2“Ìwọ yóò ti máa sọ nǹkán wọ̀nyí pẹ́ tó? Tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ yóò sì máa bí ẹ̀fúùfú ńlá?
3Ọlọ́run a ha máa yí ìdájọ́ po bí, tàbí Olódùmárè a máa fi òtítọ́ sẹ̀ bí?
4Nígbà tí àwọn ọmọ rẹ̀ sẹ̀ sí i, ó sì gbá wọn kúrò nítorí àṣẹ wọn.
5Bí ìwọ bá sì képe Ọlọ́run ní ìgbà àkókò, tí ìwọ sì gbàdúrà ẹ̀bẹ̀ sí Olódùmáarè.
6Ìwọ ìbá mọ́, kí ó sì dúró sinṣsin: ǹjẹ́ nítòótọ́ nísinsìn yìí òun yóò tají fún ọ, òun a sì sọ ibùjókòó òdodo rẹ di púpọ̀.
7Ìpilẹsẹ̀ rẹ ìbá tilẹ̀ kéré si í, bẹ́ẹ̀ ìgbẹ̀yin rẹ ìbá pọ̀ sí i gidigidi.
7
8“Èmi bẹ̀ ọ́ ǹjẹ́, bèèrè lọ́wọ́ àwọn ará ìgbà nì kí o sì kíyèsí ìwádìí àwọn baba wọn.
9Nítorí pé ọmọ-àná ni àwa, a kò sì mọ nǹkan, nítorí pé òjìji ni ọjọ́ wa ni ayé.
10Àwọn kì yóò wa kọ ọ́, wọn kì yóò sì sọ fún ọ? Wọn kì yóò sì sọ̀rọ̀ láti inú òye wọn jáde wá?
11Koríko odò ha lè dàgbà láìní ẹrẹ̀ tàbí èèsú ha lè dàgbà láìlómi?
12Nígbà tí ó wà ní tútù, tí a kò kee lulẹ̀, ó rọ dànù, ewéko mìíràn gbogbo hù dípò rẹ̀
13Bẹ́ẹ̀ ni ipa ọ̀nà gbogbo àwọn tí ó gbàgbé Ọlọ́run, àbá àwọn àgàbàgebè yóò di òfo.
14Àbá ẹni tí a ó ké kúrò, àti ìgbẹ́kẹ̀lé ẹni tí ó dà bí ilé aláǹtakùn.
15Yóò fi ara ti ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró, yóò fi di ara rẹ̀ mú ṣinṣin ṣùgbọ́n kì yóò lè dúró pẹ́
16Ó tutù bí irúgbìn tí a bomirin níwájú òòrùn, ẹ̀ka rẹ̀ sì yọ jáde nínú ọgbà rẹ̀.
17Gbòǹgbò rẹ̀ ta yí ebè ká, ó sì wó ibi òkúta wọ̀n-ọn-nì.
18Bí ó bá sì pa á run kúrò ní ipò rẹ̀, nígbà náà ni ipò náà sẹ́ ẹ pé, ‘Èmi kò ri ọ rí!’
19Kíyèsí i, ayé rẹ̀ gbẹ dànù àti lati inú ilẹ̀ ní irúgbìn òmìíràn yóò hù jáde wá.
19
20“Kíyèsí i, Ọlọ́run kì yóò ta ẹni òtítọ́ nù, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò ran oníwà-búburú lọ́wọ́
21títí yóò fi fi ẹ̀rín kún ọ ní ẹnu, àti ètè rẹ pẹ̀lú ìhó ayọ̀
22ìtìjú ní a o fi bo àwọn tí ó koríra rẹ̀, àti ibùjókòó ènìyàn búburú kì yóò sí mọ́.”