1Èyí ni ìran àwọn ọmọ Nóà: Ṣémù, Ámù àti Jáfétì, tí àwọn náà sì bí ọmọ lẹ́yìn ìkún omi.
2Àwọn ọmọ Jáfétì ni: Gómérì, Mágógì, Mádáì, Jáfánì, Túbálì, Méṣékì àti Tírásì.
3Àwọn ọmọ Gómérì ni:
3Áṣíkénásì, Rífátì àti Tógárímà.
4Àwọn ọmọ Jáfánì ni:
4Élíṣà, Tásísì, Kítímù, àti Ródánímù.
5(Láti ọ̀dọ̀ àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí ń gbé agbégbé tí omi wà ti tàn ká agbégbé wọn, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, ìdílé wọn ní orílẹ̀ èdè wọn, olúkúlùkù pẹ̀lú èdè tirẹ̀).
5
6Àwọn ọmọ Ámù ni:
6Kúsì, Mísíráímù, Fútì àti Kénánì.
7Àwọn ọmọ Kúsì ni: Àwọn ọmọ Rámà ni: Ṣébà àti Dédánì.
7Ṣébà, Háfílà, Ṣábátà, Rámà, àti Ṣábítékà.
8Kúsì sì bí Nímúrọ́dù, èyí tí ó di alágbára àti jagunjagun ní ayé.
9Ó sì jẹ́ ògbójú ọdẹ níwájú OLÚWA; nítorí náà ni a ṣe ń wí pé, “Bí Nímúrọ́dù-ògbójú ọdẹ níwájú OLÚWA.”
10Ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni Bábílónì, Érékì, Ákádì, Kálínéhì, gbogbo wọn wà ní ilẹ̀ Ṣínárì.
11Láti ilẹ̀ náà ni ó ti lọ sí dé Áṣíríà, níbi tí ó ti tẹ ìlú Nínéfè, Réhóbótì àti Kálà,
12àti Résínì, tí ó wà ní àárin Nínéfè àti Kálà, tí ó jẹ́ ìlú olókìkí.
13Mísíráímù ni baba ńlá àwọn ará Lúdì, Ánámì, Léhábì, Náfítúhímù.
14Pátírúsímù, Kásílúhímù (èyí tí í ṣe baba ńlá àwọn Fílístínì) àti Káfítórímù.
14
15Kénánì ni baba àwọn ará
15Sídónì (èyi ni àkọ́bí rẹ̀), àti àwọn ara Hítì.
16Àwọn ará Jébúsì, Ámórì, Gágásì.
17Hífì, Áríkì, Sínì,
18Áfádì, Ṣémárì àti Hámátì.
18Nígbà tí ó ṣe, àwọn ẹ̀yà Kénánì tàn kálẹ̀.
19Ààlà ilẹ̀ àwọn ará Kénánì sì dé Ṣídónì, lọ sí Gérárì títí dé Gásà, lọ sí Sódómù, Gòmórà, Ádímà àti Ṣébóìmù, títí dé Láṣà.
20Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Ámù, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, àti èdè wọn, ní ìpínlẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀-èdè wọn.
21A bí àwọn ọmọ fún Ṣémù tí Jáfétì jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin: Ṣémù sì ni baba gbogbo àwọn ọmọ Ébérì.
22Àwọn ọmọ Ṣémù ni: Élámù, Ásọ̀, Áfákísádì, Lúdì àti Árámù.
23Àwọn ọmọ Árámù ni:
23Úsì, Úlì, Gétérì àti Méṣékì.
24Áfákísádì ni baba Ṣélà,
24Ṣélà yìí sì ni ó bí Ébérì.
25Ébérì sì bí ọmọ méjì:
25ọ̀kan sì ń jẹ́ Pélégì, nítorí ní ìgbà ayé rẹ̀ ni ilẹ̀ ayé pín sí oríṣìíríṣìí ẹ̀yà àti èdè. Orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Jókítanì.
26Jókítanì sì bí
26Álímádádì, Ṣéléfì, Hásámáfétì àti Jérà.
27Hádórámù, Húsálì, Díbílà.
28Óbálì, Ábímáélì, Ṣébà.
29Ófírì, Áfílà àti Jóbábù. Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ọmọ Jókítanì.
30Agbègbè ibi tí wọn ń gbé bẹ̀rẹ̀ láti Méṣà títí dé Ṣéfárì, ní àwọn ilẹ̀ tó kún fún òkè ní ìlà oòrùn.
31Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ọmọ Ṣémù gẹ́gẹ́ bí ìdílé wọn, ní èdè wọn, ní ilẹ̀ wọn àti ní orílẹ̀ èdè wọn.
32Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà ọmọ Nóà gẹ́gẹ́ bí ìran wọn, ní orílẹ̀ èdè wọn. Ní ipaṣẹ̀ wọn ni àwọn ènìyàn ti tàn ká ilẹ̀ ayé lẹ́yìn ìkún omi.