1Lẹ́yìn náà, gbogbo àgbáyé sì ń sọ èdè kan ṣoṣo.
2Bí àwọn ènìyàn ṣe ń tẹ̀ṣíwájú lọ sí ìhà ìlà oòrùn, wọ́n rí pẹ̀tẹ́lẹ̀ kan ní ilẹ̀ Sínárì (Bábílónì), wọ́n sì tẹ̀dó ṣíbẹ̀.
3Wọ́n sì wí fún ara wọn pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a mọ bíríkì kí a sì sun wọ́n jiná.” Bíríkì ni wọn ń lò ní ipò òkúta, àti ọ̀dà ilẹ̀ tí wọn ń lò láti mú wọn papọ̀ dípò ẹfun (òkúta láìmù tí wọn fi ń ṣe símẹ́ńtì àti omi).
4Nígbà náà ni wọ́n wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tẹ ìlú kan fún ara wa, kí a sì kọ́ ilé-ìṣọ́ kan tí yóò kan ọ̀run, kí á baà lè ní orúkọ (òkìkí) kí a má sì tú káàkiri sórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”
5Ṣùgbọ́n, OLÚWA sọ̀kalẹ̀ láti wo ìlú àti ilé-ìṣọ́ tí àwọn ènìyàn náà ń kọ́.
6OLÚWA wí pé, “Bí àwọn ènìyàn bá ń jẹ́ ọ̀kan àti èdè kan tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iṣẹ́ yìí, kò sí ohun tí wọ́n gbérò tí wọn kò ní le ṣeyọrí.
7Ẹ̀ wá, ẹ jẹ́ kí a sọ̀kalẹ̀ lọ, kí a da èdè wọn rú kí èdè wọn má baà yé ara wọn mọ́.”
8Ọlọ́run sì tú wọn ká sórí ilẹ̀ gbogbo, wọ́n sì ṣíwọ́ ìlú náà tí wọn ń tẹ̀dó.
9Ìdí èyí ni a fi pè é ní Bábílónì nítorí ní ibẹ̀ ni Ọlọ́run ti da èdè gbogbo ayé rú, tí ó sì tú àwọn ènìyàn ká sí gbogbo orí ilẹ̀ ayé.
10Wọ̀nyí ni ìran Ṣémù
11Lẹ́yìn tí ó bí Áfákísádì, ó tún wà láàyè fún ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún (500), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
12Nígbà tí Áfákísádì pé ọdún marùndínlógójì (35) ni ó bí Ṣélà.
13Ó sì wà láàyè fún ọdún mẹ́talénírínwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Ṣélà, ó sì bí àwọn ọmọbìnrin àti àwọn ọmọkùnrin mìíràn.
14Nígbà tí Ṣélà pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni ó bí Ébérì.
15Ó sì wà láàyè fún ọdún mẹ́talénírinwó (403) lẹ́yìn tí ó bí Ébérì, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
16Ébérì sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n (34), ó sì bí Pélégì.
17Ébérì sì wà láàyè fún irínwó-ó-lé-ọgbọ̀n ọdún (430) lẹ́yìn tí ó bí Pélégì, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
18Nígbà tí Pélégì pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni ó bí Réù.
19Ó sì tún wà láàyè fún igba-ó-lé-mẹ́sàn án ọdún (209) lẹ́yìn tí ó bí Réù, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
20Nígbà tí Réù pé ọdún méjìlélọ́gbọ̀n (32) ni ó bí Ṣérúgì.
21Ó tún wà láàyè lẹ́yìn tí ó bí Ṣérúgì fún igba-ó-lé-méje ọdún (207), ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin mìíràn.
22Nígbà tí Ṣérúgì pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni ó bí Náhórì.
23Ó sì wà láàyè fún igba ọdún (200) lẹ́yìn tí ó bí Náhórì, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
24Nígbà tí Náhórì pé ọmọ ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29), ó bí Tẹ́rà.
25Ó sì wà láàyè fún ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́fà (119) lẹ́yìn ìbí Tẹ́rà, ó sì bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin mìíràn.
26Lẹ́yìn tí Tẹ́rà pé ọmọ àádọ́rin ọdún (70) ó bí Ábúrámù, Náhórì àti Háránì.
27Wọ̀nyí ni ìran Tẹ́rà: Tẹ́rà ni baba Ábúrámù, Náhórì àti Áránì, Áránì sì bí Lọ́tì.
28Áránì sì kú ṣáájú Tẹ́rà baba rẹ̀ ní ilẹ̀ ìbí rẹ̀ ní Úrì ti ilẹ̀ Kálídéà.
29Ábúrámù àti Náhórì sì gbéyàwó. Orúkọ aya Ábúrámù ni Sáráì, nígbà tí aya Náhórì ń jẹ́ Mílíkà, tí ṣe ọmọ Áránì. Áránì ni ó bí Mílíkà àti Ísíkà.
30Sáráì sì yàgàn, kò sì bímọ.
31Tẹ́rà sì mú ọmọ rẹ̀ Ábúrámù àti Lọ́tì ọmọ Áránì, ọmọ-ọmọ rẹ̀, ó sì mú Sáráì tí i ṣe aya ọmọ rẹ̀. Ábúrámù pẹ̀lú, gbogbo wọn sì jáde kúrò ní Úrì ti Kálídéà láti lọ sí ilẹ̀ Kénánì. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọn dé Áránì wọ́n tẹ̀dó síbẹ̀.
32Nígbà tí Tẹ́rà pé ọmọ igba ó lé márùn-ún ọdún (205) ni ó kú nì Áránì