Ìwé Jóòbù 7:1-21 BYB2014 - Bible AI

1“Sé ìjà kò ha si fún ènìyàn lórí ilẹ̀? Ọjọ́ rẹ̀ pẹ̀lú kò ha dàbí ọjọ́ alágbàṣe?

2Bí ọmọ-ọ̀dọ̀ tí máa ń kanjú bojúwo òjíjì àti bí alágbàṣe ti í kánjú wo ọ̀nà owó iṣẹ́ rẹ̀.

3Bẹ́ẹ̀ ni a mú mi ní ìbànújẹ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù, òru ìdáni-lágara ni a sì là sílẹ̀ fún mi.

4Nígbà ti mo dùbúlẹ̀, ‘Èmi wí pé nígbà wo ni èmi ó dìde?’ Tí òru yóò sì kọjá? Ó sì tó fún mi láti yí síhìn-ín yí sọ́hùn-ún Títí yóò fi di ògúlùtu erùpẹ̀ ti a fi wọ̀ mí ní aṣọ, àwọ̀ mi bù, ó sì di sísun ni.

5Kòkòrò àti ògúlùtu erúpẹ̀ ni á fi wọ̀ mi ni aṣọ, awọ ara mi bù, o sì di sísun.

5

6“Ọjọ́ mi yára jù ọkọ̀ ìhunṣọ lọ, o sì di lílò ní àìní ìrètí.

7Áà! Ránti pé afẹ́fẹ́ ni ẹ̀mí mi; ojú mi kì yóò padà rí rere mọ́.

8Ojú ẹni tí ó rí mi, kì yóò rí mi mọ́; ojú rẹ̀ tẹ̀ mọ́ra mi, èmi kò sí mọ́.

9Bí ìkùùku tí i túká, tí í sì fò lọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń lọ sí ipò òkú tí kì yóò padà wa mọ́.

10Kì yóò padà sínú ilé rẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ ní ipò rẹ̀ kì yóò mọ̀ ọn mọ́.

10

11“Nítorí náà èmi kì yóò pa ẹnu mi mọ́, èmi yóò máa sọ nínú ìrora ọkàn mi, èmí yóò máa ṣe ìráhùn nínú kíkorò ọkàn mi.

12Èmi a máa ṣe ejò òkun tàbí erinmi, tí ìwọ fi ń yan olùṣọ́ tì mi?

13Nígbà tí mo wí pé, ibùsùn mi yóò tù mí lára, ìtẹ́ mi yóò gbé ẹrù ìráhùn mi pẹ̀lú.

14Nígbà náà ni ìwọ fi àlá da ẹ̀gbọ̀n bò mi, ìwọ sì fi ìran òru dẹ́rù bà mí.

15Bẹ́ẹ̀ ni ọkàn mí yàn láti so àti ikú ju kí ń wà láàyè ní ipò tí ara mí wà yìí lọ.

16O ṣú mi, èmi kò le wà títí: jọ̀wọ́ mi jẹ́, nítorí pé asán ni ọjọ́ mi.

16

17ⓐ “Kí ni ènìyàn tí ìwọ o máa kókìkí rẹ̀? Àti tí ìwọ ìbá fi gbé ọ̀kàn rẹ lé e?

18Àti ti ìwọ ó fi máa wá í bẹ̀ ẹ́ wò ni òròòwúrọ̀, ti ìwọ o sì máa dán anwò nígbàkúgbà!

19Yóò ti pẹ́ tó kí ìwọ kí ó tó fi mí sílẹ̀ lọ, tí ìwọ o fi jọ títí èmi o fi lè dá itọ́ mi mì.

20Èmi ti ṣẹ̀, ki ní èmi ó se sí ọ. Ìwọ Olùtọ́jú ènìyàn? Èéṣe tí ìwọ fi mí ṣe àmì ìtasi niwájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni èmi si di erù-wúwo sì ara rẹ̀

21Èéṣe tí ìwọ kò sì dárí ìrékọjá mi jìn, kí ìwọ kí ó sì mú aìṣédéédéé mi kúrò? Ǹjẹ́ nísinsìn yìí ni èmi ìbá sùn nínú erùpẹ̀, ìwọ ìbá sì wá mi kiri ní owúrọ̀, èmi kì bá tí sí.”

Copyright © 2014 by Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide
>