Ìwé Jóòbù 4:1-21 BYB2014 - Bible AI

1Ígbà náà ni Élífásì, ará Témà dáhùn wí pé:

2“Bí àwa bá fi ẹnu lé e, láti bá ọ sọ̀rọ̀, ìwọ o ha banújẹ́? Ṣùgbọ́n ta ni ó lè pa ọ̀rọ̀ mọ́ ẹnu láìsọ?

3Kíyèsí i, ìwọ sá ti kọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn, ìwọ ṣá ti mú ọwọ́ aláìlera le.

4Ọ̀rọ̀ rẹ ti gbé àwọn tí ń ṣubú lọ dúró, ìwọ sì ti mú eékún àwọn tí ń wárìrì lera.

5Ṣùgbọ́n nísinsìnyí ó dé bá ọ, ó sì rẹ̀ ọ́, ó kọ lù ọ́; ara rẹ kò lélẹ̀.

6Ìbẹ̀rù Ọlọ́run rẹ kò ha jẹ́ ìgbẹ́kẹ̀lé rẹ àti ìdúró ọ̀nà rẹ kò ha sì jẹ́ ìrètí rẹ?

6

7“Èmi bẹ̀ ọ́ rántí: Ta ni ó ṣègbé rí láìṣẹ̀? Tàbí níbo ni a gbé gé olódodo kúrò rí?

8Àní bí èmi ti rí i pé, àwọn tí ń se ìtùlẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, tí wọ́n sì fún irúgbìn ìwà búburú, wọn a sì ká èso rẹ̀ náà.

9Nípa ìfẹ́ sí Ọlọ́run wọn a ṣègbé, nípa èémí ìbínú rẹ̀ wọn a parun.

10Bíbú ramúramù kìnnìún àti ohùn òǹrorò kìnníun àti eyín àwọn ẹ̀gbọ̀rọ̀ kìnnìún ní a ká.

11Ógbó kìnnìún kígbe, nítorí àìrí ohun ọdẹ, àwọn ẹ̀gbọrọ kìnnún sísanra ni a túká kiri.

11

12“Ǹjẹ́ nísinsìn yìí a fí ohun lílùmọ́ kan hàn fún mi, etí mi sì gbà díẹ̀ nínú rẹ̀.

13Ní ìrò ínú lojú ìrán òru, nígbà tí oorun èjìkà kùn ènìyàn.

14Ẹ̀rù bà mí àti ìwárìrì tí ó mú gbogbo egungun mi jí pépé.

15Nígbà náà ni iwin kan kọjá lọ ní iwájú mi, irun ara mi dìde ró ṣánṣán.

16Ó dúró jẹ́ẹ́, ṣùgbọ́n èmi kò le wo àpẹẹrẹ ìrí rẹ̀, àwòrán kan hàn níwájú mi, ìdákẹ́ rọ́rọ́ wà, mo sì gbóhùn kan wí pé:

17‘Ẹni kíkú le jẹ́ olódodo níwájú Ọlọ́run, ènìyàn kò ha le mọ̀ ju Ẹlẹ́dàá rẹ̀ bí?

18Kíyèsí i, òun kò gbẹ́kẹ̀lé àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, nínú àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ ní ó sì rí ẹ̀ṣẹ̀

19Áńbọ̀ńtórí àwọn tí ń gbé inú ilé amọ̀, ẹni tí ìbílẹ̀ wọ́n jẹ́ sí erùpẹ̀ tí yóò di rírun kòkòrò.

20A pa wọ́n run láti òwúrọ̀ di alẹ́, wọ́n gbé láé láìrí ẹni kà á sí.

21A kò ha ké okùn ìye wọ̀n kúrò bí? Wọ́n kú, àní láìlọ́gbọ́n?’

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
>