1Báyìí ni Ọlọ́run parí dídá àwọn ọ̀run àti ayé pẹ̀lú ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.
2
3Ọlọ́run sì súre fún ọjọ́ kéje, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ní ọjọ́ náà ni ó sinmi kúrò nínú iṣẹ́ dídá ayé tí ó ti ń ṣe.
4Èyí ni ìtàn bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn ọ̀run àti ayé nígbà tí ó dá wọn.
5kò sí igi igbó kan ní orí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ewéko igbó kan tí ó tí ì hù jáde ní ilẹ̀, nítorí OLÚWA Ọlọ́run kò tí ì rọ̀jò sórí ilẹ̀, kò sì sí ènìyàn láti ro ilẹ̀.
6Ṣùgbọ́n ìsun omi ń jáde láti ilẹ̀, ó sì ń bu omi rin gbogbo ilẹ̀.
7
8OLÚWA Ọlọ́run sì gbin ọgbà kan sí Édẹ́nì ní ìhà ìlà oòrùn, níbẹ̀ ni ó fi ọkùnrin náà tí ó ti dá sí.
9
10Odò kan sì ń ti Édẹ́nì sàn wá láti bu omi rin ọgbà náà, láti ibẹ̀ ni odò náà gbé ya sí ipa mẹ́rin.
11Orúkọ èkínní ni Písónì: òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Háfílà ká, níbi tí wúrà gbé wà.
12(Wúrà ilẹ̀ náà dára, òjíá àti òkúta oníyebíye wà níbẹ̀ pẹ̀lú).
13Orúkọ odò kejì ni Gíhónì: òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Kúsì ká.
14Orúkọ odò kẹta ni Tígírísì: òun ni ó sàn ní apá ìlà oòrùn ilẹ̀ Áṣúrì. Odò kẹ́rin ni Yúfúrátè.
15OLÚWA Ọlọ́run mú ọkùnrin náà sínú ọgbà Édẹ́nì láti máa ṣe iṣẹ́ níbẹ̀, kí ó sì máa ṣe ìtọ́jú rẹ̀.
16OLÚWA Ọlọ́run sì pàṣẹ fún ọkùnrin náà pé, “ìwọ́ lè jẹ lára èyíkéyìí èṣo àwọn igi inú ọgbà;
17ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú èṣo igi ìmọ̀ rere àti èṣo igi ìmọ̀ búburú, nítorí ní ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ ẹ́ ni ìwọ yóò kú.”
18OLÚWA Ọlọ́run wí pé, “Kò dára kí ọkùnrin wà ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀ fún un.”
19Lẹ́yìn tí OLÚWA Ọlọ́run ti dá àwọn ẹranko inú igbó àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀, Ó sì kó wọn tọ ọkùnrin náà wá láti wo orúkọ tí yóò sọ wọ́n; orúkọ tí ó sì sọ gbogbo ẹ̀dá alààyè náà ni wọ́n ń jẹ́.
20Gbogbo ohun ọ̀sìn, ẹyẹ ojú ọ̀run àti gbogbo ẹranko igbó ni ọkùnrin náà sọ ní orúkọ.
21Nígbà náà ni OLÚWA Ọlọ́run mú kí ọkùnrin náà sùn fọnfọn; nígbà tí ó sì ń sùn, Ọlọ́run yọ egungun ìhà rẹ̀ kan, ó sì fi ẹran ara bò ó padà.
22OLÚWA Ọlọ́run sì dá obìnrin láti inú egungun tí ó yọ ní ìhà ọkùnrin náà, ó sì mu obìnrin náà tọ̀ ọ́ wá.
23Ọkùnrin náà sì wí pé,
24
25Ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ sì wà ní ìhòòhò, ojú kò sì tì wọ́n.