Ìwé Jóòbù 5:1-27 BYB2014 - Bible AI

1“Ó jẹ́ pé nísinsìn yìí bí ẹnìkan bá wà tí yóò dá wa lóhùn? Tàbí ta ni nínú àwọn ènìyàn mímọ́ tí ìwọ ó wò?

2Nítorí pé ìbínú pa aláìmòye, ìrunú a sì pa òpè ènìyàn.

3Èmi ti rí aláìmòye ti ó ta gbọ̀n-ọ́n-gbọ̀n-ọ́n lulẹ̀, ṣùgbọ́n lójú kan náà mo fi ibùjókòó rẹ̀ bú.

4Àwọn ọmọ rẹ̀ kò jìnnà sí ewu, a sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ lójú ibodè, bẹ́ẹ̀ ni kò sí aláàbò kan.

5Ìkórè oko ẹni tí àwọn tí ebi ń pa jẹ ẹran, tí wọ́n sì wọ inú ẹ̀kún lọ kó, àwọn ìgárá sì gbé ohun ìní wọn mì.

6Bí ìpọ́njú kò bá ti inú erùpẹ̀ jáde wá ni, tí ìyọnu kò ti ilẹ̀ jáde wá.

7Ṣùgbọ́n a bí ènìyàn sínú wàhálà, gẹ́gẹ́ bí ìpẹ́pẹ́ iná ti máa ń ta sókè.

7

8“Sọ́dọ̀ Ọlọ́run ní èmi lè máa ṣe àwárí, ní ọwọ́ Ọlọ́run ní èmi lè máa fi ọ̀rọ̀ mi lé.

9Ẹni tí ó ṣe ohun tí ó tóbi tí a kò lè ṣe àwárí, ohun ìyanu láìní iye.

10Tí ń rọ̀jò sí orí ilẹ̀ ayé tí ó sì ń rán omi sí ilẹ̀ẹ́lẹ̀.

11Láti gbé àwọn orilẹ̀ èdè lékè kí á lè gbé àwọn ẹni ìbànújẹ́ ga sí ibi aláìléwu.

12ⓐ Ó yí ìmọ̀ àwọn alárèékérekè po, bẹ́ẹ̀ ní ọwọ́ wọn kò lè mú ìdàwọ́lé wọn sẹ.

13Ó mú àwọn ọlọ́gbọ́n nínú arékerekè ara wọn, àti ìmọ̀ àwọn òǹrorò ní ó tari ṣubú ní ògèdèǹgbé.

14Wọ́n sáre wọ inú òkùnkùn ní ọ̀sán wọ́n sì fọwọ́ tálẹ̀ ní ọ̀sán gangan bí ẹni pé ní òru.

15Ṣùgbọ́n ó gba talákà là ní ọwọ́ idà, lọ́wọ́ ẹnu wọn àti lọ́wọ́ àwọn alágbára.

16Bẹ́ẹ̀ ni ìrètí wà fún talákà àìsòótọ́ sì pa ẹnu rẹ̀ mọ́.

16

17“Kíyèsíi, ìbùkún ni fún ẹni tí Ọlọ́run bá wí, nítorí náà, má ṣe gan ìbàwí Olódùmarè.

18Nítorí pé òun a mú ni lára kan, a sì di ìdì ìtura, ó ṣá lọ́gbẹ́, ọwọ́ rẹ̀ á sì mú jìnnà.

19Yóò gbà ọ́ nínú ìpọ́njú mẹ́fà, àní nínú méje, ibi kan kì yóò bá ọ

20Nínu ìyànu yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ ikú àti nínú ogun, yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ idà.

21A ó pa ọ́ mọ́ kúrò lọ́wọ́ iná ahọ́n bẹ́ẹ̀ ní ìwọ kì yóò bẹ̀rù ìparun tí ó bá dé.

22Ìrin ìparun àti ti ìyàn ni ìwọ yóò rìn bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì yóò bẹ̀rù ẹranko ilẹ̀ ayé.

23Nitorí pé ìwọ ó bá òkúta ìgbẹ́ múlẹ̀, àwọn ẹranko ìgbẹ́ yóò wà pẹ̀lú rẹ ní àlàáfíà.

24Ìwọ ó sì mọ̀ pé àlàáfíà ni ibùjókòó rẹ wà ìwọ yóò sì máa ṣe ìbẹ̀wò ibùjókòó rẹ, ìwọ kì yóò sìnà.

25Ìwọ ó sì mọ̀ pẹ̀lú pé irú ọmọ rẹ ó sì pọ̀ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ yóò rí bí koríko ìgbẹ́.

26Ìwọ yóò wọ iṣà òkú rẹ ní ògbólógbòó ọjọ́, bí àpò-ọkà tí ó gbó tí á sì kó ní ìgbà ìkórè rẹ̀.

26

27“Kíyèsí i, àwa ti wádìí rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ní ó rí! Gbà á gbọ́, kí o sì mọ̀ pé fún ire ara rẹ ni.”

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
>