Ìwé Jóòbù 40:1-24 BYB2014 - Bible AI

1OLÚWA dá Jóòbù lóhùn sí pẹ̀lú, ó sì wi pé:

2“ẹni tí ń wá ẹ̀sùn yóò bá Olódùmarè wíjọ́ bí? Ẹni tí ń bá Ọlọ́run jiyàn jẹ́ kí ó dáhùn!”

3Nígbà náà ni Jóòbù dá OLÚWA lóhùn wá ó sì wí pé,

4“Kíyèsí i, èmi kò jámọ́ ohun kankan; ohun kí ni èmi ó dà? Èmi ó fi ọwọ́ le ẹnu mi.

5Ẹ̀ẹ̀kan ní mo sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n èmi kò rí ìdáhùn kankan; lẹ́ẹ̀kejì ni, èmi kò sì ní sọ ọ́ mọ́.”

6Nígbà náà ní OLÚWA sọ̀rọ̀ fún un láti inú ìjì àjàyíká wá, ó sì wí pé:

7“Di àmùrè gíri ní ẹgbẹ́ rẹ, èmi ó bi ọ léèrè, kí ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn.

7

8“Ìwọ ha fẹ́ mú ìdájọ́ mi di asán? Ìwọ ó sì dá mi lẹ́bi, kí ìwọ lè ṣe olódodo

9Ìwọ ni apá bí Ọlọ́run tàbí ìwọ lè fi ohùn sán àrá bí òun?

10Fi ọlá ńlá àti ọlá ìtayọ rẹ̀ ṣe ara rẹ ní ọ̀ṣọ́, tí ó sì fi ògo àti títóbi ọ̀ṣọ́ bi ara ní aṣọ.

11Mú ìrúnu ìbínú rẹ jáde; kíyèsí gbogbo ìwà ìgbéraga rẹ kí o sì rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀

12Wo gbogbo ìwà ìgbéraga, ènìyàn kí o sì rẹ ẹ sílẹ̀, kí o sì tẹ ènìyàn búburú mọ́lẹ̀ ní ipò wọn.

13Sin gbogbo wọn pa pọ̀ nínú erùpẹ̀, kí o sì di ojú ìkọ̀kọ̀ wọn ní isà òkú

14Nígbà náà ní èmi ó yàn ọ́ pé, ọwọ́ ọ̀tún ara rẹ lè gbà ọ́ là.

14

15“Ǹjẹ́ nísinsìnyí kíyèsí Béhámótì tí mo dá pẹ̀lú rẹ: òun ha máa jẹ koríko bí ọ̀dá màlúù.

16Wò o nísinsìnyí, agbára rẹ wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ, àti ipa rẹ nínú ìṣàn ìkún rẹ.

17Òun a máa jù ìru rẹ̀ bí i igi kédarì; Isan itan rẹ̀ dijọ pọ̀.

18Egungun rẹ̀ ní ògùsọ̀ idẹ; Egungun rẹ̀ dàbí ọ̀pá irin.

19Òun ni olórí nínú àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run; ṣíbẹ̀ Ẹlẹ́dàá rẹ̀ fi idà rẹ̀ lé e lọ́wọ́.

20Nítòótọ́ òkè ńláńlá ní imu ohun jíjẹ fún un wá, níbi tí gbogbo ẹranko ìgbẹ́ máa siré ní ẹ̀gbẹ́ ibẹ̀

21Ó dùbúlẹ̀ lábẹ́ igi lótósì, lábẹ́ èèsún àti ẹrẹ̀.

22Igi lótósì síji wọn bò o; igi àrọ̀rọ̀ odò yí i kákiri.

23Kíyèsí i, odò ńlá sàn jọjọ, òun kò sálọ; ó wà láìléwu bí ó bá ṣe pé odò Jọ́rdánì ti ṣàn lọ sí ẹnu rẹ̀.

24Ẹnìkan ha lè ímú u ní ojú rẹ̀, tàbí a máa fi ọ̀kọ̀ gún imú rẹ̀?

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>