1Jóòbù sì dáhùn ó sì wí pé:
2“Èmi mọ̀ pe bẹ́ẹ̀ ni ní òtítọ́! Báwo ní ènìyàn yóò ha ti ṣe jẹ́ aláre níwájú Ọlọ́run?
3Bí ó bá ṣe pé yóò bá jà, òun kì yóò lè dálóhùn kan nínú ẹgbẹ̀rùn-ún ọ̀rọ̀.
4Ọlọ́gbọ́n nínú àwọn alágbára ní ipa ní Òún; ta ni ó ṣe agídí sí i tí ó sì gbé fún rí?
5Ẹni tí ó sí òkè nídìí tí wọn kò sì mọ́: tí ó taari wọn ṣubú ní ìbínú rẹ̀
6Tí ó mi ilẹ̀ ayé tìtì kúrò ní ipò rẹ̀, ọwọ̀n rẹ̀ sì mì tìtì
7Ó pàṣẹ fún oòrùn kò sì le è ràn kí ó sì dí ìmọ́lẹ̀ ìràwọ̀ mọ́.
8Òun nìkanṣoṣo ni ó na ojú ọ̀run lọ, ti ó sì ń rìn lórí ìgbì òkun.
9Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Béárì, Óríónì àti Píléíádè àti yàrá púpọ̀ ti gúsù.
10Ẹni tí ń ṣe ohun tí ó tóbi jù àwàrí lọ, àní ohun ìyanu láìní iye.
11Kíyèsí i, ó ń kọjá lọ ní ẹ̀bá ọ̀dọ̀ mi, èmi kò sì rí i, ó sì kọjá síwáju, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò rí ojú rẹ̀.
12Kiyèsí i, ó já a gbà lọ, ta ni ó lè fà á padà? Ta ni yóò bi í pé kí ni ìwọ ń ṣe nì?
13Ọlọ́run kò ní fa ìbínú rẹ̀ sẹ́yìn, àwọn oní rànlọ́wọ́ ti Ráhábù a sì tẹriba lábẹ́ rẹ̀.
13
14“Kí ní ṣe tí èmi ò fi dá a lóhùn? Tí èmi kò fi máa fi ọ̀rọ̀ àwàwí mi ṣe àwsíyé fún-un?
15Bí ó tilẹ̀ ṣe pé mo ṣe aláìlẹ́bi, èmi kò gbọdọ̀ dá a lóhùn, ṣùgbọ́n èmi ó gbàdúrà fún àánú.
16Bí èmi bá sì ké pè é, tí Òun sì dá mi lóhùn, èmi kì yóò sì gbàgbọ́ pé, Òun ti fetí sí ohùn mi.
17Nítorí pé òun yóò lọ̀ mi lúúlúú pẹ̀lú ìjì ńlá ó sọ ọgbẹ́ mi di pupọ̀ láìnídìí.
18Òun kì yóò jẹ́ kí èmi kí ó rí ẹ̀mí mi, ṣùgbọ́n ó mú ohun kíkorò kún un fún mi.
19Bí mo bá sọ ti agbára, wò ó! Alágbára ni, tàbí ńi ti ìdájọ́, ta ni yóò dá àkókò fún mi láti rò?
20Bí mo tilẹ̀ dá ara mi láre, ẹnu ara mi óò dá mi lẹ́bi; bí mo wí pé olódodo ni èmi yóò sì fi mí hàn ní ẹni ẹ̀bi.
20
21“Olóòótọ́ ni mo ṣe, síbẹ̀ èmi kò kíyèsí ara mi, ayé mi ní èmi ìbá máa gàn.
22Ohùn kan náà ni, nítorí náà ni èmi se sọ: ‘Òun a pa ẹni òtítọ́ àti ènìyàn búburú pẹ̀lú.’
23Bí ìjàǹbá bá pani lójijì, yóò rẹ́rín-ín ìdàwọ́ aláìṣẹ̀.
24Nígbà tí a bá fi ayé lé ọwọ́ ènìyàn búburú; ó sì bo àwọn onídàájọ́ rẹ̀ lójú; bí kò bá rí bẹ́ẹ̀ ǹjẹ́ ta ni?
24
25“Ǹjẹ́ nísinsìn yìí ọjọ́ mi yára ju oníṣẹ́ lọ, wọ́n fò lọ, wọn kò rí ayọ̀.
26Wọ́n kọjá lọ bí ọkọ̀ eésú tí ń ṣúré lọ; bí idì tí ń yára si ohùn ọdẹ.
27Bí èmi bá wí pé, ‘Èmi ó gbàgbé arò ìbìnújẹ́ mi, èmi ó fi ọkàn lélẹ̀, èmi ó sì rẹ ara mi lẹ́kún.’
28Ẹ̀rù ìbànújẹ́ mi gbogbo bà mí, èmi mọ̀ pé ìwọ kì yóò mú mi bí aláìṣẹ̀.
29Bí ó bá ṣe pé ènìyàn búburú ni èmi, ǹjẹ́ kí ni èmi ń ṣe làálàá lásán sí?
30Bí mo tilẹ̀ fi ọṣẹ ojú dídì wẹ ara mi, tí mo fi omi àrò wẹ ọwọ́ mi mọ́,
31ṣíbẹ̀ ìwọ ó gbé mi wọ inú ihò ọ̀gọ̀dọ̀ aṣọ ara mi yóò sọ mi di ìríra.
31
32“Nítorí Òun kì í ṣe ènìyàn bí èmi, tí èmi ó fi dá a lóhùn tí àwa o fi pàdé ní ìdájọ́.
33Bẹ́ẹ̀ ni kò sí alátúnṣe kan ní agbede-méjì wa tí ìbá fi ọwọ́ rẹ̀ lé àwa méjèèjì lára.
34Kí ẹnìkan ṣá à mú ọ̀pá Ọlọ́run kúrò lára mi, kí ìbẹ̀rù rẹ̀ kí ó má sì se dáyà fò mí
35Nígbà náà ni èmi ìbá sọ̀rọ̀, èmi kì bá sì bẹ̀rù rẹ̀; ṣùgbọ́n bí ó tí dáré-ti mi, kò ri bẹ́ẹ̀ fún mi.