1
2
3Ábúráhámù sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì mú méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti Ísáákì ọmọ rẹ̀, ó sì ṣe igi fún ẹbọ ṣíṣun, ó sì gbéra lọ sí ibi tí Ọlọ́run ti sọ fún-un.
4Nígbà tí ó di ọjọ kẹ́ta, Ábúráhámù gbé ojú sókè, ó sì rí ibi tí ó ń lọ ní òkèrè,
5Ó sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin, ẹ dúró níhìn-ín pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, èmi àti ọmọ yìí yóò lọ sí ọ̀hún-un-nì láti sin OLÚWA, a ó sì tún pada wá bá a yín.”
6Ábúráhámù sì gbé igi ẹbọ ṣíṣun náà ru Ísáákì, òun fúnra rẹ̀ sì mú iná àti ọ̀bẹ. Bí àwọn méjèèjì ti ń lọ,
7Ísáákì sì sọ fún Ábúráhámù baba rẹ̀ wí pé, “Baba mi.”
8Ábúráhámù sì dáhùn pé, “Ọmọ mi, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ni yóò pèsè ọ̀dọ̀-àgùntàn fún ẹbọ sísun náà.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèèjì tẹ̀ṣíwájú nínú ìrìn-àjò wọn.
9
10Ábúráhámù sì nawọ́ mú ọ̀bẹ, láti dúńbú ọmọ rẹ̀.
11Ṣùgbọ́n ańgẹ́lì OLÚWA ké sí i láti ọ̀run wí pé “Ábúráhámù! Ábúráhámù!”
12Ańgẹ́lì OLÚWA sì wí pé, “Má ṣe fọwọ́ kan ọmọ náà, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ṣe é ni ohun kan. Nísinsin yìí ni mo mọ̀ pé o bẹ̀rù Ọlọ́run, nítorí pé ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan soso dùn mi.”
13Ábúráhámù sì gbójú sókè, ó sì rí àgbò kan tí ó fi ìwo há pàǹtírí, ó sì lọ mú un, ó sì fi rú ẹbọ ṣíṣun, dípò ọmọ rẹ̀.
14Ábúráhámù sì pe orúkọ ibẹ̀ ni, OLÚWA yóò pèṣè (Jìhófà Jirè). Bẹ́ẹ̀ ni a sì ń wí títí di òní olónìí pé, “Ní orí òkè OLÚWA, ni a ó ti pèsè.”
15Ańgẹ́lì OLÚWA sì tún pe Ábúráhámù láti ọ̀run lẹ́ẹ̀kejì.
16
17
18
19Nígbà náà ni Ábúráhámù padà tọ àwọn ìrànṣẹ́ rẹ̀ lọ. Gbogbo wọn sì padà lọ sí Báá-Ṣébà Ábúráhámù sì dúró ní Báá-Ṣébà.
20Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni a wí fún Ábúráhámù pé, “Mílíkà aya Náhórì bí àwọn ọmọkùnrin fún-un.
21Úsì, àkọ́bí rẹ̀, Búsì arákùnri rẹ̀, Kémúélì (Baba Árámù).
22Kéṣédì, Áṣọ̀, Pílídásì, Jídíláfù, àti Bétúélì.”
23Bétúélì sì ni baba Rèbékà. Mílíkà sì bí àwọn ọmọ mẹ́jọ wọ̀nyí fún Náhórì arákùnrin Ábúráhámù.
24Àlè rẹ̀ tí ń jẹ́ Réhúmà náà bí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí fun un: Tébà, Gáhámù, Táhásì àti Máákà.