1Lẹ́yìn èyí, ọ̀rọ̀ OLÚWA tọ Ábúrámù wá lójú ìran pé:
2Ṣùgbọ́n Ábúrámù wí pé, “OLÚWA, alágbára, kí ni ìwọ yóò fi fún mi níwọ̀n ìgbà tí èmi kò bímọ, Élíásérì ará Dámásíkù ni yóò sì jogún mi,”
3Ábúrámù sì tún tẹ̀ṣíwájú pé, “Ìwọ kò fún mi ní ọmọ, nítorí náà ẹrú nínú ilé è mi sì ni yóò jẹ́ àrólé mi.”
4
5
6
7Ó sì tún wí fún un pé, “Èmi ni OLÚWA tí ó mú ọ jáde láti Úrì ti Kálídéà láti fún ọ ní ilẹ̀ yìí láti jogún.”
8Ṣùgbọ́n Ábúrámù wí pé, “OLÚWA Ọlọ́run, báwo ni mo ṣe lè mọ̀ pé ilẹ̀ náà yóò jẹ́ ohun ìní mi?”
9Nítorí náà, OLÚWA wí fún-un pé, “Mú abo màlúù, ewúrẹ́ àti àgbò ọlọ́dún mẹ́tamẹ́ta wá, àti àdàbà kan àti ọmọ ẹyẹlé kan.”
10Ábúrámù sì mú gbogbo nǹkan wọ̀nyí wá, ó sì là wọ́n sí méjìméjì, ó sì fi ẹ̀là èkínní kọjú sí èkejì, ṣugbọ́n kò la àwọn ẹyẹ ní tiwọn.
11Àwọn ẹyẹ igún sì ń wá sórí òkú ẹran náà, Ábúrámù sì ń lé wọn.
12
13
14
15Ṣùgbọ́n ìwọ yóò tọ àwọn baba rẹ lọ ni àlàáfíà, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ yóò sì di arúgbó kí a tó gbé ọ sin.
16Ní ìran kẹ́rin àwọn ìran rẹ yóò padà wá sí ibi. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ará Ámórì kò ì tí ì kún òṣùwọ̀n.”
17Nígbà tí oòrùn wọ̀ tí ilẹ̀ sì sú, ìkòkò iná tí ń sèéfín àti ọwọ́ iná sì ń kọjá láàrin ẹ̀là a ẹran náà.
18
19ilẹ̀ àwọn ará Kénì, Kádímónì,
20Ítì, Pérísísì, Réfáímù.
21Ámórì, Kénánì, Gírígásì àti Jébúsì.”