1OLÚWA sì farahan Ábúráhámù ní tòsí àwọn igi ńlá Mámúrè, bí ó ti jókòó ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀, nígbà tí ọjọ́ kanrí tí oòrùn sì mú.
2
3Ó wí pé, “Bí mo bá rí ojú rere yín OLÚWA mi, ẹ má ṣe lọ láì yà sọ́dọ̀ ìránṣẹ́ yín.
4Ẹ jẹ́ kí a bu omi díẹ̀ wá kí ẹ̀yin kí ó wẹ ẹṣẹ̀ yín, kí ẹ sì sinmi lábẹ́ igi níhìn-ín.
5Ẹ jẹ́ kí n wá oúnjẹ wá fún-un yín kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ, kí ara sì tù yín, kí ẹ si tẹ̀ṣíwájú ní ọ̀nà yín, nígbà tí ẹ ti yà ní ọ̀dọ̀ ìránṣẹ́ yín.”
6Ábúráhámù sì yára tọ Ṣárà aya rẹ̀ lọ nínú àgọ́, ó wí pé, “Tètè mú òṣùwọn ìyẹ̀fun dáradára mẹ́ta kí o sì pò ó pọ̀, kí o sì ṣe oúnjẹ.”
7Ó sì tún sáré lọ sí ibi agbo ẹran, ó sì mú ọmọ màlúù kan fún ìránṣẹ́ rẹ̀, ìránṣẹ́ náà sì tètè ṣè é.
8Ó sì mú wàrà àti mílíìkì àti màlúù tí ó ti pèsè, ó sì gbé e ṣíwájú wọn. Ó sì dúró nítòòsí wọn lábẹ́ igi bí wọn ti ń jẹ ẹ́.
9Wọn bèèrè pé, “Ṣárà aya rẹ ńkọ́?”
10
11Ábúráhámù àti Ṣárà sì ti di arúgbó: Ṣárà sì ti kọjá àsìkò ìbímọ.
12
13Nígbà náà ni OLÚWA wí fún Ábúráhámù pé, “Kín ló dé tí Ṣárà fi rẹ́rìn-ín tí ó sì wí pé, ‘Èmi yóò ha bímọ nítòótọ́, nígbà tí mo di ẹni ogbó tan?’
14
15Ẹ̀rù sì ba Ṣárà, ó sì sẹ́ pé òun kò rẹ́rìn-ín.
16Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà dìde láti máa lọ, wọn kọjú sí ọ̀nà Ṣódómù, Ábúráhámù sì sìn wọ́n dé ọ̀nà.
17Nígbà náà ni OLÚWA wí pé, “Ǹjẹ́ èmi yóò ha pa ohun tí mo fẹ́ ṣe mọ́ fún Ábúráhámù bí?
18
19Nítorí tí èmi ti yàn án láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ará ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, láti máa pa ọ̀nà OLÚWA mọ nípa ṣíṣe olóòtọ́ àti olódodo: kí OLÚWA le è mú ìlérí rẹ̀ fún Ábúráhámù ṣẹ.”
20OLÚWA sì wí pé, igbe Ṣódómù àti Gòmórà pọ̀ púpọ̀ àti pé ẹ̀ṣẹ̀ wọn burú jọjọ.
21“Èmi yóò sọ̀kalẹ̀ síbẹ̀ láti ṣe ìwádìí igbe tí ó dé sí etí ìgbọ́ mi nípa wọn, kí èmi sì mọ òtítọ́ tí ó wà níbẹ̀.”
22Àwọn ọkùnrin náà yí padà, wọ́n sì ń lọ sí ìhà Ṣódómù. Ṣùgbọ́n Ábúráhámù dúró níbẹ̀ níwájú OLÚWA.
23Nígbà náà ni Ábúráhámù súnmọ́ ọ̀dọ̀ OLÚWA, ó sì wí pé, “Ìwọ yóò ha pa ènìyàn rere àti ènìyàn búrurú run papọ̀ bí?”
24“Bí ó bá ṣe pé Ìwọ rí àádọ́ta olódodo nínú ìlú náà, Ìwọ yóò ha run-ún, Ìwọ kì yóò ha dá ìlú náà sí nítorí àwọn àádọ́ta olódodo tí ó wà nínú rẹ̀ náà?
25Kò jẹ́ rí bẹ́ẹ̀! Dájúdájú Ìwọ kì yóò ṣe ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀, láti pa olódodo pẹ̀lú àwọn ènìyàn rere àti àwọn ènìyàn búburú. Dájúdájú Ìwọ kì yóò ṣe èyí tí ó tó bi?”
26OLÚWA wí pé, “Bí mo bá rí àádọ́ta (150) olódodo ní ìlú Ṣódómù, èmi yóò dá ìlú náà sí nítorí tí wọn.”
27Ábúráhámù sì tún tẹ̀ṣíwájú pé, “Wò ó nísinsin yìí, níwọ̀n bí èmi ti ní ìgboyà láti bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ níwájú sí OLÚWA, èmi ẹni tí í ṣe erùpẹ̀ àti eérú,
28bí ó bá ṣe pe olódodo márùn-dín-làádọ́ta (45) ni ó wà nínú ìlú, Ìwọ yóò ha pa ìlú náà run nítorí ènìyàn márùn-ún bí?”
29Òun sì tún wí lẹ́ẹ̀kan si pé, “Bí ó bá ṣe pé ogójì (40) ni ńkọ́?”
30Ábúráhámù sì tún bẹ OLÚWA pé, “Kí OLÚWA má ṣe bínú, ṣùgbọ́n èmi yóò sọ̀rọ̀. Bí ó bá ṣe pé ọgbọ̀n (30) ni rí níbẹ̀ ńkọ́?”
31Ábúráhámù wí pé, “Níwọ̀n bí mo ti ní ìgboyà láti bá OLÚWA sọ̀rọ̀ báyìí, jẹ́ kí n tẹ̀ṣíwájú. Bí o bá ṣe pé olódodo ogún péré ni ó wà nínú ìlú náà ńkọ́?”
32Ábúráhámù sì wí pé, “Jọ̀wọ́ má ṣe bínú OLÚWA. Jẹ́ kí ń béèrè lẹ́ẹ̀kan si. Bí ó bá ṣe pé ènìyàn mẹ́wàá ni bá tí ó jẹ́ olódodo ńkọ́?”
33OLÚWA sì bá tirẹ̀ lọ, nígbà tí ó bá Ábúráhámù sọ̀rọ̀ tan, Ábúráhámù sì padà sílé.