Ìwé Jẹ́nẹ́sísì 12:1-20 BYB2014 - Bible AI

1ⓐ  OLÚWA sì wí fún Ábúrámù, “Jáde kúrò ní ile rẹ àti lọ́dọ̀ àwọn ènìyàn rẹ àti kúrò ní ìdílé baba rẹ, lọ sí ilẹ̀ kan tí èmi ó fi hàn ọ́.

2ⓑ “Èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá Èmi yóò sì bùkún fún ọ. Èmi yóò sọ orúkọ rẹ di ńlá, ìbùkún ni ìwọ yóò sì jásí.

3ⓒ Àwọn tí ó súre fún ọ ni Èmi yóò súre fún, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi ọ́ ré ni Èmi yóò fi ré; Nípaṣẹ̀ rẹ ni a ó sì bùkún gbogbo ènìyàn ayé”

4Bẹ́ẹ̀ ni Ábúrámù lọ bí OLÚWA ti sọ fún un. Lọ́tì náà sì bá a lọ. Ábúrámù jẹ́ ẹni àrùndínlọ́gọ́rin (75) ọdún nígbà tí ó jáde kúrò ní Háránì.

5Ábúrámù sì mú Ṣáráì aya rẹ̀, àti Lọ́tì ọmọ arákùnrin rẹ̀: gbogbo ohun ìní tí wọ́n ti kó jọ àti àwọn ènìyàn tí wọ́n ní ní Háránì. Wọ́n sì jáde lọ sí ilẹ̀ Kénánì. Wọ́n sì gúnlẹ̀ ṣíbẹ̀.

6Ábúrámù sì rìn la ilẹ̀ náà já títí dé ibi igi ńlá kan tí à ń pè ni Móórè ní Ṣékémù. Àwọn ará Kénánì sì wà ní ilẹ̀ náà.

7ⓓ OLÚWA sì farahan Ábúrámù, ó sì wí fún un pé, “Ìran rẹ ni Èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún.” Ábúrámù tẹ́ pẹpẹ kan ṣíbẹ̀ fún OLÚWA tí ó fara hàn-án.

8Ó sì kúrò níbẹ̀ lọ sí agbègbè àwọn òkè kan ní ìhà ìlà oòrùn Bẹ́tẹ́lì, ó sì pàgọ́ rẹ̀ ṣíbẹ̀. Bẹ́tẹ́lì wà ní ìwọ̀ oòrùn, Háì wà ní ìlà oòrùn. Ó tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún OLÚWA, ó sì ké pe orúkọ OLÚWA.

9Nígbà náà ni Ábúrámù tẹ̀ṣíwájú sí ìhà gúsù ni Gúúsù.

10ⓔ Ìyàn kan sì mú ní ilẹ̀ náà, Ábúrámù sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Éjíbítì láti ṣe àtìpó níbẹ̀ fún ìgbà díẹ̀, nítorí ìyàn náà mú gidigidi.

11Bí ó ti ku díẹ̀ kí ó wọ Éjíbítì, ó wí fún Ṣáráì, aya rẹ̀ pé, “Mo mọ̀ pé arẹwà obìnrin ni ìwọ,

12nígbà tí àwọn ara Éjíbítì bá rí ọ, wọn yóò wí pé, ‘Aya rẹ̀ nìyí.’ Wọn yóò si pa mí, ṣùgbọ́n wọn yóò dá ọ sí.

13Nítorí náà, sọ pé, arábìnrin mi ni ìwọ, wọn yóò sì ṣe mí dáradára, a ó sì dá ẹ̀mí mi sí nítorí tìrẹ.”

14Nígbà tí Ábúrámù dé Éjíbítì, àwọn ará Éjíbítì ri i pé aya rẹ̀ rẹwà gidigidi.

15Nígbà tí àwọn ìjòyè Fáráò sì rí i, wọ́n ròyìn rẹ̀ níwájú u Fáráò, Wọ́n sì mú un lọ sí ààfin,

16Ó sì kẹ́ Ábúrámù dáradára nítorí Ṣáráì, Ábúrámù sì ní àgùntàn àti màlúù, akọ àti abo, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin, pẹ̀lú u ràkunmí.

17OLÚWA sì rán àjàkálẹ̀-àrùn búburú sí Fáráò àti ilé rẹ̀, nítorí Sáráì aya Ábúrámù.

18Nítorí náà Fáráò ránṣẹ́ pe Ábúrámù, ó sì wí fun pé, “Èwo ni ìwọ ṣe sí mi yìí? Kí n ló dé tí ìwọ kò sọ fún mi pé aya rẹ ní í ṣe?

19Èéṣe tí o fi wí pé, ‘Arábìnrin mi ni,’ tí èmi sì fi fẹ́ ẹ gẹ́gẹ́ bí aya? Nítorí náà nísinsin yìí, aya rẹ náà nìyí, mú un kí sì o máa lọ.”

20Nígbà náà ni Fáráò pàṣẹ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nípa Ábúrámù, wọ́n sì lé e jáde ti òun ti aya rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní.

>