Ìwé Jóòbù 6:1-30 BYB2014 - Bible AI

1Jóòbù sì dáhùn ó si wí pé:

2“Áà! à bá lè wọ̀n ìbìnújẹ́ mi nínú òṣùwọ̀n, kí a sì le gbé ọ̀fọ̀ mi lé orí òṣùwọ̀n ṣọ̀kan pọ̀!

3Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, ìbá wúwo jú iyánrìn òkun lọ: nítorí náà ni ọ̀rọ̀ mi ṣe ń tàsé

4Nítorí pé ọfà Olódùmárè wọ̀ mi nínú, oró èyí tí ọkàn mi mú; ìpayà-ẹ̀rù Ọlọ́run dúró tì mí.

5Ǹjẹ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́ á máa dún nígbà tí ó bá ní koríko, tàbí ọ̀dá-màlúù a máa dún sórí ìjẹ rẹ̀?

6A ha lè jẹ ohun tí kò ní adùn ní àìní iyọ̀, tàbi adùn ha wà nínú fúnfún eyin?

7Ohun ti ọ̀kan mi kọ̀ láti tọ́wò, òun ni ó dàbí oúnjẹ mi tí kò ní adùn.

7

8“Áà! èmi ìbá lè rí ìbéèrè mi gbà; àti pé, kí Ọlọ́run lè fi ohun tí èmi ṣàfẹ́rí fún mi.

9Àní Ọlọ́rin ìbá jẹ́ pa mí run, tí òun ì bá jẹ́ siwọ́ rẹ̀ kì ó sì ké mi kúrò.

10Nígbà náà ní èmi ì bá ní ìtùnú síbẹ̀, àní èmi ì bá mú ọkàn mi le nínú ìbànújẹ́ mi ti kò dá ni sí: nítorí èmi kò fi ọ̀rọ̀ ẹni mímọ́ ni sin rí.

10

11“Kí ní agbára mi tí èmi ó fi retí? Kí sì ní òpin mi tí èmi ó fi ní sùúrù?

12Agbára mi iṣe agbára òkúta bí, tàbí ẹran ara iṣe idẹ?

13Ìrànlọ́wọ́ mi kò ha wà nínú mi: ọgbọ́n ha ti sálọ kúrò lọ́dọ̀ mi bí?

13

14“Ẹni tí àyà rẹ̀ yọ́ dànù, ta ni a bá máa ṣàánú fún láti ọ̀dọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá, kí ó má ba à kọ ìbẹ̀rù Olódumáarè sílẹ̀?

15Àwọn ará mi ṣọ̀tẹ̀ bí odò sólo bí ìṣàn gúru omi odò sólo, wọ́n ṣàn kọjá lọ.

16Tí ó dúdú nítorí omi dídì, àti níbi tí odò dídì gbé lùmọ̀ sí.

17Nígbà kúgbà tí wọ́n bá gbóná wọn a sì yọ́ ṣànlọ, nígbà tí òòrùn bá mú, wọn a sì gbẹ kúrò ni ipò wọn.

18Ìyà ọ̀nà wọn a sì yípadà sí apá kan, wọ́n gòkè sí ibi asán, wọ́n sì run.

19Ẹgbẹ́ ogun Témà ń wòye àwọn ọwọ́ àrò Sébà ń dúró dè wọ́n.

20Wọ́n já lulẹ̀, nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lée; wọ́n débẹ̀, wọ́n sì dààmú.

21Ǹjẹ́ nísinsìn yìí, ẹ̀yin dàbí wọn; ẹ̀yin rí ìrẹ̀sílẹ̀ mi àyà sì fò mí.

22Èmi ó ha wí pé, ‘Ẹ mú ohun fún mi wá, tàbí pé ẹ fún mi ní ẹ̀bùn nínú ohun ìní yín?

23Tàbí, ẹgbà mí lọ́wọ́ ọ̀tá ni, tàbí, ẹrà mí padà kúrò lọ́wọ́ alágbára nì.’?

23

24“Ẹ kọ́ mi, èmi ó sì pa ẹnu mi mọ́ kí ẹ sì mú mi wòye níbi tí mo gbé ti sìnà.

25Wò ó! Bí ọ̀rọ̀ òtítọ́ ti lágbára tó ṣùgbọ́n kí ni àròyé ìbàwí yín já sí?

26Ẹ̀yin ṣè bí ẹ ó bá ọ̀rọ̀ àti ohùn ẹnu tí ó takú wí tí ó dà bí afẹ́fẹ́.

27Àní ẹ̀yin ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìní baba, ẹ̀yin sì da iye lé ọ̀rẹ́ yín.

27

28“Nítorí náà, kí èyí kí ó tó fún yín. Ẹ má wò mi! Nitorí pé ó hàn gbangba pé: Ní ojú yín ni èmi kì yóò sèké.

29Èmi ń bẹ̀ yín, ẹ padà, kí ó má sì ṣe jásí ẹ̀ṣẹ̀; àní, ẹ sì tún padà, àre mi ń bẹ nínú ọ̀rọ̀ yìí.

30Àìṣedédé ha wà ní ahọ́n mi? Ǹjẹ́ ìtọ́wò ẹnu mi kò kúkú le mọ ohun ti ó burú jù?

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
>