1Ní àsìkò yìí ni Ámúráfélì ọba Ṣínárì, Áríókù ọba Élásárì, Kédóláómérì ọba Élámù àti Tídálì ọba Góímù
2jáde lọ láti bá Bérà ọba Ṣódómù, Bírísà ọba Gòmórà, Ṣínábù ọba Ádímà, Ṣémébérì ọba Ṣébóímù àti ọba Bélà (èyí-ni nì Ṣóárì) jagun.
3Gbogbo àwọn ọba wọ̀nyí ni ó kó ogun wọn jọ pọ̀ sí àfonífojì Ṣídímù (òkun iyọ̀).
4Fún ọdún méjìlá gbáko ni wọ́n ti ń sin Kédóláómérì bí ẹrú. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di ọdún kẹtàlá wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí i.
5Ní ọdún kẹrìnlá, ni Kédóláómérì àti àwọn ọba tí wọ́n ti jọ ni májẹ̀mú àṣepọ̀ wá, wọ́n sígun, wọ́n sì ṣẹ́gun ara Ráfáímù ní Aṣilerótì-Kánáímù, àwọn ará Ṣúsítù ni Ámù, àwọn ará Émímù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Kiriátaímù,
6àti àwọn ará Hórì ní orí-òkè wọ̀nnì Ṣéírì, títí ó fi dé Eli-Páránì ní etí ijù.
7Wọ́n sì tún yípadà lọ sí Ẹn-Mísífátì (èyí yìí ni Kádésì), wọ́n sì ṣẹ́gun gbogbo ilẹ̀ àwọn Ámálékì, àti àwọn ará Ámórì tí ó tẹ̀dó sí Haṣaṣoní Támárì pẹ̀lú.
8Nígbà náà ni ọba Ṣódómù, ọba Gòmórà, ọba Ádímà, ọba Ṣébóímù àti ọba Bélà (èyí ni Ṣóárì), kó àwọn ọmọ ogun wọn, wọ́n sì pa ibùdó-ogun wọn sí àfonífojì Ṣídímù,
9láti kojú ìjà sí Kedolaómérì ọba Élámù, Tídà ọba Góímù, Ámúráfélì ọba Ṣínárì àti Áríókì ọba Élásà (ọba mẹ́rin kọjú ìjà sí ọba márùn-ún).
10Àfonífojì Ṣídímù sì kún fún kòtò ọ̀dà-ilẹ̀, nígbà tí ọba Ṣódómù àti ọba Gòmórà sì ṣá, díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin ogun náà subú sínú àwọn kòtò náà, àwọn tókù sì sálọ sì orí òkè.
11Àwọn ọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà sì kó gbogbo ẹrù Ṣódómù àti Gòmórà àti oúnjẹ wọn; wọ́n sì lọ.
12Wọ́n sì mú Lọ́tì ọmọ arákùnrin Ábúrámù tí ń gbé ní Ṣódómù àti gbogbo ohun-ìní rẹ̀.
13Ẹnìkan tí ó sá àsálà sì wá ròyìn fún Ábúrámù, ará Ébérù. Ábúrámù sá ti tẹ̀dó sí igbó igi Óákù tí ó jẹ́ ti Mámúrè ará Ámórì, arákùnrin Ésíkólì àti Ánérì: àwọn ẹni tí ó ń bá Ábúrámù ní àṣepọ̀.
14Nígbà tí Ábúrámù gbọ́ wí pé, a di Lọ́tì ní ìgbékùn, o kó àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ tí a bí sí ilẹ́ rẹ̀ tí ó sì ti kọ́ ni ogun jíjà jáde, wọ́n jẹ́ okòó-lé-lọ́ọ̀dúnrún ó dín méjì ènìyàn (318), ó sì lépa wọn títí dé Dánì.
15Ní ọ̀gànjọ́ òru, Ábúrámù pín àwọn ọmọ ogun rẹ̀ sí méjì, ó sì kọlù wọ́n, ó sì ṣẹ́gun wọn, ó sì lé wọn títí dé Oba, ní àríwá Dámásíkù.
16Gbogbo ìkógun ni ó rí gbà padà àti ọmọ arákùnrin rẹ̀, Lọ́tì pẹ̀lú ohun-ìní rẹ̀, àti àwọn obìnrin pẹ̀lú àwọn ènìyàn tó kù.
17
18Mélíkísédékì ọba Ṣálẹ́mù (Jérúsálẹ́mù) sì mú oúnjẹ àti ọtí wáìnì jáde wá. Òun ni àlùfáà Ọlọ́run, ọ̀gá ògo.
19Ó sì súre fún Ábúrámù wí pé,
20
21Ọba Ṣódómù sì wí fún Ábúrámù pé, “Kó àwọn ènìyàn mi fún mi, ṣùgbọ́n mú àwọn ẹrù fún ara rẹ.”
22Ṣùgbọ́n Ábúrámù dá ọba Ṣódómù lóhùn pé, “Mo ti búra fún OLÚWA, Ọlọ́run ọ̀gá ògo, tí ó dá ọ̀run àti ayé, mo sì ti gbọ́wọ́ sókè,
23pé, èmi kì yóò mú ohunkóhun tí í ṣe tìrẹ se tèmi, ìbáà kéré bí orí abẹ́rẹ́, kí ìwọ kí ó má ba à wí pé, ‘Mo sọ Ábúrámù di ọlọ́rọ̀.’
24Èmi kì yóò gba ohunkóhun yàtọ̀ sí ohun tí àwọn ọkùnrin mi ti jẹ́, ṣùgbọ́n fi ìpín fún àwọn ọkùnrin tí ó bá mi lọ, Ánérì, Ésíkólì àti Mámúrè. Jẹ́ kí wọn kí ó gba ìpín wọn.”