1Ní àsáálẹ́, àwọn ańgẹ́lì méjì sì wá sí ìlú Ṣódómù, Lọ́tì sì jókòó ní ẹnu ibodè ìlú. Bí ó sì ti rí wọn, ó sì dide láti pàdé wọn, ó kí wọn, ó sí foríbalẹ̀ fún wọn.
2Ó wí pé, “Ẹ̀yin olúwa mi, èmi bẹ̀ yín, ẹ yà sí ilé ìránṣẹ́ yín kí ẹ sì wẹ ẹsẹ̀ yín, kí n sì gbà yín lálejò, ẹ̀yin ó sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ láti máa bá ìrìnàjò yín lọ.”
3Ṣùgbọ́n Lọ́tì rọ̀ wọ́n gidigidi tó bẹ́ẹ̀ tí wọ́n gbà láti bá a lọ sì ilé. Ó sì ṣe oúnjẹ fún wọn, ó ṣe Búrẹ́dì aláìwú wọ́n sì jẹ ẹ́.
4Ṣùgbọ́n kí ó tó di pé wọ́n lọ sùn, àwọn ọkùnrin ìlú Ṣódómù tọmọdé tàgbà yí ilé náà ká.
5
6Lọ́tì sì jáde láti pàdé wọn, ó sì ti ilẹ̀kùn lẹ́yìn rẹ̀ bí ó ti jáde.
7Ó sì wí pé; “Rárá, ẹ̀yin ará mi, ẹ má ṣe se ohun búburú yìí,
8kíyèsí i, mo ní ọmọbìnrin méjì tí kò mọ ọkùnrin rí, ẹ jẹ́ kí n mú wọn tọ̀ yín wá kí ẹ sì ṣe ohun tí ẹ fẹ́ pẹ̀lú wọn. Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe ṣe àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ní ibi kan nítorí wọ́n wá wọ̀ lábẹ́ ààbò ní ilé mi.”
9Wọ́n sì wí fún Lọ́tì pé “Yàgò lọ́nà fún wa, o jẹ́ àlejò láàrin wa, o wá ń fẹ́ ṣe onídájọ́: ohun tí a ó fi ṣe ọ́ ju ohun tí a ó fi ṣe wọn lọ.” Wọn rọ́ lu Lọ́tì, wọ́n sì súnmọ ọn láti fọ́ ilẹ̀kùn.
10Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà nawọ́ fa Lọ́tì wọlé, wọ́n sì ti ilẹ̀kùn.
11
12Àwọn ọkùnrin náà sì wí fún Lọ́tì pé, “Ǹjẹ́ ó ní ẹlòmíràn ní ìlú yìí bí? Àna rẹ ọkùnrin, àwọn ọmọ rẹ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tàbí ẹnikẹ̀ni tí ìwọ ní ní ìlú yìí, kó wọn jáde kúrò ní ibí yìí,
13nítorí a ó pa ìlú yìí run, nítorí igbe iṣẹ́ búrurú wọn ń dí púpọ̀ níwájú OLÚWA, OLÚWA sì rán wa láti pa á run.”
14Nígbà náà ni Lọ́tì jáde, ó sì wí fún àwọn àna rẹ̀ ọkùnrin tí ó ti bá jẹ́jẹ̀ẹ́ láti fẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣe kánkán, kí ẹ jáde ní ìlú yìí nítorí OLÚWA fẹ́ pa ilu yìí run!” Ṣùgbọ́n àwọn ọkọ ọmọ rẹ̀ wọ̀nyí rò pé àwàdà ló ń ṣe.
15Ní àfẹ̀mọ́jú, àwọn ańgẹ́lì náà rọ Lọ́tì pé, “Ṣe wéré, mú aya rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ méjèèjì tí ó wà níhìnín, àìṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò parun pẹ̀lú ìlú yìí nígbà tí wọ́n bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”
16
17Ní kété tí wọ́n mú wọn jáde tán, ọ̀kan nínú àwọn Ańgẹ́lì náà wí fún wọn pé, “Ẹ sá àsálà fún ẹ̀mí ti yín, ẹ má ṣe wẹ̀yìn, orí òkè ni kí ẹ sá lọ, ẹ má ṣe dúró ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, àìṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin yóò ṣègbé!”
