rẹ̀,

20Tí ìwọ í fi mú un lọ síbi àlá rẹ̀, tí ìwọ ó sì le mọ ipa ọ̀nà lọ sínú ilé rẹ̀?

21Ìwọ mọ èyí, nitorí nígbà náà ni a bí ọ? Iye ọjọ́ rẹ sì pọ̀.

21

22“Ìwọ ha wọ inú ìṣúra ìdì Sínóò lọ rí bí, kìwọ sì rí ilé ìṣúrà òjò rí,

23Tí mo ti fi pamọ́ de ìgbà ìyọnu, dé ọjọ́ ogun àti ìjà?

24Ọ̀nà wo ǹi ó lọ sí ibi tí ìmọ́lẹ̀ fi ń ya, tí afẹ́fẹ́ ìlà oòrùn ń tàn káàkiri lórí ilẹ̀ ayé?

25Ta ni ó la ipadò fún ẹkun omi, àti ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá,

26Láti mú u rọ̀jò sórí ayé níbi tí ènìyàn kò sí, ní ihà níbi tí ènìyàn kò sí;

27Láti tẹ́ ilẹ̀ tútù, aṣálẹ̀ àti ẹgàn lọ́rùn láti mú àṣẹ̀ṣẹ̀yọ ewéko rú jáde?

28Òjò ha ní baba bí? Tàbí ta ni o bí ikùn ìṣẹ ìrì?

29Láti inú ta ni ìdì omi ti jáde wá? Ta ni ó bí ìrì dídì ọ̀run?

30Omi di lile bí òkúta, ojú ibú ńlá sì dìlù pọ̀.

30

31“Ìwọ ha le fi ọ̀já de àwọn ìràwọ̀ Píléyádè dáradára? Tàbí ìwọ le tún di Ìràwọ̀ Óríónù?

32Ìwọ le mú àwọn àmì méjìlá ìràwọ̀ Másárótì jáde wá nígbà àkókò wọn? Tàbí ìwọ le ṣe amọ̀nà Béárì pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀?

33Ǹjẹ́ ìwọ mọ ìlànà ọ̀run? Ìwọ le fi ìjọba Ọlọ́run lélẹ̀ lórí ayé?

33

34“Ìwọ le gbé ohùn rẹ sókè dé àwọ̀sánmọ̀, kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi kí ó lè bò ọ́?

35Ìwọ le rán mọ̀nàmọ́ná kí wọn kí ó le lọ, ní ọ̀nà wọn kí wọn kí ó sì wí fún wọn pé, àwa nìyí?

36Ta ni ó fi ọgbọ́n pamọ́ sí ayé tàbí tí ó fi òye sínú ọkàn?

37Ta ni ó fi ọgbọ́n ka iye àwọ̀ sánmọ̀? Ta ni ó sì mú ìgò ọ̀run dà jáde,

38Nígbà tí erupẹ̀ di líle, àti ògúlùtú dípò?

38

39“Ìwọ ha dẹ ọdẹ fún abo kìnnìún bí? Ìwọ ó sì tẹ ebi ẹgbọ̀rọ̀ kìnnìún lọ́rùn,

40Nígbà tí wọ́n bá ń mọ́lẹ̀ nínú ihò tí wọ́n sì ba ní ibùba de ohun ọdẹ?

41Ta ni ó ń pèsè ohun jíjẹ fún ìwọ, nígbà tí àwọn ọmọ rẹ ń ké pe Ọlọ́run, tí wọ́n sì máa ń fò kiri nítorí àìní ohun jíjẹ?

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>