1Ṣáráì, aya Ábúrámù kò bímọ fún un, ṣùgbọ́n ó ní ọmọ ọ̀dọ̀ obìnrini ará Éjíbítì kan tí ń jẹ́ Ágárì.
2Nítorí náà, Ṣáráì wí fún Ábúrámù pé, “Kíyèsí i OLÚWA ti sé mi ní inú, èmi kò sì bímọ, wọlé tọ ọmọ ọ̀dọ̀ mi lọ, bóyá èmi yóò le ti ipaṣẹ̀ rẹ̀ ní ọmọ.”
3Lẹ́yín ọdún mẹ́wàá tí Ábúrámù ti ń gbé ni Kénánì ni Ṣáráì mú ọmọbìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Hágárì, tí í ṣe ará Éjíbítì fún Ábúrámù ọkọ rẹ̀ láti fi ṣe aya.
4Ábúrámù sì bá Ágárì lòpọ̀, ó sì lóyún.
5Nígbà náà ni Ṣáráì wí fún Ábúrámù pé, “Ìwọ ni ó jẹ́ kí ẹ̀gbin yìí máa jẹmí, mo fa ọmọ ọ̀dọ̀ mi lé ọ lọ́wọ́, nígbà tí ó sì rí i pé òun lóyún, mo di ẹni ẹ̀gàn ní ojú rẹ̀. Kí OLÚWA kí ó ṣe ìdájọ́ láàrin èmi àti ìwọ.”
6Ábúrámù dáhùn pé, “Ìwọ ló ni ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ, ṣe ohunkóhun tí ó bá tọ́ ní ojú rẹ sí i.” Nígbà náà ni Ṣáráì fi ìyà jẹ ẹ́, ó sì sá lọ.
7Ańgẹ́lì OLÚWA sì rí Ágáì ní ẹ̀gbẹ́ ìsun omi ní ijù, ìsun omi tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀na tí ó lọ sí Ṣúrì.
8Ó sì wí pé, “Hágárì, ìránṣẹ́ Ṣáráì, níbo ni o ti ń bọ̀, níbo sì ni ìwọ ń lọ?”
9Ańgẹ́lì OLÚWA sì wí fún un pé, “Padà lọ sí ọ̀dọ̀ ọ̀gá rẹ kí o sì tẹríba fún un.”
10Ańgẹ́lì náà sì fi kún fún un pé, “Èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀ èdè ńlá, ìran rẹ kì yóò sì lóǹkà.”
11Ańgẹ́lì náà sì wí fún un pé,
12
13Ó sì fi pe OLÚWA tí o bá sọ̀rọ̀ ní, “Ìwọ ni Ọlọ́run tí ó rí mi,” nítorí tí ó wí pé, “Mo ti ri ẹni tí ó rí mi báyìí.”
14Nítorí náà ni a ṣe ń pe kànga náà ní Beeri-Lahai-Róì: kànga ẹni alààyè tí ó rí mi. Ó wà lágbedeméjì Kédásì àti Bérédì.
15
16Ábúrámù jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìndín-láàádọ́rùn-ún (86) nígbà tí Hágárì bí Ísímáélì fún-un.