Ìwé Jóòbù 41:1-34 BYB2014 - Bible AI

1“Ǹjẹ́ ìwọ lè ífi ìwọ fa Lefíátanì, ọ̀nì ńlá jáde? Tàbí ìwọ lè fi okùn so ahọ́n rẹ̀ mọ́lẹ̀?

2Ìwọ lè fi okùn bọ̀ ọ́ ní ímú, tàbí fi ìwọ̀ gun ní ẹ̀rẹ̀kẹ́?

3Òun ha jẹ́ bẹ ẹ̀bẹ̀ fún àánú lọ́dọ̀ rẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ bí òun ha bá ọ sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́?

4Òun ha bá ọ dá májẹ̀mú bí? Ìwọ ó ha máa mú ṣe ẹrú láéláé bí?

5Ìwọ hà lè ba saré bí ẹni pé ẹyẹ ni, tàbí ìwọ ó dè é fún àwọn ọmọbìnrin ìránṣẹ́ rẹ̀?

6Ẹgbẹ́ àwọn apẹja yóò ha máa tà á bí? Wọn ó ha pín láàrin àwọn oníṣòwò?

7Ìwọ ha lè fi ọ̀kọ̀-irin awọ rẹ̀, tàbí orí rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀kọ̀ ipẹja.

8Fi ọwọ́ rẹ lée lára, ìwọ ó rántí ìjà náà, ìwọ kì yóò sì ṣe bẹ̀ẹ́ mọ́.

9Kiyèsí àbá nípaṣẹ̀ rẹ ní asán; ní kìkì ìrí rẹ̀ ara kì yóò ha rọ̀ ọ́ wẹ̀sì?

10Kò sí ẹni aláyà lílé tí ó lè ru sókè; Ǹjẹ́ ta ni ó lè dúró níwájú mi.

11Ta ni ó ṣáájú ṣe fún mi, tí èmi ìbá fi san-án fún un? Ohunkóhun ti ń bẹ lábẹ́ ọ̀run gbogbo, tèmi ni.

11

12“Èmi kì yóò fi ẹ̀yà ara rẹ, tàbi ipá rẹ, tàbí ìhámọ́ra rẹ tí ó ní ẹwà pamọ́.

13Ta ni yóò lè rídìí aṣọ àpáta rẹ? Tàbí ta ni ó lè súnmọ́ ọ̀nà méjì ẹ̀yìn rẹ.?

14Ta ni ó lè sí ìlẹ̀kùn ẹnu rẹ? Àyíká ẹ̀yin rẹ ni ìbẹ̀rù ńlá.

15Ipẹ́ lílé ní ìgbéraga rẹ̀; ó pàdé pọ̀ tímọ́tímọ́ bí àmì èdìdì.

16Èkíní fi ara mọ́ èkejì tóbẹ́ẹ̀ tí afẹ́fẹ́ kò lè wọ àárin wọn.

17Èkíní fi ara mọ́ èkejì rẹ̀; wọ́n lẹ̀ wọ́n pọ̀ tí a kò lè mọ̀ wọ́n.

18Nípa sísin rẹ̀ ìmọ́lẹ̀ mọ́, ojú rẹ̀ a sì dàbí ìpénpéjú òwúrọ̀.

19Láti ẹnu rẹ ni ọ̀wọ́ iná ti jáde wá, ìpẹ́pẹ́ iná a sì ta jáde.

20Láti imu rẹ ni èéfín ti jáde wá, bí ẹni pé láti inú ìkòkò tí a fẹ́ iná ìféfé lábẹ́ rẹ̀.

21Èémi rẹ̀ tinábọ ẹ̀yin, ọ̀wọ́ iná sì ti ẹnu rẹ̀ jáde.

22Ní ọrún rẹ̀ ní agbára kù sí, àti ìbànújẹ́ àyà sì padà di ayọ̀ níwájú rẹ̀.

23Jabajaba ẹran rẹ̀ dìjọ pọ̀, wọ́n múra gírí fún ara wọn, a kò lè sí wọn nípò.

24Àyà rẹ̀ dúró gbagigbagi bí òkúta, àní ó le bi ìyá ọlọ.

25Nígbà tí ó bá gbé ara rẹ̀ sókè, àwọn alágbára bẹ̀rù; nítorí ìbẹ̀rù ńlá, wọ́n dààmú.

26Ọ̀kọ̀ tàbí idà, tàbi ọfà, ẹni tí ó sá a kò lè rán an.

27Ó ká ìrin sí bi koríko gbígbẹ àti idẹ si bi igi híhù.

28Ọfà kò lè mú un sá; òkúta kànnakánná lọ́dọ̀ rẹ̀ dàbí àkékù koríko.

29Ó ka ẹṣin sí bí àkékù idi koríko; ó rẹ́rin-ín sí mímì ọ̀kọ̀.

30Òkúta mímú ń bẹ nísàlẹ̀ abẹ́ rẹ̀, ó sì tẹ́ ohun mímú ṣónṣó sórí ẹrẹ̀.

31Ó mú ibú omi hó bí ìkòkò; ó sọ̀ agbami òkun dàbí kólòbó ìkunra.

32Ó mú ipa ọ̀nà tan lẹ́yìn rẹ̀; ènìyàn a máa ka ibú sí ewú arúgbó.

33Lórí ilẹ̀ ayé kò sí ẹni tí ó dàbí rẹ̀, tí a dá láìní ìbẹ̀rù.

34Ó bojú wo ohun gíga gbogbo, ó sì nìkan já sí ọba lórí gbogbo àwọn ọmọ ìgbéraga.”

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
v>