18Ṣùgbọ́n Lọ́tì wí fún wọn pé, “Rárá, ẹ̀yin Olúwa mi, ẹ jọ̀wọ́!
19Nígbà tí ìránṣẹ́ rẹ ti rí oju rere rẹ, tí o sì ti fi àánú rẹ hàn nípa gbígba ẹ̀mí mi là, Èmi kò le è ṣá lọ sórí òkè, kí búrurú yìí má ba à lé mi bá, kí n sì kú.
20Wò ó, ìlú kékeré kan nìyí ní tòòsí láti ṣá sí: jẹ́ kí n ṣá lọ ṣíbẹ̀, ìlú kékeré ha kọ́?, Ẹ̀mí mi yóò sì yè.”
21Ó sì wí fún un pé, “Ó dára, mo gba ẹ̀bẹ̀ rẹ. Èmi kì yóò run ìlú náà tí ìwọ sọ̀rọ̀ rẹ̀.
22Tètè! Sá lọ ṣíbẹ̀, nítorí èmi kò le ṣe ohun kan àyàfi tí ó bá dé ibẹ̀,” (ìdí nìyí tí a fi ń pe ìlú náà ní Ṣóárì).
23Nígbà tí Lọ́tì yóò fi dé ìlú náà oòrùn ti yọ.
24
25Báyìí ni ó run àwọn ìlú náà àti gbogbo ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó wà ní ìlú ńláńlá wọ̀n-ọn-nì àti ohun gbogbo tí ó hù jáde nílẹ̀.
26
27Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Ábúráhámù sì dìde ó sì padà lọ sí ibi tí ó gbé dúró níwájú OLÚWA.
28
29Ọlọ́run sì rántí Ábúráhámù, nígbà tí ó run ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n-ọn-nì tan, ó sì mú Lọ́tì jáde kúrò láàrin ìparun náà, tí ó kọ lu ìlú tí Lọ́tì ti gbé.
30Lọ́tì àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin méjèèjì sì kúrò ní Sóárì, wọ́n sì ń lọ gbé ní orí òkè ní inú ihò-àpáta, nítorí ó bẹ̀rù láti gbé ní ìlú Sóárì.
31Ní ọjọ́ kan, èyí ẹ̀gbọ́n sọ fún àbúrò rẹ̀ pé, “Baba wa ti dàgbà, kò sì sí ọkùnrin kankan ní agbégbé yìí tí ì bá bá wa lò pọ̀, bí ìṣe gbogbo ayé.
32Wá, jẹ́ kí a mú bàbá wa mu ọtí yó, kí ó ba à le bá wa lò pọ̀, kí àwa kí ó lè bí ọmọ, kí ìran wa má ba à parẹ́.”
33Ní òru ọjọ́ náà, wọ́n rọ baba wọn ní ọtí yó. Èyí ẹ̀gbọ́n sì wọlé tọ̀ ọ́, ó sì bá a lò pọ̀, baba wọn kò mọ̀ ìgbà tí ó sùn ti òun àti ìgbà tí ó dìdè.
34Ní ọjọ́ kejì èyí ẹ̀gbọ́n wí fún àbúrò rẹ̀ pé, “Ní àná mo sùn ti bàbá mi. Jẹ́ kí a tún wọlé tọ̀ ọ́, kí a lè ní irú ọmọ láti ọ̀dọ̀ baba wa.”
35Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n tún fún baba wọn ní ọtí mu yó ni alẹ́ ọjọ́ náà, èyí àbúrò náà sì wọlé tọ̀ ọ́ lọ, ó sì bá a lò pọ̀, kò sì tún mọ ìgbà tí ó wọlé ṣùn ti òun tàbí ìgbà tí ó dìde.
36Àwọn ọmọbìnrin Lọ́tì méjèèjì sì lóyún fún baba wọn.
37Èyí ẹ̀gbọ́n sì bí ọmọkùnrin, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Móábù. Òun ni baba ńlá àwọn ará Móábù lónìí.
38Èyí àbúrò náà sì bí ọmọkùnrin, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Bẹni-Ámì. Òun ni baba ńlá àwọn ará Ámónì lónìí.